Romans 7 (BOYCB)

1 Ẹ̀yin kò ha mọ̀, ara: nítorí èmí bá àwọn tí ó mọ òfin sọ̀rọ̀ pé, òfin ní ipá lórí ènìyàn níwọ̀n ìgbà tí ó bá wà láààyè nìkan? 2 Fún àpẹẹrẹ, nípa òfin ní a de obìnrin mọ́ ọkọ rẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ náà wà láààyè, ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá kú, a tú u sílẹ̀ kúrò nínú òfin ìgbéyàwó náà. 3 Nígbà náà, bí ó bá fẹ́ ọkùnrin mìíràn nígbà tí ọkọ rẹ̀ wà láààyè, panṣágà ní a ó pè é. Ṣùgbọ́n bí ọkọ rẹ̀ bá kú, ó bọ́ lọ́wọ́ òfin náà, kí yóò sì jẹ́ panṣágà bí ó bá ní ọkọ mìíràn. 4 Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin ará mi, ẹ̀yin pẹ̀lú ti di òkú sí òfin nípa ara Kristi, kí ẹ̀yin kí ó lè ní ẹlòmíràn, àní ẹni náà tí a jí dìde kúrò nínú òkú, kí àwa kí ó lè so èso fún Ọlọ́run. 5 Nítorí ìgbà tí a wa nípa ti ara, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ nípa ti òfin, ma ń ṣiṣẹ́ nínú wa, tí a sì ń so èso tí ó yẹ fún ikú. 6 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa kíkú ohun tó so wá pọ̀ tẹ́lẹ̀ rí, a ti tú wa sílẹ̀ kúrò nínú òfin, kí a lè sin ín ní ìlànà tuntun ti Ẹ̀mí, kì í ṣe ní ìlànà àtijọ́ tí ìwé òfin gùnlé. 7 Ǹjẹ́ àwa o ha ti wí, nígbà náà? Òfin ha ń ṣe ẹ̀ṣẹ̀ bí? Kí a má rí i! Ṣùgbọ́n èmi kì bá tí mọ ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́, bí kò ṣe nípa òfin. Èmi kì bá tí mọ ojúkòkòrò, bí kò ṣe bí òfin ti wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò.” 8 Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ sì ti ipa òfin rí ààyè ṣiṣẹ́ onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ nínú mi. Nítorí láìsí òfin, ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ikú. 9 Èmi sì ti wà láààyè láìsí òfin nígbà kan rí; ṣùgbọ́n nígbà tí òfin dé, ẹ̀ṣẹ̀ sọjí èmi sì kú. 10 Mo ṣàkíyèsí pé òfin tí ó yẹ kí ó mú ìyè wá ni ó padà mú ikú wá. 11 Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ti ipa òfin rí ààyè láti tàn mí jẹ, ó sì ti ipa òfin ṣe ikú pa mi. 12 Bẹ́ẹ̀ ni mímọ́ ni òfin, mímọ́ sì ni àṣẹ, àti òdodo, àti dídára. 13 Ǹjẹ́ ohun tí ó dára ha di ikú fún mi bí? Kí a má rí i! Ṣùgbọ́n kí ẹ̀ṣẹ̀, kí ó lè farahàn bí ẹ̀ṣẹ̀, ó ń ti ipa ohun tí ó dára ṣiṣẹ́ ikú nínú mi, kí ẹ̀ṣẹ̀ lè ti ipa òfin di búburú rékọjá. 14 Nítorí àwa mọ̀ pé ohun ẹ̀mí ni òfin, ṣùgbọ́n ẹni ti ara ni èmi, tí a ti tà sábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. 15 Èmi pàápàá, kò mọ̀ ohun tí èmi ń ṣe. Nítorí pé, ohun tí mo fẹ́ ṣe gan an n kò ṣe é, ṣùgbọ́n ohun tí mo kórìíra ni mo ń ṣe. 16 Ṣùgbọ́n bí mo bá ṣe ohun tí èmi kò fẹ́, mo gbà pé òfin dára. 17 Ṣùgbọ́n bí ọ̀rọ̀ ṣe rí yìí kì í ṣe èmi ni ó ṣe é bí kò ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi. 18 Èmi mọ̀ dájú pé kò sí ohun tí ó dára kan tí ń gbé inú mi, àní, nínú ara ẹ̀ṣẹ̀ mi. Èmi fẹ́ ṣe èyí tí ó dára, ṣùgbọ́n kò sé é ṣe. 19 Nítorí ohun tí èmi ṣe kì í ṣe ohun rere tí èmi fẹ́ láti ṣe; rárá, ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò fẹ́, èyí nì ni èmi ń ṣe. 20 Nísinsin yìí, bí mo bá ń ṣe nǹkan tí n kò fẹ́ láti ṣe, kì í ṣe èmí fúnra mi ni ó ṣe é, bí kò ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ nínú ni ó ṣe é. 21 Nítorí náà, èmi kíyèsi pé òfin ní ń ṣiṣẹ́ nínú mi, nígbà tí èmi bá fẹ́ ṣe rere, búburú wà níbẹ̀ pẹ̀lú mi. 22 Nínú ìjìnlẹ̀ ọkàn mi mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run; 23 mo rí òfin mìíràn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yà ara mi, èyí tí ń gbógun ti òfin tó tinú ọkàn mi wá, èyí tí ó sọ mi di ẹrú òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yà ara mi. 24 Èmi ẹni òsì! Ta ni yóò ha gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ara kíkú yìí? 25 Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa!Ǹjẹ́ nítorí náà, èmi fúnra mi jẹ́ ẹrú sí òfin Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nínú ara ẹ̀ṣẹ̀ mo jẹ́ ẹrú fún òfin ẹ̀ṣẹ̀.

