Jeremiah 30 (BOYCB)
1 Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ OLÚWA wá, wí pé: 2 “Báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run Israẹli wí, pé: ‘Ìwọ kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti bá ọ sọ sínú ìwé kan. 3 Ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí ń ó mú àwọn ènìyàn mi, àwọn ọmọ Israẹli àti Juda kúrò nínú ìgbèkùn, tí n ó sì dá wọn padà sí orí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá wọn láti ní,’ ni OLÚWA Ọlọ́run wí.” 4 Ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ OLÚWA Ọlọ́run sí Israẹli àti Juda: 5 “Èyí ni ohun tí OLÚWA wí:“ ‘Igbe ẹ̀rù àti ìwárìrì ni a gbọ́láìṣe igbe àlàáfíà. 6 Béèrè kí o sì rí.Ǹjẹ́ ọkùnrin le dá ọmọ bí?Èéṣe tí mo fi ń rí àwọn alágbára ọkùnrintí wọ́n fi ọwọ́ wọn mú inú wọn bí obìnrin tó ń rọbí,tí ojú gbogbo wọ́n sì fàro fún ìrora? 7 Ọjọ́ náà yóò ha ti burú tó!Kò sí ọjọ́ tí yóò dàbí rẹ̀,Ọjọ́ náà yóò jẹ́ àkókò ìdààmú fún Jakọbuṣùgbọ́n yóò rí ìgbàlà kúrò nínú ìdààmú náà. 8 “ ‘Ní ọjọ́ náà,’ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí pé,‘Èmi yóò gbé àjàgà kúrò lọ́rùn wọn,Èmi yóò sì tú ìdè wọn sọnù.Àwọn àjèjì kì yóò sì mú ọ sìn wọ́n mọ́. 9 Dípò bẹ́ẹ̀ wọn yóò máa sin OLÚWA Ọlọ́run wọnàti Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba wọn,ẹni tí èmi yóò gbé dìde fún wọn. 10 “ ‘Nítorí náà, má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi,má sì ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, ìwọ Israẹli,’ni OLÚWA wí.‘Èmi yóò gbà ọ́ kúrò láti ọ̀nà jíjìn wá,àní àwọn ìran rẹ láti ilẹ̀ àtìpó wọn.Jakọbu yóò sì tún ní àlàáfíà àti ààbò rẹ̀ padà,kò sì ṣí ẹni tí yóò ṣẹ̀rù bà á mọ́. 11 Èmi wà pẹ̀lú rẹ, n ó sì gbà ọ́,’ni OLÚWA wí.‘Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀-èdè run,nínú èyí tí mo ti fọ́n ọn yín ká,síbẹ̀ èmi kì yóò pa yín run pátápátá.Èmi yóò bá yín wí pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo nìkan;Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìjìyà.’ 12 “Èyí ni ohun tí OLÚWA wí:“ ‘Ọgbẹ́ yín kò gbóògùn,bẹ́ẹ̀ ni egbò yín kọjá ìwòsàn. 13 Kò sí ẹnìkan tí yóò bẹ̀bẹ̀ fún àìṣedéédéé yín,kò sí ètùtù fún ọgbẹ́ yín,a kò sì mú yín láradá. 14 Gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ ti gbàgbé rẹ,wọn kò sì náání rẹ mọ́ pẹ̀lú.Mo ti nà ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá rẹ yóò ti nà ọ,mo sì bá a ọ wí gẹ́gẹ́ bí ìkà,nítorí tí ẹ̀bi rẹ pọ̀ púpọ̀,ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kò sì lóǹkà. 15 Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń kígbe nítorí ọgbẹ́ yín,ìrora yín èyí tí kò ní oògùn?Nítorí ọ̀pọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ yín àti ẹ̀bi yín tó gani mo fi ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí sí i yín. 16 “ ‘Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe yín ní ibi ni ibi yóò bá,àní gbogbo àwọn ọ̀tá yín ni a ó sọ di àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì;gbogbo àwọn tí wọ́n bà yín jẹ́ ni a ó bàjẹ́. 