Proverbs 14 (BOYCB)

1 Ọlọ́gbọ́n obìnrin kọ́ ilé e rẹ̀,ṣùgbọ́n aṣiwèrè obìnrin fi ọwọ́ ara rẹ̀ fà á lulẹ̀. 2 Ẹni tí ń rìn déédé bẹ̀rù OLÚWA,ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ kò tọ́ kẹ́gàn OLÚWA. 3 Ọ̀rọ̀ aṣiwèrè a máa ṣokùnfà pàṣán fún ẹ̀yìn rẹ̀,ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ètè ọlọ́gbọ́n a máa dáàbò bò ó. 4 Níbi tí kò sí ẹran, ibùjẹ ẹran a máa mọ́ tónítóní,ṣùgbọ́n, nípa agbára akọ màlúù ni ọ̀pọ̀ ìkórè ti ń wá. 5 Ẹlẹ́rìí tí ń ṣọ òtítọ́ kì í tan niṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké a máa tú irọ́ jáde. 6 Ẹlẹ́gàn ń wá ọgbọ́n kò sì rí rárá,ṣùgbọ́n ìmọ̀ máa ń wà fún olóye. 7 Má ṣe súnmọ́ aláìgbọ́n ènìyàn,nítorí ìwọ kì yóò rí ìmọ̀ ní ètè rẹ̀. 8 Ọgbọ́n olóye ni láti ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀nà wọnṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ aṣiwèrè ni ìtànjẹ. 9 Aláìgbọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ nígbà tí ó yẹ kí ó ṣe àtúnṣe ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ṣùgbọ́n láàrín àwọn olódodo ni a ti rí ojúrere. 10 Ọkàn kọ̀ọ̀kan ló mọ ẹ̀dùn ọkàn tirẹ̀kò sì ṣí ẹnìkan tó le è bá ọkàn mìíràn pín ayọ̀ rẹ̀. 11 A ó pa ilé ènìyàn búburú run,ṣùgbọ́n àgọ́ olódodo yóò máa gbèrú sí i. 12 Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn,ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, a máa jásí ikú. 13 Kódà nígbà tí a ń rẹ́rìn-ín, ọkàn le è máa kérora;ayọ̀ sì le è yọrí sí ìbànújẹ́. 14 A ó san án lẹ́kùnrẹ́rẹ́ fún aláìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀,ènìyàn rere yóò sì gba èrè fún tirẹ̀. 15 Òpè ènìyàn gba ohun gbogbo gbọ́ṣùgbọ́n olóye ènìyàn ronú lórí àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀. 16 Ọlọ́gbọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kórìíra ibiṣùgbọ́n aláìgbọ́n jẹ́ alágídí àti aláìṣọ́ra. 17 Ẹni tí ó máa ń tètè bínú máa ń hùwà aṣiwèrè,a sì kórìíra eléte ènìyàn. 18 Òpè jogún ìwà òmùgọ̀ṣùgbọ́n a dé ọlọ́gbọ́n ní adé ìmọ̀. 19 Ènìyàn ìkà yóò tẹríba níwájú àwọn ènìyàn rereàti ènìyàn búburú níbi ìlẹ̀kùn àwọn olódodo. 20 Kódà àwọn aládùúgbò tálákà kò fẹ́ràn rẹ̀,ṣùgbọ́n, ọlọ́rọ̀ ní ọ̀rẹ́ púpọ̀. 21 Ẹni tí ó kẹ́gàn aládùúgbò o rẹ̀ ti dẹ́ṣẹ̀ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ẹni tí ó ṣàánú àwọn aláìní. 22 Ǹjẹ́ àwọn tí ń pète ibi kì í ṣìnà bí?Ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbèrò ohun rere ń rí ìfẹ́ àti òtítọ́. 23 Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló máa ń mú èrè wá,ṣùgbọ́n ẹjọ́ rírò lásán máa ń ta ni lósì ni. 24 Ọrọ̀ ọlọ́gbọ́n ènìyàn ni adé orí wọnṣùgbọ́n ìwà aláìgbọ́n ń mú ìwà òmùgọ̀ wá. 25 Ẹlẹ́rìí tí ó ṣọ òtítọ́ gba ẹ̀mí làṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké jẹ́ ẹlẹ́tàn. 26 Nínú ìbẹ̀rù OLÚWA ni ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó lágbára,yóò sì tún jẹ́ ibi ààbò fún àwọn ọmọ rẹ̀. 27 Ìbẹ̀rù OLÚWA jẹ́ orísun ìyè,tí ń yí ènìyàn padà kúrò nínú ìkẹ́kùn ikú. 28 Ènìyàn púpọ̀ ní ìlú jẹ́ ògo ọba,ṣùgbọ́n láìsí ìjòyè, ọba á parun. 29 Onísùúrù ènìyàn ní òye tí ó pọ̀,ṣùgbọ́n onínú-fùfù ènìyàn máa ń fi ìwà aṣiwèrè hàn. 30 Ọkàn tí ó lálàáfíà fi ìyè mú kí ọjọ́ ayé gùn fún ara,ṣùgbọ́n ìlara mú kí egungun jẹrà. 31 Ẹni tí ó fi ìyà jẹ aláìní ń fi ìkórìíra hànṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó ṣoore fún aláìní bu ọlá fún Ọlọ́run. 32 Nígbà tí ìyọnu bá dé, a fa àwọn búburú lulẹ̀,kódà nínú ikú àwọn olódodo ni ààbò. 33 Ọgbọ́n wà nínú ọkàn olóyekódà láàrín àwọn aláìlóye, ó jẹ́ kí wọn mọ òun. 34 Òdodo a máa gbé orílẹ̀-èdè lékè,ṣùgbọ́n ìtìjú ni ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ fún àwùjọ káwùjọ. 35 Ọba a máa ní inú dídùn sí ìránṣẹ́ tí ó gbọ́nṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ wá sórí ìránṣẹ́ adójútini.

