Isaiah 65 (BOYCB)

1 “Èmi fi ara mi hàn fún àwọn tí kò béèrè fún mi;àwọn tí kò wá mi ni wọ́n rí mi.Sí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò pe orúkọ mi,ni èmi wí pé, ‘Èmi nìyìí, Èmi nìyìí.’ 2 Gbogbo ọjọ́ ni mo ti nawọ́ mi sítasí àwọn ènìyàn ọlọ́rùn líle,tí wọn ń rìn lọ́nà tí kò dára,tí wọ́n sì gbára lé èrò ara wọn 3 àwọn ènìyàn tí wọ́n bí mi nínú nígbà gbogbolójú ara mi gan an,wọ́n ń rú ẹbọ nínú ọgbàwọ́n sì ń sun tùràrí lórí i pẹpẹ bíríkì; 4 wọ́n ń jókòó láàrín ibojìwọ́n sì ń lo òru wọn nínú ìṣọ́ ìkọ̀kọ̀;tí wọ́n ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀,tí ìkòkò ọbẹ̀ wọn kún fún ẹran àìmọ́; 5 tí ó wí pé, ‘Ẹ sún mẹ́yìn; ẹ má wá sọ́dọ̀ mi,nítorí mo ti jẹ́ mímọ́ jù fún un yín!’Àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ jẹ́ èéfín nínú ihò imú miiná tí ń fi gbogbo ọjọ́ jó. 6 “Kíyèsi i, a ti kọ ọ́ síwájú mi,Èmi kì yóò dákẹ́,ṣùgbọ́n èmi yóò san án padà lẹ́kùnrẹ́rẹ́;Èmi yóò san án padà sí àyà wọn 7 àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín àti tàwọn baba yín,”ni OLÚWA wí.“Nítorí pé wọ́n sun ẹbọ ní orí òkè ńláwọ́n sì ṣe ẹ̀gbin sí mi ní òkè kékeré,Èmi yóò wọ́n ọ́n sí itan wọnẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹ̀san ohun gbogbo tí wọ́n ṣe tẹ́lẹ̀.” 8 Báyìí ni OLÚWA wí:“Gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí oje sì tún wà nínú àpólà àjàràtí àwọn ènìyàn sì wí pé, ‘Má ṣe bà á jẹ́,nítorí ìbùkún ń bẹ nínú rẹ̀,’bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣe nítorí ìránṣẹ́ mi;Èmi kì yóò pa gbogbo wọn run. 9 Èmi yóò mú ìrandíran wá láti ìdílé Jakọbu,àti láti Juda àwọn tí yóò jogún òkè ńlá mi wọ̀n-ọn-nì;àwọn àyànfẹ́ ènìyàn mi yóò jogún wọn,ibẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ mi yóò sì gbé. 10 Ṣaroni yóò di pápá oko fún ọ̀wọ́ ẹran,àti àfonífojì Akori yóò di ibi ìsinmi fún agbo ẹran,fún àwọn ènìyàn mi tí ó wá mi. 11 “Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yin tí ó kọ OLÚWA sílẹ̀tí ó sì gbàgbé òkè ńlá mímọ́ mi,tí ó tẹ́ tábìlì fún Gadití ẹ sì kún abọ́ pẹ̀lú ọtí wáìnì fún àtubọ̀tán, 12 Èmi yóò yà ọ́ sọ́tọ̀ fún idà,àti pé ẹ̀yin yóò bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ fún àwọn tí a pa;nítorí mo pè, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò dáhùn.Mo sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò tẹ́tí sílẹ̀.Ẹ̀yin ṣe búburú ní ojú miẹ sì yan ohun tí ó bà mí lọ́kàn jẹ́.” 