Acts 25 (BOYCB)

1 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tí ó dé sí ilẹ̀ náà, Festu gòkè láti Kesarea lọ sì Jerusalẹmu, 2 ní ibi tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn ènìyàn pàtàkì nínú àwọn Júù ti gbé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Paulu wá, wọ́n sì bẹ̀ ẹ́. 3 Wọ́n tọrọ lọ́wọ́ Festu, kí ó bá le ṣe ojúrere fún wọn, kí ó bá à lè jẹ́ kí wọn mú Paulu wá sí Jerusalẹmu, wọn ń gbìmọ̀ láti dènà dè é, kí wọn sì pa á ní ọ̀nà. 4 Ṣùgbọ́n Festu dáhùn pé, “A pa Paulu mọ́ ní Kesarea, àti pé òun tìkára òun ń múra àti padà lọ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí. 5 Ẹ jẹ́ kí díẹ̀ nínú àwọn olórí yín bá mi sọ̀kalẹ̀ lọ láti fi ìdí ẹ̀sùn tí ẹ fi sun ọkùnrin náà múlẹ̀ níbẹ̀, bí ó bá ní ohun búburú kan tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀.” 6 Lẹ́yìn tí ó sì ti gbé níwọ̀n ọjọ́ mẹ́jọ tàbí mẹ́wàá pẹ̀lú wọn, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sì Kesarea, ni ọjọ́ kejì ó jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́, ó sì pàṣẹ pé ki a mú Paulu wá síwájú òun. 7 Nígbà tí Paulu sì dé, àwọn Júù tí o tí Jerusalẹmu sọ̀kalẹ̀ wá dúró yí i ká, wọ́n ǹ ka ọ̀ràn púpọ̀ tí ó sì burú sí Paulu lọ́rùn, tí wọn kò lè fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀. 8 Paulu si wí tí ẹnu rẹ̀ pé, “Èmi kò ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ kan sì òfin àwọn Júù, tàbí tẹmpili, tàbí sí Kesari.” 9 Ṣùgbọ́n Festu ń fẹ́ láti ní ojúrere lọ́dọ̀ àwọn Júù, ó sì dá Paulu lóhùn, wí pe, “Ìwọ ń fẹ́ gòkè lọ sì Jerusalẹmu, kí a sì ṣe ẹjọ́ nǹkan wọ̀nyí níbẹ̀ níwájú mi bí?” 10 Paulu sì wí pé, “Mo dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Kesari níbi tí ó yẹ kí a ṣe ẹjọ́ mí: èmi kò ṣẹ àwọn Júù, bí ìwọ pẹ̀lú ti mọ̀ dájú. 11 Ǹjẹ́ bí mo bá ṣẹ̀, tí ó ṣe pe mo sì ṣe ohun kan tí ó yẹ fún ikú, èmi kò kọ̀ láti kú, ṣùgbọ́n bí kò bá sí òtítọ́ kan nínú ẹ̀sùn tí àwọn Júù yìí fi mi sùn sí, ẹnìkan kò lẹ́tọ̀ọ́ láti fà mí lé wọn lọ́wọ́. Mo fi ọ̀ràn mi lọ Kesari.” 12 Lẹ́yìn tí Festu ti bá àjọ ìgbìmọ̀ sọ̀rọ̀, ó dáhùn pe, “Ìwọ ti fi ọ̀ràn rẹ lọ Kesari. Ní ọ̀dọ̀ Kesari ni ìwọ ó lọ!” 13 Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, Agrippa ọba, àti Bernike sọ̀kalẹ̀ wá sì Kesarea láti kí Festu. 