In Other Versions

Proverbs 14 in the ANGEFD

Proverbs 14 in the ANTPNG2D

Proverbs 14 in the AS21

Proverbs 14 in the BAGH

Proverbs 14 in the BBPNG

Proverbs 14 in the BBT1E

Proverbs 14 in the BDS

Proverbs 14 in the BEV

Proverbs 14 in the BHAD

Proverbs 14 in the BIB

Proverbs 14 in the BLPT

Proverbs 14 in the BNT

Proverbs 14 in the BNTABOOT

Proverbs 14 in the BNTLV

Proverbs 14 in the BOATCB

Proverbs 14 in the BOATCB2

Proverbs 14 in the BOBCV

Proverbs 14 in the BOCNT

Proverbs 14 in the BOECS

Proverbs 14 in the BOGWICC

Proverbs 14 in the BOHCB

Proverbs 14 in the BOHCV

Proverbs 14 in the BOHLNT

Proverbs 14 in the BOHNTLTAL

Proverbs 14 in the BOICB

Proverbs 14 in the BOILNTAP

Proverbs 14 in the BOITCV

Proverbs 14 in the BOKCV

Proverbs 14 in the BOKCV2

Proverbs 14 in the BOKHWOG

Proverbs 14 in the BOKSSV

Proverbs 14 in the BOLCB

Proverbs 14 in the BOLCB2

Proverbs 14 in the BOMCV

Proverbs 14 in the BONAV

Proverbs 14 in the BONCB

Proverbs 14 in the BONLT

Proverbs 14 in the BONUT2

Proverbs 14 in the BOPLNT

Proverbs 14 in the BOSCB

Proverbs 14 in the BOSNC

Proverbs 14 in the BOTLNT

Proverbs 14 in the BOVCB

Proverbs 14 in the BPBB

Proverbs 14 in the BPH

Proverbs 14 in the BSB

Proverbs 14 in the CCB

Proverbs 14 in the CUV

Proverbs 14 in the CUVS

Proverbs 14 in the DBT

Proverbs 14 in the DGDNT

Proverbs 14 in the DHNT

Proverbs 14 in the DNT

Proverbs 14 in the ELBE

Proverbs 14 in the EMTV

Proverbs 14 in the ESV

Proverbs 14 in the FBV

Proverbs 14 in the FEB

Proverbs 14 in the GGMNT

Proverbs 14 in the GNT

Proverbs 14 in the HARY

Proverbs 14 in the HNT

Proverbs 14 in the IRVA

Proverbs 14 in the IRVB

Proverbs 14 in the IRVG

Proverbs 14 in the IRVH

Proverbs 14 in the IRVK

Proverbs 14 in the IRVM

Proverbs 14 in the IRVM2

Proverbs 14 in the IRVO

Proverbs 14 in the IRVP

Proverbs 14 in the IRVT

Proverbs 14 in the IRVT2

Proverbs 14 in the IRVU

Proverbs 14 in the ISVN

Proverbs 14 in the JSNT

Proverbs 14 in the KAPI

Proverbs 14 in the KBT1ETNIK

Proverbs 14 in the KBV

Proverbs 14 in the KJV