17 Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìlera fún yín,èmi yóò sì wo ọ̀gbẹ́ yín sàn,’ ni OLÚWA wí,‘nítorí tí a pè yín ní alárìnkiri,Sioni tí gbogbo ènìyàn dágunlá sí.’ 18 “Èyí ni ohun tí OLÚWA wí:“ ‘Èmi yóò dá gbogbo ìre àgọ́ Jakọbu padà,èmi yóò sì ṣe àánú fún olùgbé àgọ́ rẹ̀;ìlú náà yóò sì di títúnṣetí ààfin ìlú náà yóò sì wà ní ipò rẹ̀. 19 Láti ẹnu wọn ni orin ọpẹ́ àtiìyìn yóò sì ti máa jáde.Èmi yóò sọ wọ́n di púpọ̀,wọn kì yóò sì dínkù ní iye,Èmi yóò fi ọlá fún wọn,wọn kò sì ní di ẹni àbùkù. 20 Ọmọ ọmọ wọn yóò wà bí i ti ìgbàanìníwájú mi ni wọn yóò sì tẹ àwùjọ wọn dúró sí.Gbogbo ẹni tó bá ni wọ́n lára,ni èmi yóò fì ìyà jẹ. 21 Ọ̀kan nínú wọn ni yóò jẹ́ olórí wọn,ọba wọn yóò dìde láti àárín wọn.Èmi yóò mú un wá sí ọ̀dọ̀ mi, òun yóò sì súnmọ́ mi,nítorí ta ni ẹni náà tí yóò fi ara rẹ̀ jì láti súnmọ́ mi?’ni OLÚWA wí. 22 ‘Nítorí náà, ẹ̀yin yóò jẹ́ ènìyàn mi,èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín.’ ” 23 Wò ó, ìbínú OLÚWA yóò tú jáde,ìjì líle yóò sì sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn ènìyàn búburú. 24 Ìbínú ńlá OLÚWA kò ní dẹ̀yìn lẹ́yìnàwọn ìkà títí yóò fi múèrò ọkàn rẹ̀ ṣẹ.Ní àìpẹ́ ọjọ́,òye rẹ̀ yóò yé e yín.
In Other Versions
Jeremiah 30 in the ANGEFD
Jeremiah 30 in the ANTPNG2D
Jeremiah 30 in the AS21
Jeremiah 30 in the BAGH
Jeremiah 30 in the BBPNG
Jeremiah 30 in the BBT1E
Jeremiah 30 in the BDS
Jeremiah 30 in the BEV
Jeremiah 30 in the BHAD
Jeremiah 30 in the BIB
Jeremiah 30 in the BLPT
Jeremiah 30 in the BNT
Jeremiah 30 in the BNTABOOT
Jeremiah 30 in the BNTLV
Jeremiah 30 in the BOATCB
Jeremiah 30 in the BOATCB2
Jeremiah 30 in the BOBCV
Jeremiah 30 in the BOCNT
Jeremiah 30 in the BOECS
Jeremiah 30 in the BOGWICC
Jeremiah 30 in the BOHCB
Jeremiah 30 in the BOHCV
Jeremiah 30 in the BOHLNT
Jeremiah 30 in the BOHNTLTAL
Jeremiah 30 in the BOICB
Jeremiah 30 in the BOILNTAP
Jeremiah 30 in the BOITCV
Jeremiah 30 in the BOKCV
Jeremiah 30 in the BOKCV2
Jeremiah 30 in the BOKHWOG
Jeremiah 30 in the BOKSSV
Jeremiah 30 in the BOLCB
Jeremiah 30 in the BOLCB2
Jeremiah 30 in the BOMCV
Jeremiah 30 in the BONAV
Jeremiah 30 in the BONCB
Jeremiah 30 in the BONLT
Jeremiah 30 in the BONUT2
Jeremiah 30 in the BOPLNT
Jeremiah 30 in the BOSCB
Jeremiah 30 in the BOSNC
Jeremiah 30 in the BOTLNT
Jeremiah 30 in the BOVCB
Jeremiah 30 in the BPBB
Jeremiah 30 in the BPH
Jeremiah 30 in the BSB
Jeremiah 30 in the CCB
Jeremiah 30 in the CUV
Jeremiah 30 in the CUVS
Jeremiah 30 in the DBT
Jeremiah 30 in the DGDNT
