Deuteronomy 33 (BOYCB)
1 Èyí ni ìbùkún tí Mose ènìyàn Ọlọ́run bùkún fún àwọn ọmọ Israẹli kí ó tó kú. 2 Ó sì wí pé,“OLÚWA ti Sinai wá,ó sì yọ sí wọn láti Seiri wáó sì tàn án jáde láti òkè Parani wá.Ó ti ọ̀dọ̀ ẹgbẹgbàarùn-ún àwọn mímọ́ wáláti ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni òfin kan a mú bí iná ti jáde fún wọn wá. 3 Nítòótọ́, ó fẹ́ràn àwọn ènìyàn an rẹ̀,gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ wà ní ọwọ́ rẹ̀.Ní ẹsẹ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti foríbalẹ̀,àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti ń gba ọ̀rọ̀, 4 òfin tí Mose fi fún wa,ìní ti ìjọ ènìyàn Jakọbu. 5 Òun ni ọba lórí Jeṣuruniní ìgbà tí olórí àwọn ènìyàn péjọpọ̀,pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Israẹli. 6 “Jẹ́ kí Reubeni yè kí ó má ṣe kú,tàbí kí ènìyàn rẹ mọ níwọ̀n.” 7 Èyí ni ohun tí ó sọ nípa Juda:“OLÚWA gbọ́ ohùn Judakí o sì mú tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ wá.Kí ọwọ́ rẹ̀ kí ó tó fún un,kí ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀!” 8 Ní ti Lefi ó wí pé,“Jẹ́ kí Tumimu àti Urimu rẹ kí ó wàpẹ̀lú ẹni mímọ́ rẹ.Ẹni tí ó dánwò ní Massa,ìwọ bá jà ní omi Meriba. 9 Ó wí fún baba àti ìyá rẹ pé,‘Èmi kò buyì fún wọn.’Kò mọ àwọn arákùnrin rẹ̀,tàbí mọ àwọn ọmọ rẹ̀,ṣùgbọ́n ó dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀,ó sì pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́. 10 Ó kọ́ Jakọbu ní ìdájọ́ rẹ̀àti Israẹli ní òfin rẹ̀.Ó mú tùràrí wá síwájú rẹ̀àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹbọ sísun sórí i pẹpẹ rẹ̀. 11 Bùsi ohun ìní rẹ̀, OLÚWA,kí o sì tẹ́wọ́gbà iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.Lu ẹgbẹ́ àwọn tí ó dìde sí i;àwọn tí ó kórìíra rẹ̀,kí wọn kí ó má ṣe dìde mọ́.” 12 Ní ti Benjamini ó wí pé,“Jẹ́ kí olùfẹ́ OLÚWA máa gbé ní àlàáfíà lọ́dọ̀ rẹ̀,òun a máa bò ó ní gbogbo ọjọ́,ẹni tí OLÚWA fẹ́ràn yóò máa sinmi láàrín èjìká rẹ̀.” 13 Ní ti Josẹfu ó wí pé,“Kí OLÚWA bùkún ilẹ̀ rẹ,fún ohun iyebíye láti ọ̀run pẹ̀lú ìrìàti ibú tí ó ń bẹ níṣàlẹ̀; 14 àti fún èso iyebíye tí ọ̀run mú wáàti ti ohun iyebíye tí ń dàgbà ní oṣooṣù; 15 pẹ̀lú ohun pàtàkì òkè ńlá ìgbàanìàti fún ohun iyebíye ìgbà ayérayé; 16 Pẹ̀lú ohun iyebíye ayé àti ẹ̀kún un rẹ̀àti fún ìfẹ́ ẹni tí ó ń gbé inú igbó.Jẹ́ kí gbogbo èyí sinmi lé orí Josẹfu,lórí àtàrí ẹni tí ó yàtọ̀ láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀. 17 Ní ọláńlá ó dàbí àkọ́bí akọ màlúù;ìwo rẹ̀, ìwo àgbáǹréré ni.Pẹ̀lú wọn ni yóò fi ti àwọn orílẹ̀-èdè,pàápàá títí dé òpin ayé.Àwọn sì ni ẹgbẹẹgbàárùn mẹ́wàá Efraimu,àwọn sì ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún Manase.” 