1 Peter 1 (BOYCB)
1 Peteru, aposteli Jesu Kristi, Sí àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run, ti wọ́n ń ṣe àtìpó ní àgbáyé, tiwọn tú káàkiri sí Pọntu, Galatia, Kappadokia, Asia, àti Bitinia, 2 àwọn ẹni tí a ti yàn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Baba, nípa ìsọdimímọ́ Ẹ̀mí, sí ìgbọ́ràn àti ìbùwọ́n ẹ̀jẹ̀ Jesu Kristi: Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà máa bí sì fún yín. 3 Ìyìn yẹ Ọlọ́run àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa! Ẹni tí ó tún wa bí gẹ́gẹ́ bí àánú ńlá rẹ̀ sínú ìrètí ààyè nípa àjíǹde Jesu Kristi kúrò nínú òkú, 4 àti sínú ogún àìdíbàjẹ́, àti àìlábàwọ́n, àti èyí tí kì í ṣá, tí a ti fi pamọ́ ni ọ̀run dè yin, 5 ẹyin tí a ń pamọ́ nípa agbára Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ si ìgbàlà, tí a múra láti fihàn ní ìgbà ìkẹyìn. 6 Ẹ yọ̀ nínú èyí púpọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe nísinsin yìí fún ìgbà díẹ̀, níwọ̀n bí ó ti yẹ, a ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdánwò bá yín nínú jẹ́. 7 Àwọn wọ̀nyí sì wáyé ki ìdánwò ìgbàgbọ́ yín tí ó ni iye lórí ju wúrà, ti ń ṣègbé lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iná ni a fi ń dán an wò, lè yọrísí ìyìn àti ògo àti ọlá ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi. 8 Ẹni tí ẹ̀yin fẹ́ láìrí, ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí i nísinsin yìí ẹ̀yin sì ń yọ ayọ̀ tí a kò lè fi ẹnu sọ, tí ó sì kún fún ògo; 9 ẹyin sì ń gba ìlépa ìgbàgbọ́ yín, àní ìgbàlà ọkàn yín. 10 Ní ti ìgbàlà yìí, àwọn wòlíì tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa oore-ọ̀fẹ́ tí ó mú tọ̀ yín wá, wọ́n wádìí jinlẹ̀ lẹ́sọ̀ lẹ́sọ̀. 11 Wọ́n ń wádìí ìgbà wo tàbí irú sá à wo ni Ẹ̀mí Kristi tí ó wà nínú wọ́n ń tọ́ka sí, nígbà tí ó jẹ́rìí ìyà Kristi àti ògo tí yóò tẹ̀lé e. 12 Àwọn ẹni tí a fihàn fún, pé kì í ṣe fún àwọn tìkára wọn, bí kò ṣe fún àwa ni wọ́n ṣe ìránṣẹ́ ohun wọ̀n-ọn-nì, tí a ti ròyìn fún yin nísinsin yìí, láti ọ̀dọ̀ àwọn tó ti ń wàásù ìyìnrere náà fún yín nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a rán wá láti ọ̀run; ohun tí àwọn angẹli ń fẹ́ láti wò. 13 Nítorí náà, ẹ múra ọkàn yín sílẹ̀, ẹ kó ara yín ní ìjánu, kí ẹ sì fi ìrètí yín ní kíkún sí oore-ọ̀fẹ́, èyí tí a ń mu bọ̀ fún yin ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi. 14 Bí àwọn ọmọ tí ń gbọ́rọ̀, ẹ ma ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìmọ́ yín ti àtijọ́. 15 Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹni tí o pè yin ti jẹ mímọ́; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà jẹ mímọ́. 16 Nítorí a ti kọ ọ pé, “Ẹ jẹ́ mímọ́: nítorí tí Èmi jẹ mímọ́!” 