13 Nítorí náà, báyìí ni OLÚWA Olódùmarè wí:“Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò jẹun;ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ẹ̀yin,àwọn ìránṣẹ́ mi yóò mu,ṣùgbọ́n òǹgbẹ yóò máa gbẹ ẹ̀yin;àwọn ìránṣẹ́ mi yóò ṣe àjọyọ̀,ṣùgbọ́n a ó dójútì yin. 14 Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò kọrinláti inú ayọ̀ ọkàn wọn wá,ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò kígbe sókèláti inú ìrora ọkàn yínàti ìpohùnréré ní ìròbìnújẹ́ ọkàn. 15 Ẹ̀yin yóò fi orúkọ yín sílẹ̀fún àwọn àyànfẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí ègún; OLÚWA Olódùmarè yóò sì pa yín,ṣùgbọ́n fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni òunyóò fún ní orúkọ mìíràn. 16 Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàdúrà ìbùkún ní ilẹ̀ náàyóò ṣe é nípasẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́;Ẹni tí ó bá búra ní ilẹ̀ náàyóò búra nípasẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́.Nítorí ìyọnu àtijọ́ yóò di ìgbàgbéyóò sì fi ara sin kúrò lójú mi. 17 “Kíyèsi i, Èmi yóò dáàwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun.A kì yóò rántí ohun àtẹ̀yìnwá mọ́,tàbí kí wọn wá sí ọkàn. 18 Ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ kí inú yín dùn títí láénínú ohun tí èmi yóò dá,nítorí èmi yóò dá Jerusalẹmu láti jẹ́ ohun ìdùnnúàti àwọn ènìyàn rẹ̀, ohun ayọ̀. 19 Èmi yóò ṣe àjọyọ̀ lórí Jerusalẹmun ó sì ní inú dídùn nínú àwọn ènìyàn mi;ariwo ẹkún àti igbeni a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ mọ́. 20 “Títí láé a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ọmọ ọwọ́ tí yóò gbé fún ọjọ́ díẹ̀,tàbí àgbàlagbà tí kì yóò lo ọjọ́ ayé rẹ̀ tán;ẹni tí ó bá kú ní ìwọ̀n ọgọ́rùn-únni a ó pè ní ọ̀dọ́mọdé;ẹni tí kò ba le pé ọgọ́rùn-ún kanni a ó pè ní ẹni ìfibú. 21 Wọn yó ò kọ́ ilé, wọn yóò sì gbé nínú wọnwọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì jẹ èso wọn. 22 Wọn kì yóò kọ́ ilé fún ẹlòmíràn láti gbé,tàbí kí wọn gbìn fún ẹlòmíràn láti jẹ.Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí igi kan,bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí;àwọn àyànfẹ́ mi yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́wọn fún ìgbà pípẹ́. 23 Wọn kì yóò ṣe iṣẹ́ lásán,wọn kí yóò bímọ fún wàhálà;nítorí wọn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn ti OLÚWA bùkún fún,àwọn àti àwọn ìrandíran wọn pẹ̀lú wọn. 24 Kí wọn tó pè, èmi yóò dáhùn;nígbà tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, èmi yóò gbọ́. 25 Ìkookò àti ọ̀dọ́-àgùntàn yóò jẹun pọ̀,kìnnìún yóò sì jẹ koríko gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù,ṣùgbọ́n erùpẹ̀ ni yóò jẹ́ oúnjẹ ejò.Wọn kì yóò pa ni lára tàbí pa ni runní gbogbo òkè mímọ́ mi,”ni OLÚWA wí.

