Deuteronomy 22 (BOYCB)
        
        
          1 Bí o bá rí màlúù tàbí àgùntàn arákùnrin rẹ tí ó ń sọnù, má ṣe ṣé àìkíyèsí i rẹ̀ ṣùgbọ́n rí i dájú pé o mú padà wá fún un. 2 Bí ọkùnrin náà kì í bá gbé ní tòsí rẹ tàbí bí o kò bá mọ ẹni náà, mú un lọ ilé pẹ̀lú rẹ kí o sì fi pamọ́ títí yóò fi wá a wá. Nígbà náà ni kí o fi fún un. 3 Ṣe bákan náà tí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ arákùnrin rẹ tàbí aṣọ ìlekè tàbí ohunkóhun rẹ̀ tí ó sọnù. Má ṣe ṣe àìkíyèsí i rẹ̀.  4 Bí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí màlúù arákùnrin rẹ tí o dùbúlẹ̀ sójú ọ̀nà, má ṣe ṣàìfiyèsí i rẹ̀, ràn án lọ́wọ́ láti dìde dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀.  5 Obìnrin kò gbọdọ̀ wọ aṣọ ọkùnrin, tàbí kí ọkùnrin wọ aṣọ obìnrin, nítorí OLÚWA Ọlọ́run rẹ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó ṣe èyí.  6 Bí ìwọ bá ṣe alábòápàdé ìtẹ́ ẹyẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, bóyá lára igi tàbí lórí ilẹ̀, tí ìyá wọn sì jókòó lórí àwọn ọmọ, tàbí lórí àwọn ẹyin, má ṣe gbé ìyá pẹ̀lú àwọn ọmọ. 7 Ìwọ lè gbé ọmọ, ṣùgbọ́n rí i dájú pé o jọ̀wọ́ ìyá lọ́wọ́ lọ, kí ó ba à lè dára fún ọ àti kí o lè ní ẹ̀mí gígùn.  8 Nígbà tí o bá kọ́ ilé tuntun, mọ odi yí òrùlé rẹ̀ ká nítorí kí o má ba à mú ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀ wá sórí ilẹ̀ rẹ bí ẹnikẹ́ni bá ṣubú láti òrùlé.  9 Má ṣe gbin oríṣìí èso méjì sínú ọgbà àjàrà rẹ; bí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, kì í ṣe èso oko tí o gbìn nìkan ṣùgbọ́n èso ọgbà àjàrà pẹ̀lú yóò bàjẹ́.  10 Ìwọ kò gbọdọ̀ fi akọ màlúù àti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tulẹ̀ pọ̀.  11 Ìwọ kò gbọdọ̀ wọ aṣọ onírun àgùntàn àti aṣọ funfun papọ̀.  12 Kí o ṣe wajawaja sí etí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin aṣọ ìlekè rẹ.  13 Bí ọkùnrin kan bá mú ìyàwó àti, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti dùbúlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, kórìíra rẹ̀, 14 tí ó ṣì sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sì i, tí o sì fún un ní orúkọ búburú, wí pé, “Mo fẹ́ obìnrin yìí, ṣùgbọ́n nígbà tí mo súnmọ́ ọn. Èmi kò rí àmì ìbálé rẹ̀.” 15 Nígbà náà ni baba ọmọbìnrin náà àti ìyá rẹ̀ yóò mú ẹ̀rí pé, ó ti wà ní ìbálé tẹ́lẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ àwọn àgbàgbà ìlú ní ẹnu-bodè. 16 Baba obìnrin náà yóò wí fún àwọn àgbàgbà pé, “Mo fi ọmọbìnrin mi fún ọkùnrin yìí láti fẹ́ níyàwó, ṣùgbọ́n ó kórìíra rẹ̀. 