Proverbs 14 in the KNFD

Proverbs 14 in the LBA

Proverbs 14 in the LBLA

Proverbs 14 in the LNT

Proverbs 14 in the LSV

Proverbs 14 in the MAAL

Proverbs 14 in the MBV

Proverbs 14 in the MBV2

Proverbs 14 in the MHNT

Proverbs 14 in the MKNFD

Proverbs 14 in the MNG

Proverbs 14 in the MNT

Proverbs 14 in the MNT2

Proverbs 14 in the MRS1T

Proverbs 14 in the NAA

Proverbs 14 in the NASB

Proverbs 14 in the NBLA

Proverbs 14 in the NBS

Proverbs 14 in the NBVTP

Proverbs 14 in the NET2

Proverbs 14 in the NIV11

Proverbs 14 in the NNT

Proverbs 14 in the NNT2

Proverbs 14 in the NNT3

Proverbs 14 in the PDDPT

Proverbs 14 in the PFNT

Proverbs 14 in the RMNT

Proverbs 14 in the SBIAS

Proverbs 14 in the SBIBS

Proverbs 14 in the SBIBS2

Proverbs 14 in the SBICS

Proverbs 14 in the SBIDS

Proverbs 14 in the SBIGS

Proverbs 14 in the SBIHS

Proverbs 14 in the SBIIS

Proverbs 14 in the SBIIS2

Proverbs 14 in the SBIIS3

Proverbs 14 in the SBIKS

Proverbs 14 in the SBIKS2

Proverbs 14 in the SBIMS

Proverbs 14 in the SBIOS

Proverbs 14 in the SBIPS

Proverbs 14 in the SBISS

Proverbs 14 in the SBITS

Proverbs 14 in the SBITS2

Proverbs 14 in the SBITS3

Proverbs 14 in the SBITS4

Proverbs 14 in the SBIUS

Proverbs 14 in the SBIVS

Proverbs 14 in the SBT

Proverbs 14 in the SBT1E

Proverbs 14 in the SCHL

Proverbs 14 in the SNT

Proverbs 14 in the SUSU

Proverbs 14 in the SUSU2

Proverbs 14 in the SYNO

Proverbs 14 in the TBIAOTANT

Proverbs 14 in the TBT1E

Proverbs 14 in the TBT1E2

Proverbs 14 in the TFTIP

Proverbs 14 in the TFTU

Proverbs 14 in the TGNTATF3T

Proverbs 14 in the THAI

Proverbs 14 in the TNFD

Proverbs 14 in the TNT

Proverbs 14 in the TNTIK

Proverbs 14 in the TNTIL

Proverbs 14 in the TNTIN

Proverbs 14 in the TNTIP

Proverbs 14 in the TNTIZ

Proverbs 14 in the TOMA

Proverbs 14 in the TTENT

Proverbs 14 in the UBG

Proverbs 14 in the UGV

Proverbs 14 in the UGV2

Proverbs 14 in the UGV3

Proverbs 14 in the VBL

Proverbs 14 in the VDCC

Proverbs 14 in the YALU

Proverbs 14 in the YAPE

Proverbs 14 in the YBVTP

Proverbs 14 in the ZBP