Luke 23 (BOYCB)

1 Gbogbo ìjọ ènìyàn sì dìde, wọ́n sì fà á lọ sí ọ̀dọ̀ Pilatu. 2 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹ̀sùn kàn án, wí pé, “Àwa rí ọkùnrin yìí ó ń yí orílẹ̀-èdè wa lọ́kàn padà, ó sì ń dá wọn lẹ́kun láti san owó òde fún Kesari, ó ń wí pé, òun tìkára òun ni Kristi ọba.” 3 Pilatu sì bi í léèrè, wí pé, “Ìwọ ha ni ọba àwọn Júù?”Ó sì dá a lóhùn wí pé, “Ìwọ wí i.” 4 Pilatu sì wí fún àwọn olórí àlùfáà àti fún ìjọ ènìyàn pé, “Èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ ọkùnrin yìí.” 5 Wọ́n sì túbọ̀ tẹnumọ́ ọn pé, “Ó ń ru ènìyàn sókè, ó ń kọ́ni káàkiri gbogbo Judea, ó bẹ̀rẹ̀ láti Galili títí ó fi dé ìhín yìí!” 6 Nígbà tí Pilatu gbọ́ orúkọ Galili, ó béèrè bí ọkùnrin náà bá jẹ́ ará Galili. 7 Nígbà tí ó sì mọ̀ pé ará ilẹ̀ abẹ́ àṣẹ Herodu ni, ó rán an sí Herodu, ẹni tí òun tìkára rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu ní àkókò náà. 8 Nígbà tí Herodu, sì rí Jesu, ó yọ̀ gidigidi; nítorí tí ó ti ń fẹ́ rí i pẹ́ ó sá à ti ń gbọ́ ìròyìn púpọ̀ nítorí rẹ̀; ó sì ń retí láti rí i kí iṣẹ́ àmì díẹ̀ ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe. 9 Ó sì béèrè ọ̀rọ̀ púpọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀; ṣùgbọ́n kò da a lóhùn rárá. 10 Àti àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé dúró, wọ́n sì ń fi ẹ̀sùn kàn án gidigidi. 11 Àti Herodu pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, wọ́n kẹ́gàn rẹ̀, wọ́n sì ń fi í ṣẹ̀sín, wọ́n wọ̀ ọ́ ní aṣọ dáradára, ó sì rán an padà tọ Pilatu lọ. 12 Pilatu àti Herodu di ọ̀rẹ́ ara wọn ní ọjọ́ náà, nítorí látijọ́ ọ̀tá ara wọn ni wọ́n ti jẹ́ rí. 13 Pilatu sì pe àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olórí àti àwọn ènìyàn jọ. 14 Ó sọ fún wọn pé, “Ẹyin mú ọkùnrin yìí tọ̀ mí wá, bí ẹni tí ó ń yí àwọn ènìyàn ní ọkàn padà. Sì kíyèsi i, èmí wádìí ẹjọ́ rẹ̀ níwájú yín èmi kò sì rí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ ọkùnrin yìí, ní gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí ẹ̀yin fi ẹ̀sùn rẹ̀ sùn. 15 Àti Herodu pẹ̀lú; ó sá rán an padà tọ̀ wá wá; sì kíyèsi i, ohun kan tí ó yẹ sí ikú ni a kò ṣe láti ọwọ́ rẹ̀. 16 Ǹjẹ́ èmi ó nà án, èmi ó sì fi í sílẹ̀ lọ.” 18 Wọ́n sì kígbe sókè nígbà kan náà, pé, “Mú ọkùnrin yìí kúrò, kí o sì dá Baraba sílẹ̀ fún wa!” 19 Ẹni tí a sọ sínú túbú nítorí ọ̀tẹ̀ kan tí a ṣe ní ìlú, àti nítorí ìpànìyàn. 20 Pilatu sì tún bá wọn sọ̀rọ̀, nítorí ó fẹ́ dá Jesu sílẹ̀. 