Job 15 (BOYCB)

1 Ìgbà náà ní Elifasi, ará Temani, dáhùn wí pé, 2 “Ọlọ́gbọ́n a máa sọ̀rọ̀ ìmọ̀ asánkí ó sì máa fi afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn kún ara rẹ̀ nínú? 3 Òun lè máa fi àròyé sọ̀rọ̀ tí kò ní èrè,tàbí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ nínú èyí tí kò lè fi ṣe rere? 4 Ṣùgbọ́n ìwọ ṣá ìbẹ̀rù tì,ìwọ sì dí iṣẹ́ ìsìn lọ́nà níwájú Ọlọ́run. 5 Nítorí pé ẹnu ara rẹ̀ ni ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,ìwọ sì yàn ahọ́n alárékérekè ni ààyò. 6 Ẹnu ara rẹ̀ ni ó dá lẹ́bi, kì í ṣe èmi;àní ètè ara rẹ̀ ni ó jẹ́rìí gbè ọ́. 7 “Ìwọ ha í ṣe ọkùnrin tí a kọ́ bí?Tàbí a ha dá ọ ṣáájú àwọn òkè? 8 Ìwọ gbúròó àṣírí Ọlọ́run rí?Tàbí ìwọ ha dá ọgbọ́n dúró sọ́dọ̀ ara rẹ? 9 Kí ni ìwọ mọ̀ tí àwa kò mọ̀?Òye kí ní ó yé ọ tí kò sí nínú wa? 10 Àwọn arúgbó àti ògbólógbòó ènìyàn wà pẹ̀lú wa,tí wọ́n dàgbà ju baba rẹ lọ. 11 Ìtùnú Ọlọ́run ha kéré lọ́dọ̀ rẹ?Ọ̀rọ̀ kan sì ṣe jẹ́jẹ́ jù lọ́dọ̀ rẹ? 12 Èéṣe ti ọkàn rẹ fi ń ti ọ kiri,kí ni ìwọ tẹjúmọ́ tóbẹ́ẹ̀. 13 Tí ìwọ fi yí ẹ̀mí rẹ padà lòdì sí Ọlọ́run,tí ó fi ń jẹ́ ki ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ kí ó máa bọ́ ní ẹnu rẹ̀ bẹ́ẹ̀? 14 “Kí ni ènìyàn tí ó fi jẹ mímọ́,àti ẹni tí a tinú obìnrin bí tí yóò fi ṣe olódodo? 15 Kíyèsi i, bi Ọlọ́run ko ba gbẹ́kẹ̀lé àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀,àní àwọn ọ̀run kò mọ́ ní ojú rẹ̀, 16 mélòó mélòó ni ènìyàn, ẹni ìríra àti eléèérí,tí ń mu ẹ̀ṣẹ̀ bi ẹní mu omi. 17 “Èmi ó fihàn ọ́, gbọ́ ti èmi;èyí tí èmi sì rí, òun ni èmi ó sì sọ, 18 ohun tí àwọn ọlọ́gbọ́n ti pa ní ìtàn látiọ̀dọ̀ àwọn baba wọn wá, ti wọ́n kò sì fi pamọ́. 19 Àwọn tí a fi ilẹ̀ ayé fún nìkan,ti àlejò kan kò sì là wọ́n kọjá. 20 Ènìyàn búburú ń ṣe làálàá,pẹ̀lú ìrora, ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo,àti iye ọdún ní a dá sílẹ̀ fún aninilára. 21 Ìró ìbẹ̀rù ń bẹ ní etí rẹ̀;nínú ìrora ni apanirun yóò dìde sí i. 22 Kò gbàgbọ́ pé òun ó jáde kúrò nínú òkùnkùn;a sì ṣà á sápá kan fún idà. 23 Ó ń wò káàkiri fún oúnjẹ wí pé, níbo ní ó wà?Ó mọ̀ pé ọjọ́ òkùnkùn súnmọ́ tòsí. 24 Ìpọ́njú pẹ̀lú ìrora ọkàn yóò mú un bẹ̀rù,wọ́n ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ bi ọba ti ìmúra ogun. 25 Nítorí pé ó ti nawọ́ rẹ̀ jáde lòdì sí Ọlọ́run,ó sì múra rẹ̀ le lòdì sí Olódùmarè, 26 ó súre, ó sì fi ẹ̀yìn gíga,àní fi ike-kókó àpáta rẹ̀ tí ó nípọn kọlù ú. 27 “Nítorí tí òun fi ọ̀rá rẹ̀ bo ara rẹ̀ lójú,o sì ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹran sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. 28 Òun sì gbé inú ahoro ìlú,àti nínú ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé mọ́,tí ó múra tán láti di àlàpà. 29 Òun kò lé di ọlọ́rọ̀, bẹ́ẹ̀ ohun ìní rẹ̀ kòlè dúró pẹ́; bẹ́ẹ̀ kò lè mú pípé rẹ̀ dúró pẹ́ lórí ilẹ̀. 30 Òun kì yóò jáde kúrò nínú òkùnkùn;ọ̀wọ́-iná ni yóò jó ẹ̀ka rẹ̀,àti nípasẹ̀ ẹ̀mí ẹnu Ọlọ́run ní a ó gba kúrò. 31 Kí òun kí ó má ṣe gbẹ́kẹ̀lé asán, kí ó má sì ṣe tan ara rẹ̀ jẹ.Nítorí pé asán ní yóò jásí èrè rẹ̀. 32 A ó mú un ṣẹ ṣáájú pípé ọjọ́ rẹ̀,ẹ̀ka rẹ̀ kì yóò sì tutù. 33 Yóò dàbí àjàrà tí a gbọn èso àìpọ́n rẹ̀ dànù,yóò sì rẹ̀ ìtànná rẹ̀ dànù bí i ti igi Olifi. 34 Nítorí pé ayọ̀ àwọn àgàbàgebè yóò túká,iná ní yóò sì jó àgọ́ àwọn tí ó fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀. 35 Wọ́n lóyún ìwà ìkà, wọ́n sì bí ẹ̀ṣẹ̀,ikùn wọn sì pèsè ẹ̀tàn.”