17 Ní ìsinsin yìí ó ti sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí i ó sì wí pé, ‘Èmi kò rí ọmọbìnrin rẹ kí ó wà ní wúńdíá.’ Ṣùgbọ́n níhìn-ín yìí ni ẹ̀rí ìbálé ọmọbìnrin mi.” Nígbà náà ni àwọn òbí rẹ̀ yóò fi aṣọ hàn níwájú àwọn àgbàgbà ìlú, 18 àwọn àgbàgbà yóò sì mú ọkùnrin náà, wọn yóò sì jẹ ní yà. 19 Wọn yóò sì gba ìtánràn ọgọ́rùn-ún ṣékélì owó fàdákà fún baba ọmọbìnrin náà, nítorí ọkùnrin yìí ti fi orúkọ búburú fún wúńdíá Israẹli. Yóò sì máa ṣe ìyàwó rẹ̀; kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní gbogbo ayé e rẹ̀.  20 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀sùn náà bá jẹ́ òtítọ́ tí a kò sí rí ẹ̀rí ìbálé obìnrin náà, 21 wọn yóò mú wá sí ẹnu-ọ̀nà ilé baba rẹ̀ níbẹ̀ sì ni àwọn ọkùnrin ìlú rẹ̀ yóò ti sọ ọ́ ní òkúta pa. Ó ti ṣe ohun ìtìjú ní Israẹli nípa ṣíṣe àgbèrè nígbà tí ó wà nílé baba rẹ̀. Ẹ ní láti pa ohun búburú kúrò láàrín yín.  22 Bí o bá rí ọkùnrin kan tí ó bá ìyàwó ọkùnrin mìíràn lòpọ̀, àwọn méjèèjì ní láti kú. Ẹ ní láti pa ohun búburú kúrò láàrín Israẹli.  23 Bí ó bá ṣẹlẹ̀ wí pé ọkùnrin kan pàdé wúńdíá tí a ti fi fún ni láti fẹ́ láàrín ìlú tí ó sì lòpọ̀ pẹ̀lú u rẹ̀, 24 ìwọ yóò mú àwọn méjèèjì lọ sí ẹnu ibodè ìlú náà kí o sì sọ wọ́n ní òkúta pa nítorí ọmọbìnrin náà wà ní ìlú kò sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́, àti ọkùnrin náà nítorí ó ba ìyàwó ọkùnrin mìíràn jẹ́. O ní láti wẹ búburú kúrò láàrín rẹ.  25 Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìgbẹ́ ní ó ti ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan ti pàdé ọmọbìnrin tí a ti fẹ́ ṣọ́nà tí o sì fi tagbára tagbára bá a ṣe, ọkùnrin náà nìkan tí ó ṣe èyí ni yóò kú. 26 Má ṣe fi ohunkóhun ṣe ọmọbìnrin náà; kò ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó tọ́ sí ikú. Ẹjọ́ yìí rí bí i ti ẹnìkan tí a gbámú tí ó pa aládùúgbò rẹ̀. 27 Nítorí ọkùnrin náà rí ọmọbìnrin náà ní ìta ibodè, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọbìnrin àfẹ́sọ́nà kígbe, kò sí ẹnìkankan níbẹ̀ láti gbà á kalẹ̀.  28 Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin pàdé wúńdíá tí kò ì tí ì ní àfẹ́sọ́nà tí ó sì fi tipátipá bá a ṣe tí a gbá wọn mú. 29 Ó ní láti san àádọ́ta fàdákà fún baba obìnrin náà, nítorí tí ó ti bà á jẹ́. Kò lè kọ̀ ọ́ sílẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ó sì wà láààyè.  30 Ọkùnrin kò gbọdọ̀ fẹ́ ìyàwó baba rẹ̀; kò gbọdọ̀ sọ ìtẹ́ baba rẹ̀ di àìlọ́wọ̀.
        
