Lamentations 4 (BOYCB)
1 Báwo ni wúrà ṣe sọ ògo dídán rẹ̀ nù,wúrà dídára di àìdán!Òkúta ibi mímọ́ wá túkásí oríta gbogbo òpópó. 2 Báwo ni àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Sioni tí ó ṣe iyebíye,tí wọ́n fi wúrà dídára ṣewá dàbí ìkòkò amọ̀ lásániṣẹ́ ọwọ́ amọ̀kòkò! 3 Àwọn ajáko pèsè ọmú wọnfún ìtọ́jú àwọn ọmọ wọn,ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi wá láì lọ́kànbí ògòǹgò ní aginjù. 4 Nítorí òǹgbẹ, ahọ́n àwọn ọmọ ọwọ́lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu wọn;àwọn ọmọdé bẹ̀bẹ̀ fún oúnjẹ,ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó fi fún wọn. 5 Àwọn tí ó ń jẹ ohun dáradáradi òtòṣì ní òpópó.Àwọn tí a fi aṣọ dáradára wọ̀ni wọ́n sùn ní orí òkìtì eérú. 6 Ìjìyà àwọn ènìyàn mitóbi ju ti Sodomu lọ,tí a sí ní ipò ní òjijìláìsí ọwọ́ láti ràn án lọ́wọ́. 7 Ọmọ ọba ọkùnrin wọn mọ́ ju òjò-dídì,wọ́n sì funfun ju wàrà lọwọ́n ni ìtọ́jú bí iyùn pupa,ìrísí wọn dàbí safire. 8 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n dúdú ju èédú;wọn kò sì dá wọn mọ̀ ní òpópó.Ara wọn hun mọ́ egungun;ó sì gbẹ bí igi gbígbẹ. 9 Àwọn tí ó kù nípasẹ̀ idà sànju àwọn tí ìyàn pa;tí ó wọ àkísà ebi, tí ó ń ṣòfòfún àìní oúnjẹ láti inú pápá. 10 Pẹ̀lú ọwọ́ àwọn obìnrin aláàánúni wọ́n ṣe ọmọ wọn jẹtí ó di oúnjẹ fún wọnnígbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run. 11 OLÚWA ti fi ihò kíkún fún ìbínú rẹ̀;ó sì tú ìbínú gbígbóná rẹ̀ jáde.Ó da iná ní Sionití ó jó ìpìlẹ̀ rẹ̀ run. 12 Àwọn ọba ayé kò gbàgbọ́,tàbí àwọn ènìyàn ayé,wí pé àwọn ọ̀tá àti aninilára le wọodi ìlú Jerusalẹmu. 13 Èyí ṣẹlẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wòlíìàti àìṣedéédéé àwọn olórí àlùfáà,tí ó ta ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodosílẹ̀ láàrín rẹ̀. 14 Nísinsin yìí wọ́n ń rìn kiri ní òpópóbí ọkùnrin tí ó fọ́jú.Ẹ̀jẹ̀ ara wọn sọ wọ́n di àbàwọ́ntí kò sẹ́ni tó láyà láti fọwọ́ kan aṣọ wọn. 15 “Lọ kúrò! Ẹ̀yin di aláìmọ́!” ni àwọn ènìyàn ń kígbe sí wọn.“Ẹ lọ! Ẹ lọ! Ẹ má ṣe fọwọ́ kàn wá!”Àwọn ènìyàn láàrín orílẹ̀-èdè wí pé,“Wọn kì yóò tẹ̀dó síbí mọ́.” 16 OLÚWA ti tú wọn ká fúnra rẹ̀;kò sí bojútó wọn mọ́.Kò sí ọ̀wọ̀ fún olórí àlùfáà mọ́,àti àánú fún àwọn àgbàgbà. 17 Síwájú sí i, ojú wa kùnàfún wíwo ìrànlọ́wọ́ asán;láti orí ìṣọ́ wa ni à ń wòfún orílẹ̀-èdè tí kò le gbà wá là. 18 Wọ́n ń ṣọ́ wa kiri,àwa kò sì le rìn ní òpópó wa mọ́.Òpin wa ti súnmọ́, ọjọ́ wa sì níyenítorí òpin wa ti dé. 19 Àwọn tí ń lé wa yáraju idì ojú ọ̀run lọ;wọ́n lé wa ní gbogbo orí òkèwọ́n sì gẹ̀gùn dè wá ní aginjù. 20 Ẹni àmì òróró OLÚWA, èémí ìyè wa,ni wọ́n fi tàkúté wọn mú.