Jeremiah 30 in the DHNT
Jeremiah 30 in the DNT
Jeremiah 30 in the ELBE
Jeremiah 30 in the EMTV
Jeremiah 30 in the ESV
Jeremiah 30 in the FBV
Jeremiah 30 in the FEB
Jeremiah 30 in the GGMNT
Jeremiah 30 in the GNT
Jeremiah 30 in the HARY
Jeremiah 30 in the HNT
Jeremiah 30 in the IRVA
Jeremiah 30 in the IRVB
Jeremiah 30 in the IRVG
Jeremiah 30 in the IRVH
Jeremiah 30 in the IRVK
Jeremiah 30 in the IRVM
Jeremiah 30 in the IRVM2
Jeremiah 30 in the IRVO
Jeremiah 30 in the IRVP
Jeremiah 30 in the IRVT
Jeremiah 30 in the IRVT2
Jeremiah 30 in the IRVU
Jeremiah 30 in the ISVN
Jeremiah 30 in the JSNT
Jeremiah 30 in the KAPI
Jeremiah 30 in the KBT1ETNIK
Jeremiah 30 in the KBV
Jeremiah 30 in the KJV
Jeremiah 30 in the KNFD
Jeremiah 30 in the LBA
Jeremiah 30 in the LBLA
Jeremiah 30 in the LNT
Jeremiah 30 in the LSV
Jeremiah 30 in the MAAL
Jeremiah 30 in the MBV
Jeremiah 30 in the MBV2
Jeremiah 30 in the MHNT
Jeremiah 30 in the MKNFD
Jeremiah 30 in the MNG
Jeremiah 30 in the MNT
Jeremiah 30 in the MNT2
Jeremiah 30 in the MRS1T
Jeremiah 30 in the NAA
Jeremiah 30 in the NASB
Jeremiah 30 in the NBLA
Jeremiah 30 in the NBS
Jeremiah 30 in the NBVTP
Jeremiah 30 in the NET2
Jeremiah 30 in the NIV11
Jeremiah 30 in the NNT
Jeremiah 30 in the NNT2
Jeremiah 30 in the NNT3
Jeremiah 30 in the PDDPT
Jeremiah 30 in the PFNT
Jeremiah 30 in the RMNT
Jeremiah 30 in the SBIAS
Jeremiah 30 in the SBIBS
Jeremiah 30 in the SBIBS2
Jeremiah 30 in the SBICS
Jeremiah 30 in the SBIDS
Jeremiah 30 in the SBIGS
Jeremiah 30 in the SBIHS
Jeremiah 30 in the SBIIS
Jeremiah 30 in the SBIIS2
Jeremiah 30 in the SBIIS3
Jeremiah 30 in the SBIKS
Jeremiah 30 in the SBIKS2
Jeremiah 30 in the SBIMS
Jeremiah 30 in the SBIOS
Jeremiah 30 in the SBIPS
Jeremiah 30 in the SBISS
Jeremiah 30 in the SBITS
Jeremiah 30 in the SBITS2
Jeremiah 30 in the SBITS3
Jeremiah 30 in the SBITS4
Jeremiah 30 in the SBIUS
Jeremiah 30 in the SBIVS
Jeremiah 30 in the SBT
Jeremiah 30 in the SBT1E
Jeremiah 30 in the SCHL
Jeremiah 30 in the SNT
Jeremiah 30 in the SUSU
Jeremiah 30 in the SUSU2
Jeremiah 30 in the SYNO
Jeremiah 30 in the TBIAOTANT
Jeremiah 30 in the TBT1E
Jeremiah 30 in the TBT1E2
Jeremiah 30 in the TFTIP
Jeremiah 30 in the TFTU
Jeremiah 30 in the TGNTATF3T
Jeremiah 30 in the THAI
Jeremiah 30 in the TNFD
Jeremiah 30 in the TNT
Jeremiah 30 in the TNTIK
Jeremiah 30 in the TNTIL
Jeremiah 30 in the TNTIN
Jeremiah 30 in the TNTIP
Jeremiah 30 in the TNTIZ
Jeremiah 30 in the TOMA
Jeremiah 30 in the TTENT
Jeremiah 30 in the UBG
Jeremiah 30 in the UGV
Jeremiah 30 in the UGV2
Jeremiah 30 in the UGV3
Jeremiah 30 in the VBL
Jeremiah 30 in the VDCC
Jeremiah 30 in the YALU
Jeremiah 30 in the YAPE
Jeremiah 30 in the YBVTP
Jeremiah 30 in the ZBP