21 Ṣùgbọ́n wọ́n kígbe, wí pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú, kàn án mọ àgbélébùú!” 22 Ó sì wí fún wọn lẹ́ẹ̀mẹ́ta pé, “Èéṣe, búburú kín ni ọkùnrin yìí ṣe? Èmi kò rí ọ̀ràn ikú lára rẹ̀: nítorí náà èmi ó nà án, èmi ó sì fi í sílẹ̀.” 23 Wọ́n túbọ̀ tẹramọ́ igbe ńlá, wọ́n ń fẹ́ kí a kàn án mọ́ àgbélébùú, ohùn tiwọn àti ti àwọn olórí àlùfáà borí tirẹ̀. 24 Pilatu sí fi àṣẹ sí i pé, kí ó rí bí wọ́n ti ń fẹ́. 25 Ó sì dá ẹni tí wọ́n fẹ́ sílẹ̀ fún wọn, ẹni tí a tìtorí ọ̀tẹ̀ àti ìpànìyàn sọ sínú túbú; ṣùgbọ́n ó fi Jesu lé wọn lọ́wọ́. 26 Bí wọ́n sì ti ń fà á lọ, wọ́n mú ọkùnrin kan, Simoni ara Kirene, tí ó ń ti ìgbèríko bọ̀, òun ni wọ́n sì gbé àgbélébùú náà lé, kí ó máa rù ú lọ tẹ̀lé Jesu. 27 Ìjọ ènìyàn púpọ̀ ni ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, àti àwọn obìnrin, tí ń pohùnréré ẹkún, 28 ṣùgbọ́n Jesu yíjú padà sí wọn, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerusalẹmu, ẹ má sọkún fún mi, ṣùgbọ́n ẹ sọkún fún ara yín, àti fún àwọn ọmọ yín. 29 Nítorí kíyèsi i, ọjọ́ ń bọ̀ ní èyí tí ẹ̀yin ó wí pé, ‘Ìbùkún ni fún àgàn, àti fún inú tí kò bímọ rí, àti fún ọmú tí kò fún ni mu rí!’ 30 Nígbà náà ni “ ‘wọn ó bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn òkè kéékèèké pé, “Yí lù wá!” Sí àwọn òkè ńlá, “Bò wá mọ́lẹ̀!” ’ 31 Nítorí bí wọn bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí sára igi tútù, kín ni a ó ṣe sára igi gbígbẹ?” 32 Àwọn méjì mìíràn bákan náà, àwọn arúfin, ni wọ́n sì fà lọ pẹ̀lú rẹ̀ láti pa. 33 Nígbà tí wọ́n sì dé ibi tí a ń pè ní Agbárí, níbẹ̀ ni wọ́n gbé kàn án mọ́ àgbélébùú, àti àwọn arúfin náà, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún, àti ọ̀kan ní ọwọ́ òsì. 34 Jesu sì wí pé, “Baba, dáríjì wọ́n; nítorí tí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.” Wọ́n di ìbò láti pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn. 35 Àwọn ènìyàn sì dúró láti wòran. Àti àwọn ìjòyè pẹ̀lú wọn, wọ́n ń yọ ṣùtì sí i, wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là; kí ó gbara rẹ̀ là, bí ó bá ṣe Kristi, àyànfẹ́ Ọlọ́run.” 36 Àti àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú ń fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n tọ̀ ọ́ wá, wọ́n ń fi ọtí kíkan fún un. 37 Wọ́n sì ń wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe ọba àwọn Júù, gba ara rẹ là.” 38 Wọ́n sì kọ̀wé àkọlé sí ìgbèrí rẹ̀ ní èdè Giriki, àti ti Latin, àti tí Heberu