        
          In Other Versions
        
        
  
    Deuteronomy 22 in the ANGEFD
  
  
    Deuteronomy 22 in the ANTPNG2D
  
  
    Deuteronomy 22 in the AS21
  
  
    Deuteronomy 22 in the BAGH
  
  
    Deuteronomy 22 in the BBPNG
  
  
    Deuteronomy 22 in the BBT1E
  
  
    Deuteronomy 22 in the BDS
  
  
    Deuteronomy 22 in the BEV
  
  
    Deuteronomy 22 in the BHAD
  
  
    Deuteronomy 22 in the BIB
  
  
    Deuteronomy 22 in the BLPT
  
  
    Deuteronomy 22 in the BNT
  
  
    Deuteronomy 22 in the BNTABOOT
  
  
    Deuteronomy 22 in the BNTLV
  
  
    Deuteronomy 22 in the BOATCB
  
  
    Deuteronomy 22 in the BOATCB2
  
  
    Deuteronomy 22 in the BOBCV
  
  
    Deuteronomy 22 in the BOCNT
  
  
    Deuteronomy 22 in the BOECS
  
  
    Deuteronomy 22 in the BOGWICC
  
  
    Deuteronomy 22 in the BOHCB
  
  
    Deuteronomy 22 in the BOHCV
  
  
    Deuteronomy 22 in the BOHLNT
  
  
    Deuteronomy 22 in the BOHNTLTAL
  
  
    Deuteronomy 22 in the BOICB
  
  
    Deuteronomy 22 in the BOILNTAP
  
  
    Deuteronomy 22 in the BOITCV
  
  
    Deuteronomy 22 in the BOKCV
  
  
    Deuteronomy 22 in the BOKCV2
  
  
    Deuteronomy 22 in the BOKHWOG
  
  
    Deuteronomy 22 in the BOKSSV
  
  
    Deuteronomy 22 in the BOLCB
  
  
    Deuteronomy 22 in the BOLCB2
  
  
    Deuteronomy 22 in the BOMCV
  
  
    Deuteronomy 22 in the BONAV
  
  
    Deuteronomy 22 in the BONCB
  
  
    Deuteronomy 22 in the BONLT
  
  
    Deuteronomy 22 in the BONUT2
  
  
    Deuteronomy 22 in the BOPLNT
  
  
    Deuteronomy 22 in the BOSCB
  
  
    Deuteronomy 22 in the BOSNC
  
  
    Deuteronomy 22 in the BOTLNT
  
  
    Deuteronomy 22 in the BOVCB
  
  
    Deuteronomy 22 in the BPBB
  
  
    Deuteronomy 22 in the BPH
  
  
    Deuteronomy 22 in the BSB
  
  
    Deuteronomy 22 in the CCB
  
  
    Deuteronomy 22 in the CUV
  
  
    Deuteronomy 22 in the CUVS
  
  
    Deuteronomy 22 in the DBT
  
  
    Deuteronomy 22 in the DGDNT
  
  
    Deuteronomy 22 in the DHNT
  
  
    Deuteronomy 22 in the DNT
  
  
    Deuteronomy 22 in the ELBE
  
  
    Deuteronomy 22 in the EMTV
  
  
    Deuteronomy 22 in the ESV
  
  
    Deuteronomy 22 in the FBV
  
  
    Deuteronomy 22 in the FEB
  
  
    Deuteronomy 22 in the GGMNT
  
  
    Deuteronomy 22 in the GNT
  
  
    Deuteronomy 22 in the HARY
  
  
    Deuteronomy 22 in the HNT
  
  
    Deuteronomy 22 in the IRVA
  
  
    Deuteronomy 22 in the IRVB
  
  
    Deuteronomy 22 in the IRVG
  
  
    Deuteronomy 22 in the IRVH
  
  
    Deuteronomy 22 in the IRVK
  
  
    Deuteronomy 22 in the IRVM
  
  
    Deuteronomy 22 in the IRVM2
  
  
    Deuteronomy 22 in the IRVO
  
  
    Deuteronomy 22 in the IRVP
  
  
    Deuteronomy 22 in the IRVT
  
  
    Deuteronomy 22 in the IRVT2
  
  
    Deuteronomy 22 in the IRVU
  
  
    Deuteronomy 22 in the ISVN
  
  
    Deuteronomy 22 in the JSNT
  
  
    Deuteronomy 22 in the KAPI
  
  
    Deuteronomy 22 in the KBT1ETNIK
  
  
    Deuteronomy 22 in the KBV
  
  
    Deuteronomy 22 in the KJV
  
  