In Other Versions

Job 15 in the ANGEFD

Job 15 in the ANTPNG2D

Job 15 in the AS21

Job 15 in the BAGH

Job 15 in the BBPNG

Job 15 in the BBT1E

Job 15 in the BDS

Job 15 in the BEV

Job 15 in the BHAD

Job 15 in the BIB

Job 15 in the BLPT

Job 15 in the BNT

Job 15 in the BNTABOOT

Job 15 in the BNTLV

Job 15 in the BOATCB

Job 15 in the BOATCB2

Job 15 in the BOBCV

Job 15 in the BOCNT

Job 15 in the BOECS

Job 15 in the BOGWICC

Job 15 in the BOHCB

Job 15 in the BOHCV

Job 15 in the BOHLNT

Job 15 in the BOHNTLTAL

Job 15 in the BOICB

Job 15 in the BOILNTAP

Job 15 in the BOITCV

Job 15 in the BOKCV

Job 15 in the BOKCV2

Job 15 in the BOKHWOG

Job 15 in the BOKSSV

Job 15 in the BOLCB

Job 15 in the BOLCB2

Job 15 in the BOMCV

Job 15 in the BONAV

Job 15 in the BONCB

Job 15 in the BONLT

Job 15 in the BONUT2

Job 15 in the BOPLNT

Job 15 in the BOSCB

Job 15 in the BOSNC

Job 15 in the BOTLNT

Job 15 in the BOVCB

Job 15 in the BPBB

Job 15 in the BPH

Job 15 in the BSB

Job 15 in the CCB

Job 15 in the CUV

Job 15 in the CUVS

Job 15 in the DBT

Job 15 in the DGDNT

Job 15 in the DHNT

Job 15 in the DNT

Job 15 in the ELBE

Job 15 in the EMTV

Job 15 in the ESV

Job 15 in the FBV

Job 15 in the FEB

Job 15 in the GGMNT

Job 15 in the GNT

Job 15 in the HARY

Job 15 in the HNT

Job 15 in the IRVA

Job 15 in the IRVB

Job 15 in the IRVG

Job 15 in the IRVH

Job 15 in the IRVK

Job 15 in the IRVM

Job 15 in the IRVM2

Job 15 in the IRVO

Job 15 in the IRVP

Job 15 in the IRVT

Job 15 in the IRVT2

Job 15 in the IRVU

Job 15 in the ISVN

Job 15 in the JSNT

Job 15 in the KAPI

Job 15 in the KBT1ETNIK

Job 15 in the KBV

Job 15 in the KJV

Job 15 in the KNFD

Job 15 in the LBA

Job 15 in the LBLA

Job 15 in the LNT

Job 15 in the LSV

Job 15 in the MAAL

Job 15 in the MBV

Job 15 in the MBV2

Job 15 in the MHNT

Job 15 in the MKNFD

Job 15 in the MNG

Job 15 in the MNT

Job 15 in the MNT2

Job 15 in the MRS1T

Job 15 in the NAA

Job 15 in the NASB

Job 15 in the NBLA

Job 15 in the NBS

Job 15 in the NBVTP

Job 15 in the NET2

Job 15 in the NIV11

Job 15 in the NNT

Job 15 in the NNT2

Job 15 in the NNT3

Job 15 in the PDDPT

Job 15 in the PFNT

Job 15 in the RMNT

Job 15 in the SBIAS

Job 15 in the SBIBS

Job 15 in the SBIBS2

Job 15 in the SBICS

Job 15 in the SBIDS

Job 15 in the SBIGS

Job 15 in the SBIHS

Job 15 in the SBIIS

Job 15 in the SBIIS2

Job 15 in the SBIIS3

Job 15 in the SBIKS

Job 15 in the SBIKS2

Job 15 in the SBIMS

Job 15 in the SBIOS

Job 15 in the SBIPS

Job 15 in the SBISS

Job 15 in the SBITS

Job 15 in the SBITS2

Job 15 in the SBITS3

Job 15 in the SBITS4

Job 15 in the SBIUS

Job 15 in the SBIVS

Job 15 in the SBT

Job 15 in the SBT1E

Job 15 in the SCHL

Job 15 in the SNT

Job 15 in the SUSU

Job 15 in the SUSU2

Job 15 in the SYNO

Job 15 in the TBIAOTANT

Job 15 in the TBT1E

Job 15 in the TBT1E2

Job 15 in the TFTIP

Job 15 in the TFTU

Job 15 in the TGNTATF3T

Job 15 in the THAI

Job 15 in the TNFD

Job 15 in the TNT

Job 15 in the TNTIK

Job 15 in the TNTIL

Job 15 in the TNTIN

Job 15 in the TNTIP

Job 15 in the TNTIZ

Job 15 in the TOMA

Job 15 in the TTENT

Job 15 in the UBG

Job 15 in the UGV

Job 15 in the UGV2

Job 15 in the UGV3

Job 15 in the VBL

Job 15 in the VDCC

Job 15 in the YALU

Job 15 in the YAPE

Job 15 in the YBVTP

Job 15 in the ZBP