17 Níwọ́n bí ẹ̀yin ti ń ké pe Baba, ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ olúkúlùkù láìṣe ojúsàájú, ẹ máa lo ìgbà àtìpó yin ni ìbẹ̀rù. 18 Níwọ̀n bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé a kò fi ohun ìdíbàjẹ́ rà yín padà, bí fàdákà tàbí wúrà kúrò nínú ìwà asán yín, tí ẹ̀yin ti jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba yín. 19 Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ iyebíye, bí i ti ọ̀dọ́-àgùntàn ti kò lábùkù, tí kò sì lábàwọ́n, àní, ẹ̀jẹ̀ Kristi. 20 Ẹni tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nítòótọ́ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, ṣùgbọ́n tí a fihàn ní ìgbà ìkẹyìn wọ̀nyí nítorí yín. 21 Àní ẹ̀yin tí o tipasẹ̀ rẹ̀ gba Ọlọ́run gbọ́, ẹni ti ó jí i dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì fi ògo fún un; kí ìgbàgbọ́ àti ìrètí yín lè wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run. 22 Níwọ́n bí ẹ̀yin ti wẹ ọkàn yin mọ́ nípa ìgbọ́ràn yín sí òtítọ́ sí ìfẹ́ ará ti kò ní ẹ̀tàn, ẹ fẹ́ ọmọnìkejì yín gidigidi láti ọkàn wá. 23 Bí a ti tún yín bí, kì í ṣe láti inú ìdíbàjẹ́ wá, bí kò ṣe èyí ti kì í díbàjẹ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń bẹ láààyè tí ó sì dúró. 24 Nítorí pé,“Gbogbo ènìyàn dàbí koríko,àti gbogbo ògo rẹ̀ bi ìtànná koríko.Koríko á máa gbẹ ìtànná a sì máa rẹ̀ dànù, 25 ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa dúró títí láé.”Ọ̀rọ̀ náà yìí sì ni ìyìnrere tí a wàásù fún yín.
In Other Versions
1 Peter 1 in the ANGEFD
1 Peter 1 in the ANTPNG2D
1 Peter 1 in the AS21
1 Peter 1 in the BAGH
1 Peter 1 in the BBPNG
1 Peter 1 in the BBT1E
1 Peter 1 in the BDS
1 Peter 1 in the BEV
1 Peter 1 in the BHAD
1 Peter 1 in the BIB
1 Peter 1 in the BLPT
1 Peter 1 in the BNT
1 Peter 1 in the BNTABOOT
1 Peter 1 in the BNTLV
1 Peter 1 in the BOATCB
1 Peter 1 in the BOATCB2
1 Peter 1 in the BOBCV
1 Peter 1 in the BOCNT
1 Peter 1 in the BOECS
1 Peter 1 in the BOGWICC
1 Peter 1 in the BOHCB
1 Peter 1 in the BOHCV
1 Peter 1 in the BOHLNT
1 Peter 1 in the BOHNTLTAL
1 Peter 1 in the BOICB
1 Peter 1 in the BOILNTAP
1 Peter 1 in the BOITCV
1 Peter 1 in the BOKCV
1 Peter 1 in the BOKCV2
1 Peter 1 in the BOKHWOG
1 Peter 1 in the BOKSSV
1 Peter 1 in the BOLCB
1 Peter 1 in the BOLCB2
1 Peter 1 in the BOMCV
1 Peter 1 in the BONAV
1 Peter 1 in the BONCB
1 Peter 1 in the BONLT
1 Peter 1 in the BONUT2
1 Peter 1 in the BOPLNT
1 Peter 1 in the BOSCB
1 Peter 1 in the BOSNC
1 Peter 1 in the BOTLNT
1 Peter 1 in the BOVCB
1 Peter 1 in the BPBB
1 Peter 1 in the BPH
1 Peter 1 in the BSB
1 Peter 1 in the CCB
