John 11 (BOYCB)

1 Ara ọkùnrin kan kò sì dá, Lasaru, ará Betani, tí í ṣe ìlú Maria àti Marta arábìnrin rẹ̀. 2 Maria náà ni ẹni tí ó fi òróró ìkunra kun Olúwa, tí ó sì fi irun orí rẹ̀ nù ún, arákùnrin rẹ̀ ni Lasaru í ṣe, ara ẹni tí kò dá. 3 Nítorí náà, àwọn arábìnrin rẹ̀ ránṣẹ́ sí i, wí pé, “Olúwa, wò ó, ara ẹni tí ìwọ fẹ́ràn kò dá.” 4 Nígbà tí Jesu sì gbọ́, ó wí pé, “Àìsàn yìí kì í ṣe sí ikú, ṣùgbọ́n fún ògo Ọlọ́run, kí a lè yin Ọmọ Ọlọ́run lógo nípasẹ̀ rẹ̀.” 5 Jesu sì fẹ́ràn Marta, àti arábìnrin rẹ̀ àti Lasaru. 6 Nítorí náà, nígbà tí ó ti gbọ́ pé, ara rẹ̀ kò dá, ó gbé ọjọ́ méjì sí i níbìkan náà tí ó gbé wà. 7 Ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí a tún padà lọ sí Judea.” 8 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wí fún un pé, “Rabbi, ní àìpẹ́ yìí ni àwọn Júù ń wá ọ̀nà láti sọ ọ́ ní òkúta; ìwọ sì tún padà lọ síbẹ̀?” 9 Jesu dáhùn pé, “Wákàtí méjìlá kọ́ ni ó bẹ nínú ọ̀sán kan bí? Bí ẹnìkan bá rìn ní ọ̀sán, kì yóò kọsẹ̀, nítorí tí ó rí ìmọ́lẹ̀ ayé yìí. 10 Ṣùgbọ́n bí ẹnìkan bá rìn ní òru, yóò kọsẹ̀, nítorí tí kò sí ìmọ́lẹ̀ nínú rẹ̀.” 11 Nǹkan wọ̀nyí ni ó sọ, lẹ́yìn èyí nì ó sì wí fún wọn pé, “Lasaru ọ̀rẹ́ wa sùn; ṣùgbọ́n èmi ń lọ kí èmi kí ó lè jí i dìde nínú orun rẹ̀.” 12 Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olúwa, bí ó bá ṣe pé ó sùn, yóò sàn.” 13 Ṣùgbọ́n Jesu ń sọ ti ikú rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n rò pé, ó ń sọ ti orun sísùn. 14 Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn gbangba pé, “Lasaru ti kú. 15 Èmi sì yọ̀ nítorí yín, tí èmi kò sí níbẹ̀. Kí ẹ le gbàgbọ́; ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí a lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.” 16 Nítorí náà Tomasi, ẹni tí à ń pè ní Didimu, wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ẹgbẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí àwa náà lọ, kí a lè bá a kú pẹ̀lú.” 17 Nítorí náà nígbà tí Jesu dé, ó rí i pé a ti tẹ́ ẹ sínú ibojì ní ọjọ́ mẹ́rin ná, 18 ǹjẹ́ Betani súnmọ́ Jerusalẹmu tó ibùsọ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. 19 Ọ̀pọ̀ nínú àwọn Júù sì wá sọ́dọ̀ Marta àti Maria láti tù wọ́n nínú nítorí ti arákùnrin wọn. 20 Nítorí náà, nígbà tí Marta gbọ́ pé Jesu ń bọ̀ wá, ó jáde lọ pàdé rẹ̀, ṣùgbọ́n Maria jókòó nínú ilé. 21 Nígbà náà, ni Marta wí fún Jesu pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú. 22 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí náà, mo mọ̀ pé, ohunkóhun tí ìwọ bá béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run yóò fi fún ọ.” 23 Jesu wí fún un pé, “Arákùnrin rẹ yóò jíǹde.” 24 Marta wí fún un pé, “Mo mọ̀ pé yóò jíǹde ní àjíǹde ìkẹyìn.” 25 Jesu wí fún un pé, “Èmi ni àjíǹde àti ìyè, ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè. 26 Ẹnikẹ́ni tí ó ń bẹ láààyè, tí ó sì gbà mí gbọ́, kì yóò kú láéláé ìwọ gbà èyí gbọ́?” 27 Ó wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, èmi gbàgbọ́ pé, ìwọ ni Kristi náà Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí ń bọ̀ wá sí ayé.” 28 Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó lọ, ó sì pe Maria arábìnrin rẹ̀ sẹ́yìn wí pé, “Olùkọ́ dé, ó sì ń pè ọ́.” 29 Nígbà tí ó gbọ́, ó dìde lọ́gán, ó sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀. 30 Jesu kò tí ì wọ ìlú, ṣùgbọ́n ó wà ní ibi kan náà tí Marta ti pàdé rẹ̀. 31 Nígbà tí àwọn Júù tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nínú ilé, tí wọ́n ń tù ú nínú rí Maria tí ó dìde kánkán, tí ó sì jáde, wọ́n tẹ̀lé, wọ́n ṣe bí ó ń lọ sí ibojì láti sọkún níbẹ̀. 