pe:Èyí ni Ọba àwọn Júù. 39 Àti ọ̀kan nínú àwọn arúfin tí a gbé kọ́ ń fi ṣe ẹlẹ́yà wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Kristi, gba ara rẹ àti àwa náà là.” 40 Ṣùgbọ́n èyí èkejì dáhùn, ó ń bá a wí pé, “Ìwọ kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ìwọ wà nínú ẹ̀bi kan náà? 41 Ní tiwa, wọ́n jàre nítorí èrè ohun tí àwa ṣe ni à ń jẹ, ṣùgbọ́n ọkùnrin yìí kò ṣe ohun búburú kan.” 42 Ó sì wí pé, “Jesu, rántí mi nígbà tí ìwọ bá dé ìjọba rẹ.” 43 Jesu sì wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, lónìí ni ìwọ ó wà pẹ̀lú mi ní Paradise!” 44 Ó sì tó ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́, òkùnkùn sì ṣú bo gbogbo ilẹ̀ títí ó fi di wákàtí kẹsànán ọjọ́. 45 Òòrùn sì ṣú òòkùn, aṣọ ìkélé ti tẹmpili sì ya ní àárín méjì. 46 Nígbà tí Jesu sì kígbe lóhùn rara, ó ní, “Baba, ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé!” Nígbà tí ó sì wí èyí tan, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀. 47 Nígbà tí balógun ọ̀rún rí ohun tí ó ṣe, ó yin Ọlọ́run lógo, wí pé, “Dájúdájú olódodo ni ọkùnrin yìí!” 48 Gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó péjọ láti rí ìran yìí, nígbà tí wọ́n rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ wọ́n lu ara wọn ní oókan àyà, wọ́n sì padà sí ilé. 49 Àti gbogbo àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀, àti àwọn obìnrin tí ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn láti Galili wá, wọ́n dúró lókèèrè, wọ́n ń wo nǹkan wọ̀nyí. 50 Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Josẹfu, láti ìlú àwọn Júù kan tí ń jẹ́ Arimatea. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ènìyàn rere, àti olóòtítọ́. 51 Òun kò bá wọn fi ohùn sí ìmọ̀ àti ìṣe wọn; Ó wá láti Judea, ìlú àwọn ará Arimatea, òun pẹ̀lú ń retí ìjọba Ọlọ́run. 52 Ọkùnrin yìí tọ Pilatu lọ, ó sì tọrọ òkú Jesu. 53 Nígbà tí ó sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀, ó sì fi aṣọ àlà dì í, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì tí a gbẹ́ nínú Òkúta, níbi tí a kò tẹ́ ẹnikẹ́ni sí rí. 54 Ó sì jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́, ọjọ́ ìsinmi sì kù sí dẹ̀dẹ̀. 55 Àti àwọn obìnrin, tí wọ́n bá a ti Galili wá, tí wọ́n sì tẹ̀lé, wọ́n kíyèsi ibojì náà, àti bí a ti tẹ́ òkú rẹ̀ sílẹ̀. 56 Nígbà tí wọ́n sì padà, wọ́n pèsè ohun olóòórùn dídùn, òróró ìkunra (àti tùràrí tútù); wọ́n sì sinmi ní ọjọ́ ìsinmi gẹ́gẹ́ bí òfin.

