Psalms 37 (BOYCB)

undefined Ti Dafidi. 1 Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú,kí ìwọ má sì ṣe ṣe ìlara nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀; 2 nítorí pé wọn yóò gbẹ bí i koríko,wọn yóò sì rẹ̀ dànù bí ewéko tútù. 3 Gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA, kí o sì máa ṣe rere;torí pé ìwọ yóò gbé ilẹ̀ náà, kí o sì gbádùn ààbò rẹ̀. 4 Ṣe inú dídùn sí OLÚWA;òun yóò sì fún ọ ní ìfẹ́ inú rẹ̀. 5 Fi ọ̀nà rẹ lé OLÚWA lọ́wọ́;gbẹ́kẹ̀lé pẹ̀lú, òun yóò sì ṣe é. 6 Yóò sì mú kí òdodo rẹ̀ jáde bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,àti ìdájọ́ rẹ̀ bí ọ̀sán gangan. 7 Ìwọ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLÚWA,kí o sì fi sùúrù dúró dè é;má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọn tí ń rí rere ní ọ̀nà wọn,nítorí ọkùnrin náà ti mú èrò búburú ṣẹ. 8 Fàsẹ́yìn nínú inúbíbí, kí o sì kọ ìkáàánú sílẹ̀,má ṣe ṣe ìkanra, kí ó má ba à ṣé búburú pẹ̀lú. 9 Nítorí tí á ó gé àwọn olùṣe búburú kúrò,ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá dúró de OLÚWA àwọn ni yóò jogún ilẹ̀ náà. 10 Síbẹ̀ nígbà díẹ̀ sí i, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí mọ̀;nítòótọ́ ìwọ yóò fi ara balẹ̀ wo ipò rẹ̀, wọn kì yóò sí níbẹ̀. 11 Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ilẹ̀ náà,wọn yóò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà. 12 Ènìyàn búburú di rìkíṣí sí olóòtítọ́,wọ́n sì pa eyín wọn keke sí wọn; 13 ṣùgbọ́n Olúwa rẹ́rìn-ín sí àwọn ènìyàn búburú,nítorí tí ó rí wí pé ọjọ́ wọn ń bọ̀. 14 Ènìyàn búburú fa idà yọ,wọ́n sì tẹ àwọn ọrun wọn,láti sọ tálákà àti aláìní kalẹ̀,láti pa àwọn tí ó dúró ṣinṣin. 15 Idà wọn yóò wọ àyà wọn lọ,àti wí pé ọrun wọn yóò sì ṣẹ́. 16 Ohun díẹ̀ tí olódodo ní,sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ènìyàn búburú; 17 nítorí pé a óò ṣẹ́ ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú,ṣùgbọ́n OLÚWA gbé olódodo sókè. 18 OLÚWA mọ àwọn ọjọ́ àwọn tó dúró ṣinṣin,àti wí pé ilẹ̀ ìní wọn yóò wà títí ayérayé. 19 Ojú kì yóò tì wọ́n ní àkókò ibi,àti ní ọjọ́ ìyàn, a ó tẹ́ wọn lọ́rùn. 20 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú yóò ṣègbé.