32 Nígbà tí Maria sì dé ibi tí Jesu wà, tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wí fún un pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé ìwọ ti wà níhìn-ín, arákùnrin mi kì bá kú.” 33 Nígbà tí Jesu rí i, tí ó ń sọkún, àti àwọn Júù tí ó bá a wá ń sọkún pẹ̀lú rẹ̀, ó kérora nínú ẹ̀mí, inú rẹ̀ sì bàjẹ́. 34 Ó sì wí pé, “Níbo ni ẹ̀yin gbé tẹ́ ẹ sí?”Wọ́n sì wí fún un pé, “Olúwa, wá wò ó.” 35 Jesu sọkún. 36 Nítorí náà àwọn Júù wí pé, “Sá wò ó bí ó ti fẹ́ràn rẹ̀ tó!” 37 Àwọn kan nínú wọn sì wí pé, “Ọkùnrin yìí, ẹni tí ó la ojú afọ́jú, kò lè ṣe é kí ọkùnrin yìí má kú bí?” 38 Nígbà náà ni Jesu tún kérora nínú ara rẹ̀, ó wá sí ibojì, ó sì jẹ́ ihò, a sì gbé òkúta lé ẹnu rẹ̀. 39 Jesu wí pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò!”Marta, arábìnrin ẹni tí ó kú náà wí fún un pé, “Olúwa, ó ti ń rùn nísinsin yìí, nítorí pé ó di ọjọ́ kẹrin tí ó tí kú.” 40 Jesu wí fún un pé, “Èmi kò ti wí fún ọ pé, bí ìwọ bá gbàgbọ́, ìwọ yóò rí ògo Ọlọ́run?” 41 Nígbà náà ni wọ́n gbé òkúta náà kúrò (níbi tí a tẹ́ ẹ sí). Jesu sì gbé ojú rẹ̀ sókè, ó sì wí pé, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí tí ìwọ gbọ́ tèmi. 42 Èmi sì ti mọ̀ pé, ìwọ a máa gbọ́ ti èmi nígbà gbogbo, ṣùgbọ́n nítorí ìjọ ènìyàn tí ó dúró yìí ni mo ṣe wí i, kí wọn ba à lè gbàgbọ́ pé ìwọ ni ó rán mi.” 43 Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó kígbe lóhùn rara pé, “Lasaru, jáde wá.” 44 Ẹni tí ó kú náà sì jáde wá, tí a fi aṣọ òkú dì tọwọ́ tẹsẹ̀ a sì fi gèlè dì í lójú.Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ!” 45 Nítorí náà ni ọ̀pọ̀ àwọn Júù tí ó wá sọ́dọ̀ Maria, tí wọ́n rí ohun tí Jesu ṣe, ṣe gbà á gbọ́. 46 Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn nínú wọn tọ àwọn Farisi lọ, wọ́n sì sọ fún wọn ohun tí Jesu ṣe. 47 Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi pe ìgbìmọ̀ jọ.Wọ́n sì wí pé, “Kín ni yóò jẹ àṣeyọrí wa? Nítorí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì. 48 Bí àwa bá fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀, gbogbo ènìyàn ni yóò gbà á gbọ́, àwọn ará Romu yóò sì wá gba ilẹ̀ àti orílẹ̀-èdè wa pẹ̀lú.” 49 Ṣùgbọ́n Kaiafa, ọ̀kan nínú wọn, ẹni tí í ṣe olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohunkóhun rárá! 50 Bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì ronú pé, ó ṣàǹfààní fún wa, kí ènìyàn kan kú fún àwọn ènìyàn kí gbogbo orílẹ̀-èdè má ba à ṣègbé.” 51 Kì í ṣe fún ara rẹ̀ ni ó sọ èyí ṣùgbọ́n bí ó ti jẹ́ olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó sọtẹ́lẹ̀ pé, Jesu yóò kú fún orílẹ̀-èdè náà, 52 kì sì í ṣe kìkì fún orílẹ̀-èdè náà nìkan, ṣùgbọ́n fún àwọn ọmọ Ọlọ́run tí ó fọ́nká kiri, kí ó le kó wọn papọ̀, kí ó sì sọ wọ́n di ọ̀kan. 53 Nítorí náà, láti ọjọ́ náà lọ ni wọ́n ti jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á. 54 Nítorí náà Jesu kò rìn ní gbangba láàrín àwọn Júù mọ́; ṣùgbọ́n ó ti ibẹ̀ lọ sí ìgbèríko kan tí ó súnmọ́ aginjù, sí ìlú ńlá kan tí a ń pè ní Efraimu, níbẹ̀ ni ó sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. 55 Àjọ ìrékọjá àwọn Júù sì súnmọ́ etílé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti ìgbèríko sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu ṣáájú ìrékọjá, láti ya ara wọn sí mímọ́. 56 Nígbà náà ni wọ́n ń wá Jesu, wọ́n sì ń bá ara wọn sọ̀, bí wọ́n ti dúró ní tẹmpili, wí pé, “Kín ni ẹyin ti rò ó sí pé kì yóò wá sí àjọ?” 57 Ǹjẹ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi ti pàṣẹ pé bí ẹnìkan bá mọ ibi tí ó gbé wà, kí ó fi í hàn, kí wọn ba à lè mú un.