In Other Versions

Romans 7 in the ANGEFD

Romans 7 in the ANTPNG2D

Romans 7 in the AS21

Romans 7 in the BAGH

Romans 7 in the BBPNG

Romans 7 in the BBT1E

Romans 7 in the BDS

Romans 7 in the BEV

Romans 7 in the BHAD

Romans 7 in the BIB

Romans 7 in the BLPT

Romans 7 in the BNT

Romans 7 in the BNTABOOT

Romans 7 in the BNTLV

Romans 7 in the BOATCB

Romans 7 in the BOATCB2

Romans 7 in the BOBCV

Romans 7 in the BOCNT

Romans 7 in the BOECS

Romans 7 in the BOGWICC

Romans 7 in the BOHCB

Romans 7 in the BOHCV

Romans 7 in the BOHLNT

Romans 7 in the BOHNTLTAL

Romans 7 in the BOICB

Romans 7 in the BOILNTAP

Romans 7 in the BOITCV

Romans 7 in the BOKCV

Romans 7 in the BOKCV2

Romans 7 in the BOKHWOG

Romans 7 in the BOKSSV

Romans 7 in the BOLCB

Romans 7 in the BOLCB2

Romans 7 in the BOMCV

Romans 7 in the BONAV

Romans 7 in the BONCB

Romans 7 in the BONLT

Romans 7 in the BONUT2

Romans 7 in the BOPLNT

Romans 7 in the BOSCB

Romans 7 in the BOSNC

Romans 7 in the BOTLNT

Romans 7 in the BOVCB

Romans 7 in the BPBB

Romans 7 in the BPH

Romans 7 in the BSB

Romans 7 in the CCB

Romans 7 in the CUV

Romans 7 in the CUVS

Romans 7 in the DBT

Romans 7 in the DGDNT

Romans 7 in the DHNT

Romans 7 in the DNT

Romans 7 in the ELBE

Romans 7 in the EMTV

Romans 7 in the ESV

Romans 7 in the FBV

Romans 7 in the FEB

Romans 7 in the GGMNT

Romans 7 in the GNT

Romans 7 in the HARY

Romans 7 in the HNT

Romans 7 in the IRVA

Romans 7 in the IRVB

Romans 7 in the IRVG

Romans 7 in the IRVH

Romans 7 in the IRVK

Romans 7 in the IRVM

Romans 7 in the IRVM2

Romans 7 in the IRVO

Romans 7 in the IRVP

Romans 7 in the IRVT

Romans 7 in the IRVT2

Romans 7 in the IRVU

Romans 7 in the ISVN

Romans 7 in the JSNT

Romans 7 in the KAPI

Romans 7 in the KBT1ETNIK

Romans 7 in the KBV

Romans 7 in the KJV

Romans 7 in the KNFD

Romans 7 in the LBA

Romans 7 in the LBLA

Romans 7 in the LNT

Romans 7 in the LSV

Romans 7 in the MAAL

Romans 7 in the MBV

Romans 7 in the MBV2

Romans 7 in the MHNT

Romans 7 in the MKNFD

Romans 7 in the MNG

Romans 7 in the MNT

Romans 7 in the MNT2

Romans 7 in the MRS1T

Romans 7 in the NAA

Romans 7 in the NASB

Romans 7 in the NBLA

Romans 7 in the NBS

Romans 7 in the NBVTP

Romans 7 in the NET2

Romans 7 in the NIV11

Romans 7 in the NNT

Romans 7 in the NNT2

Romans 7 in the NNT3

Romans 7 in the PDDPT

Romans 7 in the PFNT

Romans 7 in the RMNT

Romans 7 in the SBIAS

Romans 7 in the SBIBS

Romans 7 in the SBIBS2

Romans 7 in the SBICS

Romans 7 in the SBIDS

Romans 7 in the SBIGS

Romans 7 in the SBIHS

Romans 7 in the SBIIS

Romans 7 in the SBIIS2

Romans 7 in the SBIIS3

Romans 7 in the SBIKS

Romans 7 in the SBIKS2

Romans 7 in the SBIMS

Romans 7 in the SBIOS

Romans 7 in the SBIPS

Romans 7 in the SBISS

Romans 7 in the SBITS

Romans 7 in the SBITS2

Romans 7 in the SBITS3

Romans 7 in the SBITS4

Romans 7 in the SBIUS

Romans 7 in the SBIVS

Romans 7 in the SBT

Romans 7 in the SBT1E

Romans 7 in the SCHL

Romans 7 in the SNT

Romans 7 in the SUSU

Romans 7 in the SUSU2

Romans 7 in the SYNO

Romans 7 in the TBIAOTANT

Romans 7 in the TBT1E

Romans 7 in the TBT1E2

Romans 7 in the TFTIP

Romans 7 in the TFTU

Romans 7 in the TGNTATF3T

Romans 7 in the THAI

Romans 7 in the TNFD

Romans 7 in the TNT

Romans 7 in the TNTIK

Romans 7 in the TNTIL

Romans 7 in the TNTIN

Romans 7 in the TNTIP

Romans 7 in the TNTIZ

Romans 7 in the TOMA

Romans 7 in the TTENT

Romans 7 in the UBG

Romans 7 in the UGV

Romans 7 in the UGV2

Romans 7 in the UGV3

Romans 7 in the VBL

Romans 7 in the VDCC

Romans 7 in the YALU

Romans 7 in the YAPE

Romans 7 in the YBVTP

Romans 7 in the ZBP