Àwa rò pé lábẹ́ òjìji rẹ̀ni àwa yóò máa gbé láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo. 21 Ẹ yọ̀ kí inú yín sì dùn, ẹ̀yin ọmọbìnrin Edomu,ẹ̀yin tó ń gbé ní ilẹ̀ Usi.Ṣùgbọ́n, a ó gbé ago náà kọjá sọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú;ìwọ yóò yó bí ọ̀mùtí, ìwọ yóò sì rìn ní ìhòhò. 22 Ìwọ ọmọbìnrin Sioni, ìjìyà rẹ yóò dópin;kò ní mú ìgbèkùn rẹ pẹ́ mọ́.Ṣùgbọ́n, ìwọ ọmọbìnrin Edomu, yóò jẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ní yàyóò sì fi àìṣedéédéé rẹ hàn kedere.
In Other Versions
Lamentations 4 in the ANGEFD
Lamentations 4 in the ANTPNG2D
Lamentations 4 in the AS21
Lamentations 4 in the BAGH
Lamentations 4 in the BBPNG
Lamentations 4 in the BBT1E
Lamentations 4 in the BDS
Lamentations 4 in the BEV
Lamentations 4 in the BHAD
Lamentations 4 in the BIB
Lamentations 4 in the BLPT
Lamentations 4 in the BNT
Lamentations 4 in the BNTABOOT
Lamentations 4 in the BNTLV
Lamentations 4 in the BOATCB
Lamentations 4 in the BOATCB2
Lamentations 4 in the BOBCV
Lamentations 4 in the BOCNT
Lamentations 4 in the BOECS
Lamentations 4 in the BOGWICC
Lamentations 4 in the BOHCB
Lamentations 4 in the BOHCV
Lamentations 4 in the BOHLNT
Lamentations 4 in the BOHNTLTAL
Lamentations 4 in the BOICB
Lamentations 4 in the BOILNTAP
Lamentations 4 in the BOITCV
Lamentations 4 in the BOKCV
Lamentations 4 in the BOKCV2
Lamentations 4 in the BOKHWOG
Lamentations 4 in the BOKSSV
Lamentations 4 in the BOLCB
Lamentations 4 in the BOLCB2
Lamentations 4 in the BOMCV
Lamentations 4 in the BONAV
Lamentations 4 in the BONCB
Lamentations 4 in the BONLT
Lamentations 4 in the BONUT2
Lamentations 4 in the BOPLNT
Lamentations 4 in the BOSCB
Lamentations 4 in the BOSNC
Lamentations 4 in the BOTLNT
Lamentations 4 in the BOVCB
Lamentations 4 in the BPBB
Lamentations 4 in the BPH
Lamentations 4 in the BSB
Lamentations 4 in the CCB
Lamentations 4 in the CUV
Lamentations 4 in the CUVS
Lamentations 4 in the DBT
Lamentations 4 in the DGDNT
Lamentations 4 in the DHNT
Lamentations 4 in the DNT
Lamentations 4 in the ELBE
Lamentations 4 in the EMTV
Lamentations 4 in the ESV
Lamentations 4 in the FBV
Lamentations 4 in the FEB
Lamentations 4 in the GGMNT
Lamentations 4 in the GNT
Lamentations 4 in the HARY
Lamentations 4 in the HNT
Lamentations 4 in the IRVA
Lamentations 4 in the IRVB
Lamentations 4 in the IRVG
Lamentations 4 in the IRVH
Lamentations 4 in the IRVK
Lamentations 4 in the IRVM
Lamentations 4 in the IRVM2
Lamentations 4 in the IRVO
Lamentations 4 in the IRVP