    Deuteronomy 22 in the KNFD
  
  
    Deuteronomy 22 in the LBA
  
  
    Deuteronomy 22 in the LBLA
  
  
    Deuteronomy 22 in the LNT
  
  
    Deuteronomy 22 in the LSV
  
  
    Deuteronomy 22 in the MAAL
  
  
    Deuteronomy 22 in the MBV
  
  
    Deuteronomy 22 in the MBV2
  
  
    Deuteronomy 22 in the MHNT
  
  
    Deuteronomy 22 in the MKNFD
  
  
    Deuteronomy 22 in the MNG
  
  
    Deuteronomy 22 in the MNT
  
  
    Deuteronomy 22 in the MNT2
  
  
    Deuteronomy 22 in the MRS1T
  
  
    Deuteronomy 22 in the NAA
  
  
    Deuteronomy 22 in the NASB
  
  
    Deuteronomy 22 in the NBLA
  
  
    Deuteronomy 22 in the NBS
  
  
    Deuteronomy 22 in the NBVTP
  
  
    Deuteronomy 22 in the NET2
  
  
    Deuteronomy 22 in the NIV11
  
  
    Deuteronomy 22 in the NNT
  
  
    Deuteronomy 22 in the NNT2
  
  
    Deuteronomy 22 in the NNT3
  
  
    Deuteronomy 22 in the PDDPT
  
  
    Deuteronomy 22 in the PFNT
  
  
    Deuteronomy 22 in the RMNT
  
  
    Deuteronomy 22 in the SBIAS
  
  
    Deuteronomy 22 in the SBIBS
  
  
    Deuteronomy 22 in the SBIBS2
  
  
    Deuteronomy 22 in the SBICS
  
  
    Deuteronomy 22 in the SBIDS
  
  
    Deuteronomy 22 in the SBIGS
  
  
    Deuteronomy 22 in the SBIHS
  
  
    Deuteronomy 22 in the SBIIS
  
  
    Deuteronomy 22 in the SBIIS2
  
  
    Deuteronomy 22 in the SBIIS3
  
  
    Deuteronomy 22 in the SBIKS
  
  
    Deuteronomy 22 in the SBIKS2
  
  
    Deuteronomy 22 in the SBIMS
  
  
    Deuteronomy 22 in the SBIOS
  
  
    Deuteronomy 22 in the SBIPS
  
  
    Deuteronomy 22 in the SBISS
  
  
    Deuteronomy 22 in the SBITS
  
  
    Deuteronomy 22 in the SBITS2
  
  
    Deuteronomy 22 in the SBITS3
  
  
    Deuteronomy 22 in the SBITS4
  
  
    Deuteronomy 22 in the SBIUS
  
  
    Deuteronomy 22 in the SBIVS
  
  
    Deuteronomy 22 in the SBT
  
  
    Deuteronomy 22 in the SBT1E
  
  
    Deuteronomy 22 in the SCHL
  
  
    Deuteronomy 22 in the SNT
  
  
    Deuteronomy 22 in the SUSU
  
  
    Deuteronomy 22 in the SUSU2
  
  
    Deuteronomy 22 in the SYNO
  
  
    Deuteronomy 22 in the TBIAOTANT
  
  
    Deuteronomy 22 in the TBT1E
  
  
    Deuteronomy 22 in the TBT1E2
  
  
    Deuteronomy 22 in the TFTIP
  
  
    Deuteronomy 22 in the TFTU
  
  
    Deuteronomy 22 in the TGNTATF3T
  
  
    Deuteronomy 22 in the THAI
  
  
    Deuteronomy 22 in the TNFD
  
  
    Deuteronomy 22 in the TNT
  
  
    Deuteronomy 22 in the TNTIK
  
  
    Deuteronomy 22 in the TNTIL
  
  
    Deuteronomy 22 in the TNTIN
  
  
    Deuteronomy 22 in the TNTIP
  
  
    Deuteronomy 22 in the TNTIZ
  
  
    Deuteronomy 22 in the TOMA
  
  
    Deuteronomy 22 in the TTENT
  
  
    Deuteronomy 22 in the UBG
  
  
    Deuteronomy 22 in the UGV
  
  
    Deuteronomy 22 in the UGV2
  
  
    Deuteronomy 22 in the UGV3
  
  
    Deuteronomy 22 in the VBL
  
  
    Deuteronomy 22 in the VDCC
  
  
    Deuteronomy 22 in the YALU
  
  
    Deuteronomy 22 in the YAPE
  
  
    Deuteronomy 22 in the YBVTP
  
  
    Deuteronomy 22 in the ZBP