In Other Versions

Luke 23 in the ANGEFD

Luke 23 in the ANTPNG2D

Luke 23 in the AS21

Luke 23 in the BAGH

Luke 23 in the BBPNG

Luke 23 in the BBT1E

Luke 23 in the BDS

Luke 23 in the BEV

Luke 23 in the BHAD

Luke 23 in the BIB

Luke 23 in the BLPT

Luke 23 in the BNT

Luke 23 in the BNTABOOT

Luke 23 in the BNTLV

Luke 23 in the BOATCB

Luke 23 in the BOATCB2

Luke 23 in the BOBCV

Luke 23 in the BOCNT

Luke 23 in the BOECS

Luke 23 in the BOGWICC

Luke 23 in the BOHCB

Luke 23 in the BOHCV

Luke 23 in the BOHLNT

Luke 23 in the BOHNTLTAL

Luke 23 in the BOICB

Luke 23 in the BOILNTAP

Luke 23 in the BOITCV

Luke 23 in the BOKCV

Luke 23 in the BOKCV2

Luke 23 in the BOKHWOG

Luke 23 in the BOKSSV

Luke 23 in the BOLCB

Luke 23 in the BOLCB2

Luke 23 in the BOMCV

Luke 23 in the BONAV

Luke 23 in the BONCB

Luke 23 in the BONLT

Luke 23 in the BONUT2

Luke 23 in the BOPLNT

Luke 23 in the BOSCB

Luke 23 in the BOSNC

Luke 23 in the BOTLNT

Luke 23 in the BOVCB

Luke 23 in the BPBB

Luke 23 in the BPH

Luke 23 in the BSB

Luke 23 in the CCB

Luke 23 in the CUV

Luke 23 in the CUVS

Luke 23 in the DBT

Luke 23 in the DGDNT

Luke 23 in the DHNT

Luke 23 in the DNT

Luke 23 in the ELBE

Luke 23 in the EMTV

Luke 23 in the ESV

Luke 23 in the FBV

Luke 23 in the FEB

Luke 23 in the GGMNT

Luke 23 in the GNT

Luke 23 in the HARY

Luke 23 in the HNT

Luke 23 in the IRVA

Luke 23 in the IRVB

Luke 23 in the IRVG

Luke 23 in the IRVH

Luke 23 in the IRVK

Luke 23 in the IRVM

Luke 23 in the IRVM2

Luke 23 in the IRVO

Luke 23 in the IRVP

Luke 23 in the IRVT

Luke 23 in the IRVT2

Luke 23 in the IRVU

Luke 23 in the ISVN

Luke 23 in the JSNT

Luke 23 in the KAPI

Luke 23 in the KBT1ETNIK

Luke 23 in the KBV

Luke 23 in the KJV

Luke 23 in the KNFD

Luke 23 in the LBA

Luke 23 in the LBLA

Luke 23 in the LNT

Luke 23 in the LSV

Luke 23 in the MAAL

Luke 23 in the MBV

Luke 23 in the MBV2

Luke 23 in the MHNT

Luke 23 in the MKNFD

Luke 23 in the MNG

Luke 23 in the MNT

Luke 23 in the MNT2

Luke 23 in the MRS1T

Luke 23 in the NAA

Luke 23 in the NASB

Luke 23 in the NBLA

Luke 23 in the NBS

Luke 23 in the NBVTP

Luke 23 in the NET2

Luke 23 in the NIV11

Luke 23 in the NNT

Luke 23 in the NNT2

Luke 23 in the NNT3

Luke 23 in the PDDPT

Luke 23 in the PFNT

Luke 23 in the RMNT

Luke 23 in the SBIAS

Luke 23 in the SBIBS

Luke 23 in the SBIBS2

Luke 23 in the SBICS

Luke 23 in the SBIDS

Luke 23 in the SBIGS

Luke 23 in the SBIHS

Luke 23 in the SBIIS

Luke 23 in the SBIIS2

Luke 23 in the SBIIS3

Luke 23 in the SBIKS

Luke 23 in the SBIKS2

Luke 23 in the SBIMS

Luke 23 in the SBIOS

Luke 23 in the SBIPS

Luke 23 in the SBISS

Luke 23 in the SBITS

Luke 23 in the SBITS2

Luke 23 in the SBITS3

Luke 23 in the SBITS4

Luke 23 in the SBIUS

Luke 23 in the SBIVS

Luke 23 in the SBT

Luke 23 in the SBT1E

Luke 23 in the SCHL

Luke 23 in the SNT

Luke 23 in the SUSU

Luke 23 in the SUSU2

Luke 23 in the SYNO

Luke 23 in the TBIAOTANT

Luke 23 in the TBT1E

Luke 23 in the TBT1E2

Luke 23 in the TFTIP

Luke 23 in the TFTU

Luke 23 in the TGNTATF3T

Luke 23 in the THAI

Luke 23 in the TNFD

Luke 23 in the TNT

Luke 23 in the TNTIK

Luke 23 in the TNTIL

Luke 23 in the TNTIN

Luke 23 in the TNTIP

Luke 23 in the TNTIZ

Luke 23 in the TOMA

Luke 23 in the TTENT

Luke 23 in the UBG

Luke 23 in the UGV

Luke 23 in the UGV2

Luke 23 in the UGV3

Luke 23 in the VBL

Luke 23 in the VDCC

Luke 23 in the YALU

Luke 23 in the YAPE

Luke 23 in the YBVTP

Luke 23 in the ZBP