In Other Versions

John 11 in the ANGEFD

John 11 in the ANTPNG2D

John 11 in the AS21

John 11 in the BAGH

John 11 in the BBPNG

John 11 in the BBT1E

John 11 in the BDS

John 11 in the BEV

John 11 in the BHAD

John 11 in the BIB

John 11 in the BLPT

John 11 in the BNT

John 11 in the BNTABOOT

John 11 in the BNTLV

John 11 in the BOATCB

John 11 in the BOATCB2

John 11 in the BOBCV

John 11 in the BOCNT

John 11 in the BOECS

John 11 in the BOGWICC

John 11 in the BOHCB

John 11 in the BOHCV

John 11 in the BOHLNT

John 11 in the BOHNTLTAL

John 11 in the BOICB

John 11 in the BOILNTAP

John 11 in the BOITCV

John 11 in the BOKCV

John 11 in the BOKCV2

John 11 in the BOKHWOG

John 11 in the BOKSSV

John 11 in the BOLCB

John 11 in the BOLCB2

John 11 in the BOMCV

John 11 in the BONAV

John 11 in the BONCB

John 11 in the BONLT

John 11 in the BONUT2

John 11 in the BOPLNT

John 11 in the BOSCB

John 11 in the BOSNC

John 11 in the BOTLNT

John 11 in the BOVCB

John 11 in the BPBB

John 11 in the BPH

John 11 in the BSB

John 11 in the CCB

John 11 in the CUV

John 11 in the CUVS

John 11 in the DBT

John 11 in the DGDNT

John 11 in the DHNT

John 11 in the DNT

John 11 in the ELBE

John 11 in the EMTV

John 11 in the ESV

John 11 in the FBV

John 11 in the FEB

John 11 in the GGMNT

John 11 in the GNT

John 11 in the HARY

John 11 in the HNT

John 11 in the IRVA

John 11 in the IRVB

John 11 in the IRVG

John 11 in the IRVH

John 11 in the IRVK

John 11 in the IRVM

John 11 in the IRVM2

John 11 in the IRVO

John 11 in the IRVP

John 11 in the IRVT

John 11 in the IRVT2

John 11 in the IRVU

John 11 in the ISVN

John 11 in the JSNT

John 11 in the KAPI

John 11 in the KBT1ETNIK

John 11 in the KBV

John 11 in the KJV

John 11 in the KNFD

John 11 in the LBA

John 11 in the LBLA

John 11 in the LNT

John 11 in the LSV

John 11 in the MAAL

John 11 in the MBV

John 11 in the MBV2

John 11 in the MHNT

John 11 in the MKNFD

John 11 in the MNG

John 11 in the MNT

John 11 in the MNT2

John 11 in the MRS1T

John 11 in the NAA

John 11 in the NASB

John 11 in the NBLA

John 11 in the NBS

John 11 in the NBVTP

John 11 in the NET2

John 11 in the NIV11

John 11 in the NNT

John 11 in the NNT2

John 11 in the NNT3

John 11 in the PDDPT

John 11 in the PFNT

John 11 in the RMNT

John 11 in the SBIAS

John 11 in the SBIBS

John 11 in the SBIBS2

John 11 in the SBICS

John 11 in the SBIDS

John 11 in the SBIGS

John 11 in the SBIHS

John 11 in the SBIIS

John 11 in the SBIIS2

John 11 in the SBIIS3

John 11 in the SBIKS

John 11 in the SBIKS2

John 11 in the SBIMS

John 11 in the SBIOS

John 11 in the SBIPS

John 11 in the SBISS

John 11 in the SBITS

John 11 in the SBITS2

John 11 in the SBITS3

John 11 in the SBITS4

John 11 in the SBIUS

John 11 in the SBIVS

John 11 in the SBT

John 11 in the SBT1E

John 11 in the SCHL

John 11 in the SNT

John 11 in the SUSU

John 11 in the SUSU2

John 11 in the SYNO

John 11 in the TBIAOTANT

John 11 in the TBT1E

John 11 in the TBT1E2

John 11 in the TFTIP

John 11 in the TFTU

John 11 in the TGNTATF3T

John 11 in the THAI

John 11 in the TNFD

John 11 in the TNT

John 11 in the TNTIK

John 11 in the TNTIL

John 11 in the TNTIN

John 11 in the TNTIP

John 11 in the TNTIZ

John 11 in the TOMA

John 11 in the TTENT

John 11 in the UBG

John 11 in the UGV

John 11 in the UGV2

John 11 in the UGV3

John 11 in the VBL

John 11 in the VDCC

John 11 in the YALU

John 11 in the YAPE

John 11 in the YBVTP

John 11 in the ZBP