In Other Versions

Isaiah 65 in the ANGEFD

Isaiah 65 in the ANTPNG2D

Isaiah 65 in the AS21

Isaiah 65 in the BAGH

Isaiah 65 in the BBPNG

Isaiah 65 in the BBT1E

Isaiah 65 in the BDS

Isaiah 65 in the BEV

Isaiah 65 in the BHAD

Isaiah 65 in the BIB

Isaiah 65 in the BLPT

Isaiah 65 in the BNT

Isaiah 65 in the BNTABOOT

Isaiah 65 in the BNTLV

Isaiah 65 in the BOATCB

Isaiah 65 in the BOATCB2

Isaiah 65 in the BOBCV

Isaiah 65 in the BOCNT

Isaiah 65 in the BOECS

Isaiah 65 in the BOGWICC

Isaiah 65 in the BOHCB

Isaiah 65 in the BOHCV

Isaiah 65 in the BOHLNT

Isaiah 65 in the BOHNTLTAL

Isaiah 65 in the BOICB

Isaiah 65 in the BOILNTAP

Isaiah 65 in the BOITCV

Isaiah 65 in the BOKCV

Isaiah 65 in the BOKCV2

Isaiah 65 in the BOKHWOG

Isaiah 65 in the BOKSSV

Isaiah 65 in the BOLCB

Isaiah 65 in the BOLCB2

Isaiah 65 in the BOMCV

Isaiah 65 in the BONAV

Isaiah 65 in the BONCB

Isaiah 65 in the BONLT

Isaiah 65 in the BONUT2

Isaiah 65 in the BOPLNT

Isaiah 65 in the BOSCB

Isaiah 65 in the BOSNC

Isaiah 65 in the BOTLNT

Isaiah 65 in the BOVCB

Isaiah 65 in the BPBB

Isaiah 65 in the BPH

Isaiah 65 in the BSB

Isaiah 65 in the CCB

Isaiah 65 in the CUV

Isaiah 65 in the CUVS

Isaiah 65 in the DBT

Isaiah 65 in the DGDNT

Isaiah 65 in the DHNT

Isaiah 65 in the DNT

Isaiah 65 in the ELBE

Isaiah 65 in the EMTV

Isaiah 65 in the ESV

Isaiah 65 in the FBV

Isaiah 65 in the FEB

Isaiah 65 in the GGMNT

Isaiah 65 in the GNT

Isaiah 65 in the HARY

Isaiah 65 in the HNT

Isaiah 65 in the IRVA

Isaiah 65 in the IRVB

Isaiah 65 in the IRVG

Isaiah 65 in the IRVH

Isaiah 65 in the IRVK

Isaiah 65 in the IRVM

Isaiah 65 in the IRVM2

Isaiah 65 in the IRVO

Isaiah 65 in the IRVP

Isaiah 65 in the IRVT

Isaiah 65 in the IRVT2

Isaiah 65 in the IRVU

Isaiah 65 in the ISVN

Isaiah 65 in the JSNT

Isaiah 65 in the KAPI

Isaiah 65 in the KBT1ETNIK

Isaiah 65 in the KBV

Isaiah 65 in the KJV

Isaiah 65 in the KNFD

Isaiah 65 in the LBA

Isaiah 65 in the LBLA

Isaiah 65 in the LNT

Isaiah 65 in the LSV

Isaiah 65 in the MAAL

Isaiah 65 in the MBV

Isaiah 65 in the MBV2

Isaiah 65 in the MHNT

Isaiah 65 in the MKNFD

Isaiah 65 in the MNG

Isaiah 65 in the MNT

Isaiah 65 in the MNT2

Isaiah 65 in the MRS1T

Isaiah 65 in the NAA

Isaiah 65 in the NASB

Isaiah 65 in the NBLA

Isaiah 65 in the NBS

Isaiah 65 in the NBVTP

Isaiah 65 in the NET2

Isaiah 65 in the NIV11

Isaiah 65 in the NNT

Isaiah 65 in the NNT2

Isaiah 65 in the NNT3

Isaiah 65 in the PDDPT

Isaiah 65 in the PFNT

Isaiah 65 in the RMNT

Isaiah 65 in the SBIAS

Isaiah 65 in the SBIBS

Isaiah 65 in the SBIBS2

Isaiah 65 in the SBICS

Isaiah 65 in the SBIDS

Isaiah 65 in the SBIGS

Isaiah 65 in the SBIHS

Isaiah 65 in the SBIIS

Isaiah 65 in the SBIIS2

Isaiah 65 in the SBIIS3

Isaiah 65 in the SBIKS

Isaiah 65 in the SBIKS2

Isaiah 65 in the SBIMS

Isaiah 65 in the SBIOS

Isaiah 65 in the SBIPS

Isaiah 65 in the SBISS

Isaiah 65 in the SBITS

Isaiah 65 in the SBITS2

Isaiah 65 in the SBITS3

Isaiah 65 in the SBITS4

Isaiah 65 in the SBIUS

Isaiah 65 in the SBIVS

Isaiah 65 in the SBT

Isaiah 65 in the SBT1E

Isaiah 65 in the SCHL

Isaiah 65 in the SNT

Isaiah 65 in the SUSU

Isaiah 65 in the SUSU2

Isaiah 65 in the SYNO

Isaiah 65 in the TBIAOTANT

Isaiah 65 in the TBT1E

Isaiah 65 in the TBT1E2

Isaiah 65 in the TFTIP

Isaiah 65 in the TFTU

Isaiah 65 in the TGNTATF3T

Isaiah 65 in the THAI

Isaiah 65 in the TNFD

Isaiah 65 in the TNT

Isaiah 65 in the TNTIK

Isaiah 65 in the TNTIL

Isaiah 65 in the TNTIN

Isaiah 65 in the TNTIP

Isaiah 65 in the TNTIZ

Isaiah 65 in the TOMA

Isaiah 65 in the TTENT

Isaiah 65 in the UBG

Isaiah 65 in the UGV

Isaiah 65 in the UGV2

Isaiah 65 in the UGV3

Isaiah 65 in the VBL

Isaiah 65 in the VDCC

Isaiah 65 in the YALU

Isaiah 65 in the YAPE

Isaiah 65 in the YBVTP

Isaiah 65 in the ZBP