Lamentations 4 in the IRVT
Lamentations 4 in the IRVT2
Lamentations 4 in the IRVU
Lamentations 4 in the ISVN
Lamentations 4 in the JSNT
Lamentations 4 in the KAPI
Lamentations 4 in the KBT1ETNIK
Lamentations 4 in the KBV
Lamentations 4 in the KJV
Lamentations 4 in the KNFD
Lamentations 4 in the LBA
Lamentations 4 in the LBLA
Lamentations 4 in the LNT
Lamentations 4 in the LSV
Lamentations 4 in the MAAL
Lamentations 4 in the MBV
Lamentations 4 in the MBV2
Lamentations 4 in the MHNT
Lamentations 4 in the MKNFD
Lamentations 4 in the MNG
Lamentations 4 in the MNT
Lamentations 4 in the MNT2
Lamentations 4 in the MRS1T
Lamentations 4 in the NAA
Lamentations 4 in the NASB
Lamentations 4 in the NBLA
Lamentations 4 in the NBS
Lamentations 4 in the NBVTP
Lamentations 4 in the NET2
Lamentations 4 in the NIV11
Lamentations 4 in the NNT
Lamentations 4 in the NNT2
Lamentations 4 in the NNT3
Lamentations 4 in the PDDPT
Lamentations 4 in the PFNT
Lamentations 4 in the RMNT
Lamentations 4 in the SBIAS
Lamentations 4 in the SBIBS
Lamentations 4 in the SBIBS2
Lamentations 4 in the SBICS
Lamentations 4 in the SBIDS
Lamentations 4 in the SBIGS
Lamentations 4 in the SBIHS
Lamentations 4 in the SBIIS
Lamentations 4 in the SBIIS2
Lamentations 4 in the SBIIS3
Lamentations 4 in the SBIKS
Lamentations 4 in the SBIKS2
Lamentations 4 in the SBIMS
Lamentations 4 in the SBIOS
Lamentations 4 in the SBIPS
Lamentations 4 in the SBISS
Lamentations 4 in the SBITS
Lamentations 4 in the SBITS2
Lamentations 4 in the SBITS3
Lamentations 4 in the SBITS4
Lamentations 4 in the SBIUS
Lamentations 4 in the SBIVS
Lamentations 4 in the SBT
Lamentations 4 in the SBT1E
Lamentations 4 in the SCHL
Lamentations 4 in the SNT
Lamentations 4 in the SUSU
Lamentations 4 in the SUSU2
Lamentations 4 in the SYNO
Lamentations 4 in the TBIAOTANT
Lamentations 4 in the TBT1E
Lamentations 4 in the TBT1E2
Lamentations 4 in the TFTIP
Lamentations 4 in the TFTU
Lamentations 4 in the TGNTATF3T
Lamentations 4 in the THAI
Lamentations 4 in the TNFD
Lamentations 4 in the TNT
Lamentations 4 in the TNTIK
Lamentations 4 in the TNTIL
Lamentations 4 in the TNTIN
Lamentations 4 in the TNTIP
Lamentations 4 in the TNTIZ
Lamentations 4 in the TOMA
Lamentations 4 in the TTENT
Lamentations 4 in the UBG
Lamentations 4 in the UGV
Lamentations 4 in the UGV2
Lamentations 4 in the UGV3
Lamentations 4 in the VBL
Lamentations 4 in the VDCC
Lamentations 4 in the YALU
Lamentations 4 in the YAPE
Lamentations 4 in the YBVTP
Lamentations 4 in the ZBP