1 Peter 1 in the CUV
1 Peter 1 in the CUVS
1 Peter 1 in the DBT
1 Peter 1 in the DGDNT
1 Peter 1 in the DHNT
1 Peter 1 in the DNT
1 Peter 1 in the ELBE
1 Peter 1 in the EMTV
1 Peter 1 in the ESV
1 Peter 1 in the FBV
1 Peter 1 in the FEB
1 Peter 1 in the GGMNT
1 Peter 1 in the GNT
1 Peter 1 in the HARY
1 Peter 1 in the HNT
1 Peter 1 in the IRVA
1 Peter 1 in the IRVB
1 Peter 1 in the IRVG
1 Peter 1 in the IRVH
1 Peter 1 in the IRVK
1 Peter 1 in the IRVM
1 Peter 1 in the IRVM2
1 Peter 1 in the IRVO
1 Peter 1 in the IRVP
1 Peter 1 in the IRVT
1 Peter 1 in the IRVT2
1 Peter 1 in the IRVU
1 Peter 1 in the ISVN
1 Peter 1 in the JSNT
1 Peter 1 in the KAPI
1 Peter 1 in the KBT1ETNIK
1 Peter 1 in the KBV
1 Peter 1 in the KJV
1 Peter 1 in the KNFD
1 Peter 1 in the LBA
1 Peter 1 in the LBLA
1 Peter 1 in the LNT
1 Peter 1 in the LSV
1 Peter 1 in the MAAL
1 Peter 1 in the MBV
1 Peter 1 in the MBV2
1 Peter 1 in the MHNT
1 Peter 1 in the MKNFD
1 Peter 1 in the MNG
1 Peter 1 in the MNT
1 Peter 1 in the MNT2
1 Peter 1 in the MRS1T
1 Peter 1 in the NAA
1 Peter 1 in the NASB
1 Peter 1 in the NBLA
1 Peter 1 in the NBS
1 Peter 1 in the NBVTP
1 Peter 1 in the NET2
1 Peter 1 in the NIV11
1 Peter 1 in the NNT
1 Peter 1 in the NNT2
1 Peter 1 in the NNT3
1 Peter 1 in the PDDPT
1 Peter 1 in the PFNT
1 Peter 1 in the RMNT
1 Peter 1 in the SBIAS
1 Peter 1 in the SBIBS
1 Peter 1 in the SBIBS2
1 Peter 1 in the SBICS
1 Peter 1 in the SBIDS
1 Peter 1 in the SBIGS
1 Peter 1 in the SBIHS
1 Peter 1 in the SBIIS
1 Peter 1 in the SBIIS2
1 Peter 1 in the SBIIS3
1 Peter 1 in the SBIKS
1 Peter 1 in the SBIKS2
1 Peter 1 in the SBIMS
1 Peter 1 in the SBIOS
1 Peter 1 in the SBIPS
1 Peter 1 in the SBISS
1 Peter 1 in the SBITS
1 Peter 1 in the SBITS2
1 Peter 1 in the SBITS3
1 Peter 1 in the SBITS4
1 Peter 1 in the SBIUS
1 Peter 1 in the SBIVS
1 Peter 1 in the SBT
1 Peter 1 in the SBT1E
1 Peter 1 in the SCHL
1 Peter 1 in the SNT
1 Peter 1 in the SUSU
1 Peter 1 in the SUSU2
1 Peter 1 in the SYNO
1 Peter 1 in the TBIAOTANT
1 Peter 1 in the TBT1E
1 Peter 1 in the TBT1E2
1 Peter 1 in the TFTIP
1 Peter 1 in the TFTU
1 Peter 1 in the TGNTATF3T
1 Peter 1 in the THAI
1 Peter 1 in the TNFD
1 Peter 1 in the TNT
1 Peter 1 in the TNTIK
1 Peter 1 in the TNTIL
1 Peter 1 in the TNTIN
1 Peter 1 in the TNTIP
1 Peter 1 in the TNTIZ
1 Peter 1 in the TOMA
1 Peter 1 in the TTENT
1 Peter 1 in the UBG
1 Peter 1 in the UGV
1 Peter 1 in the UGV2
1 Peter 1 in the UGV3
1 Peter 1 in the VBL
1 Peter 1 in the VDCC
1 Peter 1 in the YALU
1 Peter 1 in the YAPE
1 Peter 1 in the YBVTP
1 Peter 1 in the ZBP