14 Bí wọ́n sì tí wà níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, Festu mú ọ̀ràn Paulu wá síwájú ọba, wí pé, “Feliksi fi ọkùnrin kan sílẹ̀ nínú túbú. 15 Ẹni tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà àwọn Júù fi sùn nígbà tí mo wà ni Jerusalẹmu, wọ́n ń fẹ́ kí èmi ó dá a lẹ́bi ikú. 16 “Àwọn ẹni tí mo sì dá lóhùn pé, kì í ṣe àṣà àwọn ará Romu láti dá ẹnikẹ́ni lẹ́bi, kí ẹni tí a fi sùn náà tó ko àwọn olùfisùn rẹ̀ lójú, láti lè ri ààyè wí tí ẹnu rẹ̀, nítorí ọ̀ràn tí a kà sí i lọ́rùn. 17 Nítorí náà nígbà tí wọ́n jùmọ̀ wá sí ìhín yìí, èmi kò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀ rara, níjọ́ kejì mo jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́, mo sì pàṣẹ pé kí a mú ọkùnrin náà wá. 18 Nígbà tí àwọn olùfisùn náà dìde, wọn kò ka ọ̀ràn búburú irú èyí tí mo rò sí i lọ́rùn. 19 Ṣùgbọ́n wọ́n ní ọ̀ràn kan sí i, ní ti ìsìn wọn, àti ní ti Jesu kan tí o tí kú, tí Paulu tẹnumọ́ pé ó wà láààyè. 20 Bí èmi kò sì tí mọ̀ bí a tí ń ṣe ìwádìí nǹkan wọ̀nyí, mo bí i lérè pé ṣe ó ń fẹ́ lọ sì Jerusalẹmu, kí a sì ṣe ẹjọ́ nǹkan wọ̀nyí níbẹ̀. 21 Ṣùgbọ́n nígbà tí Paulu fi ọ̀ràn rẹ lọ Augustu, pé kí a pa òun mọ́ fún ìdájọ́ rẹ̀, mo pàṣẹ pe kí a pa á mọ́ títí èmi o fi lè rán an lọ sọ́dọ̀ Kesari.” 22 Agrippa wí fún Festu pé, “Èmi pẹ̀lú fẹ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọkùnrin náà tìkára mi.”Ó sì wí pé, “Ní ọ̀la ìwọ ó gbọ́ ọ.” 23 Ní ọjọ́ kejì, tí Agrippa àti Bernike wọ ilé ẹjọ́ ti àwọn ti ẹ̀ṣọ́ púpọ̀ pẹ̀lú àwọn olórí ogun àti àwọn ènìyàn ńlá ní ìlú, Festu pàṣẹ, wọ́n sì mú Paulu jáde. 24 Festu sì wí pé, “Agrippa ọba, àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn tí ó wà níhìn-ín pẹ̀lú wa, ẹ̀yin rí ọkùnrin yìí, nítorí ẹni tí gbogbo ìjọ àwọn Júù tí fi ẹ̀bẹ̀ béèrè lọ́wọ́ mi ni Jerusalẹmu àti Kesarea níhìn-ín yìí, tí wọ́n ń kígbe pé, kò yẹ fún un láti wà láààyè mọ́. 25 Ṣùgbọ́n èmi rí i pe, kò ṣe ohun kan tí ó yẹ sí ikú, bí òun tìkára rẹ̀ sí tí fi ọ̀ràn rẹ̀ lọ Augustu, mo tí pinnu láti rán an lọ. 26 Ṣùgbọ́n èmi kò ri ohun kan dájúdájú láti kọ̀wé sí olúwa mi. Nítorí náà ni mo ṣe mú un jáde wá síwájú yín, àní síwájú rẹ ọba Agrippa, kí o fi jẹ́ pé lẹ́yìn tí a ba tí ṣe ìwádìí rẹ̀, èmi yóò lè rí ohun tí èmi yóò kọ. 27 Nítorí tí kò tọ́ ní ojú mi láti rán òǹdè, kí a má sì sọ ọ̀ràn tí a kà sí i lọ́rùn.”