Àwọn ọ̀tá OLÚWA yóò dàbí ẹwà oko tútù;wọn fò lọ; bi èéfín ni wọn yóò fò lọ kúrò. 21 Àwọn ènìyàn búburú yá, wọn kò sì san án padà,ṣùgbọ́n àwọn olódodo a máa ṣàánú, a sì máa fi fún ni; 22 nítorí àwọn tí OLÚWA bá bùkún ni yóò jogún ilẹ̀ náà,àwọn tí ó fi bú ni a ó gé kúrò. 23 Ìlànà ìgbésẹ̀ ènìyàn rere wá láti ọ̀dọ̀ OLÚWA wá,o sì ṣe inú dídùn sí ọ̀nà rẹ̀; 24 bí ó tilẹ̀ ṣubú a kì yóò ta á nù pátápátá,nítorí tí OLÚWA di ọwọ́ rẹ̀ mú. 25 Èmi ti wà ni èwe, báyìí èmi sì dàgbà;síbẹ̀ èmi kò ì tí ì ri kí a kọ olódodo sílẹ̀,tàbí kí irú-ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe oúnjẹ. 26 Aláàánú ni òun nígbà gbogbo a máa yá ni;a sì máa bùsi i fún ni. 27 Lọ kúrò nínú ibi, kí o sì máa ṣe rere;nígbà náà ni ìwọ yóò gbé ní ilẹ̀ náà títí láéláé. 28 Nítorí pé OLÚWA fẹ́ràn ìdájọ́ òtítọ́,kò sì kọ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀. Àwọn olódodo ni a ó pamọ́ títí ayérayé,ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ènìyàn búburú ni a ó ké kúrò. 29 Olódodo ni yóò jogún ilẹ̀ náà,yóò sì máa gbé ibẹ̀ títí ayérayé. 30 Ẹnu olódodo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,ahọ́n rẹ̀ a sì máa sọ̀rọ̀ ìdájọ́. 31 Òfin Ọlọ́run rẹ̀ ń bẹ ní àyà wọn;àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ kì yóò yẹ̀. 32 Ènìyàn búburú ń ṣọ́ olódodo,Ó sì ń wá ọ̀nà láti pa á. 33 OLÚWA kì yóò fi lé e lọ́wọ́ kì yóò sì dá a lẹ́bi,nígbà tí a bá ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀. 34 Dúró de OLÚWA,kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́.Yóò sì gbé ọ lékè láti jogún ilẹ̀ náà;nígbà tí a bá gé àwọn ènìyàn búburú kúrò ìwọ yóò ri. 35 Èmi ti rí ènìyàn búburú tí ń hu ìwà ìkà,ó sì fi ara rẹ̀ gbilẹ̀ bí igi tútù ńlá, 36 ṣùgbọ́n ní ìṣẹ́jú kan sí i ó kọjá lọ, sì kíyèsi, kò sì sí mọ́;bi ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé mo wá a kiri, ṣùgbọ́n a kò le è ri. 37 Máa kíyèsi ẹni pípé, kí o sì wo ẹni tó dúró ṣinṣin;nítorí àlàáfíà ni òpin ọkùnrin náà. 38 Ṣùgbọ́n àwọn olùrékọjá ni a ó parun papọ̀;ìran àwọn ènìyàn búburú ni a ó gé kúrò. 39 Ìgbàlà àwọn onídùúró ṣinṣin wá láti ọ̀dọ̀ OLÚWA;òun ni ààbò wọn ní ìgbà ìpọ́njú 40 OLÚWA yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ yóò sì gbà wọ́n;yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ènìyàn búburú, yóò sì gbà wọ́n là,nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.

In Other Versions

Psalms 37 in the ANGEFD

Psalms 37 in the ANTPNG2D

Psalms 37 in the AS21

Psalms 37 in the BAGH

Psalms 37 in the BBPNG

Psalms 37 in the BBT1E

Psalms 37 in the BDS

Psalms 37 in the BEV

Psalms 37 in the BHAD

Psalms 37 in the BIB

Psalms 37 in the BLPT

Psalms 37 in the BNT

Psalms 37 in the BNTABOOT

Psalms 37 in the BNTLV

Psalms 37 in the BOATCB

Psalms 37 in the BOATCB2

Psalms 37 in the BOBCV

Psalms 37 in the BOCNT

Psalms 37 in the BOECS

Psalms 37 in the BOGWICC

Psalms 37 in the BOHCB

Psalms 37 in the BOHCV

Psalms 37 in the BOHLNT

Psalms 37 in the BOHNTLTAL

Psalms 37 in the BOICB

Psalms 37 in the BOILNTAP

Psalms 37 in the BOITCV

Psalms 37 in the BOKCV

Psalms 37 in the BOKCV2

Psalms 37 in the BOKHWOG

Psalms 37 in the BOKSSV

Psalms 37 in the BOLCB

Psalms 37 in the BOLCB2

Psalms 37 in the BOMCV

Psalms 37 in the BONAV

Psalms 37 in the BONCB

Psalms 37 in the BONLT

Psalms 37 in the BONUT2

Psalms 37 in the BOPLNT

Psalms 37 in the BOSCB

Psalms 37 in the BOSNC

Psalms 37 in the BOTLNT

Psalms 37 in the BOVCB

Psalms 37 in the BPBB

Psalms 37 in the BPH

Psalms 37 in the BSB

Psalms 37 in the CCB

Psalms 37 in the CUV

Psalms 37 in the CUVS

Psalms 37 in the DBT

Psalms 37 in the DGDNT

Psalms 37 in the DHNT

Psalms 37 in the DNT

Psalms 37 in the ELBE

Psalms 37 in the EMTV

Psalms 37 in the ESV

Psalms 37 in the FBV

Psalms 37 in the FEB

Psalms 37 in the GGMNT

Psalms 37 in the GNT

Psalms 37 in the HARY

Psalms 37 in the HNT

Psalms 37 in the IRVA

Psalms 37 in the IRVB

Psalms 37 in the IRVG

Psalms 37 in the IRVH

Psalms 37 in the IRVK

Psalms 37 in the IRVM

Psalms 37 in the IRVM2

Psalms 37 in the IRVO

Psalms 37 in the IRVP

Psalms 37 in the IRVT

Psalms 37 in the IRVT2

Psalms 37 in the IRVU

Psalms 37 in the ISVN

Psalms 37 in the JSNT

Psalms 37 in the KAPI

Psalms 37 in the KBT1ETNIK

Psalms 37 in the KBV

Psalms 37 in the KJV

Psalms 37 in the KNFD

Psalms 37 in the LBA

Psalms 37 in the LBLA

Psalms 37 in the LNT

Psalms 37 in the LSV

Psalms 37 in the MAAL

Psalms 37 in the MBV

Psalms 37 in the MBV2

Psalms 37 in the MHNT

Psalms 37 in the MKNFD

Psalms 37 in the MNG

Psalms 37 in the MNT

Psalms 37 in the MNT2

Psalms 37 in the MRS1T

Psalms 37 in the NAA

Psalms 37 in the NASB

Psalms 37 in the NBLA

Psalms 37 in the NBS

Psalms 37 in the NBVTP

Psalms 37 in the NET2

Psalms 37 in the NIV11

Psalms 37 in the NNT

Psalms 37 in the NNT2

Psalms 37 in the NNT3

Psalms 37 in the PDDPT

Psalms 37 in the PFNT

Psalms 37 in the RMNT

Psalms 37 in the SBIAS

Psalms 37 in the SBIBS

Psalms 37 in the SBIBS2

Psalms 37 in the SBICS

Psalms 37 in the SBIDS

Psalms 37 in the SBIGS

Psalms 37 in the SBIHS

Psalms 37 in the SBIIS

Psalms 37 in the SBIIS2

Psalms 37 in the SBIIS3

Psalms 37 in the SBIKS

Psalms 37 in the SBIKS2

Psalms 37 in the SBIMS

Psalms 37 in the SBIOS

Psalms 37 in the SBIPS

Psalms 37 in the SBISS

Psalms 37 in the SBITS

Psalms 37 in the SBITS2

Psalms 37 in the SBITS3

Psalms 37 in the SBITS4

Psalms 37 in the SBIUS

Psalms 37 in the SBIVS

Psalms 37 in the SBT

Psalms 37 in the SBT1E

Psalms 37 in the SCHL

Psalms 37 in the SNT

Psalms 37 in the SUSU

Psalms 37 in the SUSU2

Psalms 37 in the SYNO

Psalms 37 in the TBIAOTANT

Psalms 37 in the TBT1E

Psalms 37 in the TBT1E2

Psalms 37 in the TFTIP

Psalms 37 in the TFTU

Psalms 37 in the TGNTATF3T

Psalms 37 in the THAI

Psalms 37 in the TNFD

Psalms 37 in the TNT

Psalms 37 in the TNTIK

Psalms 37 in the TNTIL

Psalms 37 in the TNTIN

Psalms 37 in the TNTIP

Psalms 37 in the TNTIZ

Psalms 37 in the TOMA

Psalms 37 in the TTENT

Psalms 37 in the UBG

Psalms 37 in the UGV

Psalms 37 in the UGV2

Psalms 37 in the UGV3

Psalms 37 in the VBL

Psalms 37 in the VDCC

Psalms 37 in the YALU

Psalms 37 in the YAPE

Psalms 37 in the YBVTP

Psalms 37 in the ZBP