In Other Versions

Acts 25 in the ANGEFD

Acts 25 in the ANTPNG2D

Acts 25 in the AS21

Acts 25 in the BAGH

Acts 25 in the BBPNG

Acts 25 in the BBT1E

Acts 25 in the BDS

Acts 25 in the BEV

Acts 25 in the BHAD

Acts 25 in the BIB

Acts 25 in the BLPT

Acts 25 in the BNT

Acts 25 in the BNTABOOT

Acts 25 in the BNTLV

Acts 25 in the BOATCB

Acts 25 in the BOATCB2

Acts 25 in the BOBCV

Acts 25 in the BOCNT

Acts 25 in the BOECS

Acts 25 in the BOGWICC

Acts 25 in the BOHCB

Acts 25 in the BOHCV

Acts 25 in the BOHLNT

Acts 25 in the BOHNTLTAL

Acts 25 in the BOICB

Acts 25 in the BOILNTAP

Acts 25 in the BOITCV

Acts 25 in the BOKCV

Acts 25 in the BOKCV2

Acts 25 in the BOKHWOG

Acts 25 in the BOKSSV

Acts 25 in the BOLCB

Acts 25 in the BOLCB2

Acts 25 in the BOMCV

Acts 25 in the BONAV

Acts 25 in the BONCB

Acts 25 in the BONLT

Acts 25 in the BONUT2

Acts 25 in the BOPLNT

Acts 25 in the BOSCB

Acts 25 in the BOSNC

Acts 25 in the BOTLNT

Acts 25 in the BOVCB

Acts 25 in the BPBB

Acts 25 in the BPH

Acts 25 in the BSB

Acts 25 in the CCB

Acts 25 in the CUV

Acts 25 in the CUVS

Acts 25 in the DBT

Acts 25 in the DGDNT

Acts 25 in the DHNT

Acts 25 in the DNT

Acts 25 in the ELBE

Acts 25 in the EMTV

Acts 25 in the ESV

Acts 25 in the FBV

Acts 25 in the FEB

Acts 25 in the GGMNT

Acts 25 in the GNT

Acts 25 in the HARY

Acts 25 in the HNT

Acts 25 in the IRVA

Acts 25 in the IRVB

Acts 25 in the IRVG

Acts 25 in the IRVH

Acts 25 in the IRVK

Acts 25 in the IRVM

Acts 25 in the IRVM2

Acts 25 in the IRVO

Acts 25 in the IRVP

Acts 25 in the IRVT

Acts 25 in the IRVT2

Acts 25 in the IRVU

Acts 25 in the ISVN

Acts 25 in the JSNT

Acts 25 in the KAPI

Acts 25 in the KBT1ETNIK

Acts 25 in the KBV

Acts 25 in the KJV

Acts 25 in the KNFD

Acts 25 in the LBA

Acts 25 in the LBLA

Acts 25 in the LNT

Acts 25 in the LSV

Acts 25 in the MAAL

Acts 25 in the MBV

Acts 25 in the MBV2

Acts 25 in the MHNT

Acts 25 in the MKNFD

Acts 25 in the MNG

Acts 25 in the MNT

Acts 25 in the MNT2

Acts 25 in the MRS1T

Acts 25 in the NAA

Acts 25 in the NASB

Acts 25 in the NBLA

Acts 25 in the NBS

Acts 25 in the NBVTP

Acts 25 in the NET2

Acts 25 in the NIV11

Acts 25 in the NNT

Acts 25 in the NNT2

Acts 25 in the NNT3

Acts 25 in the PDDPT

Acts 25 in the PFNT

Acts 25 in the RMNT

Acts 25 in the SBIAS

Acts 25 in the SBIBS

Acts 25 in the SBIBS2

Acts 25 in the SBICS

Acts 25 in the SBIDS

Acts 25 in the SBIGS

Acts 25 in the SBIHS

Acts 25 in the SBIIS

Acts 25 in the SBIIS2

Acts 25 in the SBIIS3

Acts 25 in the SBIKS

Acts 25 in the SBIKS2

Acts 25 in the SBIMS

Acts 25 in the SBIOS

Acts 25 in the SBIPS

Acts 25 in the SBISS

Acts 25 in the SBITS

Acts 25 in the SBITS2

Acts 25 in the SBITS3

Acts 25 in the SBITS4

Acts 25 in the SBIUS

Acts 25 in the SBIVS

Acts 25 in the SBT

Acts 25 in the SBT1E

Acts 25 in the SCHL

Acts 25 in the SNT

Acts 25 in the SUSU

Acts 25 in the SUSU2

Acts 25 in the SYNO

Acts 25 in the TBIAOTANT

Acts 25 in the TBT1E

Acts 25 in the TBT1E2

Acts 25 in the TFTIP

Acts 25 in the TFTU

Acts 25 in the TGNTATF3T

Acts 25 in the THAI

Acts 25 in the TNFD

Acts 25 in the TNT

Acts 25 in the TNTIK

Acts 25 in the TNTIL

Acts 25 in the TNTIN

Acts 25 in the TNTIP

Acts 25 in the TNTIZ

Acts 25 in the TOMA

Acts 25 in the TTENT

Acts 25 in the UBG

Acts 25 in the UGV

Acts 25 in the UGV2

Acts 25 in the UGV3

Acts 25 in the VBL

Acts 25 in the VDCC

Acts 25 in the YALU

Acts 25 in the YAPE

Acts 25 in the YBVTP

Acts 25 in the ZBP