18 Ní ti Sebuluni ó wí pé,“Yọ̀ Sebuluni, ní ti ìjáde lọ rẹ,àti ìwọ Isakari, nínú àgọ́ rẹ. 19 Wọn yóò pe àwọn ènìyàn sórí òkèàti níbẹ̀ wọn yóò rú ẹbọ òdodo,wọn yóò mu nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òkun,nínú ìṣúra tí ó pamọ́ nínú iyanrìn.” 20 Ní ti Gadi ó wí pé,“Ìbùkún ni ẹni tí ó mú Gadi gbilẹ̀!Gadi ń gbé níbẹ̀ bí kìnnìún,ó sì fa apá ya, àní àtàrí. 21 Ó sì yan ilẹ̀ tí ó dára jù fún ara rẹ̀;ìpín olórí ni a sì fi fún un.Nígbà tí ó rí tí gbogbo àwọn ènìyàn péjọ,ó mú òdodo OLÚWA ṣẹ,àti ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Israẹli.” 22 Ní ti Dani ó wí pé,“Ọmọ kìnnìún ni Dani,tí ń fò láti Baṣani wá.” 23 Ní ti Naftali ó wí pé,“Ìwọ Naftali, kún fún ojúrere Ọlọ́runàti ìbùkún OLÚWA;yóò jogún ìhà ìwọ̀-oòrùn àti gúúsù.” 24 Ní ti Aṣeri ó wí pé,“Ìbùkún ọmọ ni ti Aṣeri;jẹ́ kí ó rí ojúrere láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀kí ó sì ri ẹsẹ̀ rẹ̀ sínú òróró. 25 Bàtà rẹ̀ yóò jẹ́ irin àti idẹ,agbára rẹ̀ yóò sì rí bí ọjọ́ rẹ̀. 26 “Kò sí ẹlòmíràn bí Ọlọ́run Jeṣuruni,ẹni tí ń gun ọ̀run fún ìrànlọ́wọ́ rẹàti ní ojú ọ̀run nínú ọláńlá rẹ̀. 27 Ọlọ́run ayérayé ni ibi ìsádi rẹ,àti ní ìsàlẹ̀ ni apá ayérayé wà.Yóò lé àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ,ó sì wí pé, ‘Ẹ máa parun!’ 28 Israẹli nìkan yóò jókòó ní àlàáfíà,orísun Jakọbu nìkanní ilẹ̀ ọkà àti ti ọtí wáìnì,níbi tí ọ̀run ti ń sẹ ìrì sílẹ̀. 29 Ìbùkún ni fún ọ, Israẹli,ta ni ó dàbí rẹ,ẹni tí a gbàlà láti ọ̀dọ̀ OLÚWA?Òun ni asà àti ìrànwọ́ rẹ̀àti idà ọláńlá rẹ̀.Àwọn ọ̀tá rẹ yóò tẹríba fún ọ,ìwọ yóò sì tẹ ibi gíga wọn mọ́lẹ̀.”
In Other Versions
Deuteronomy 33 in the ANGEFD
Deuteronomy 33 in the ANTPNG2D
Deuteronomy 33 in the AS21
Deuteronomy 33 in the BAGH
Deuteronomy 33 in the BBPNG
Deuteronomy 33 in the BBT1E
Deuteronomy 33 in the BDS
Deuteronomy 33 in the BEV
Deuteronomy 33 in the BHAD
Deuteronomy 33 in the BIB
Deuteronomy 33 in the BLPT
Deuteronomy 33 in the BNT
Deuteronomy 33 in the BNTABOOT
Deuteronomy 33 in the BNTLV
Deuteronomy 33 in the BOATCB
Deuteronomy 33 in the BOATCB2
Deuteronomy 33 in the BOBCV
Deuteronomy 33 in the BOCNT
Deuteronomy 33 in the BOECS
Deuteronomy 33 in the BOGWICC
Deuteronomy 33 in the BOHCB
Deuteronomy 33 in the BOHCV
Deuteronomy 33 in the BOHLNT
Deuteronomy 33 in the BOHNTLTAL
Deuteronomy 33 in the BOICB
Deuteronomy 33 in the BOILNTAP
Deuteronomy 33 in the BOITCV
Deuteronomy 33 in the BOKCV
Deuteronomy 33 in the BOKCV2
Deuteronomy 33 in the BOKHWOG
Deuteronomy 33 in the BOKSSV
Deuteronomy 33 in the BOLCB
Deuteronomy 33 in the BOLCB2
Deuteronomy 33 in the BOMCV
Deuteronomy 33 in the BONAV
Deuteronomy 33 in the BONCB
Deuteronomy 33 in the BONLT
Deuteronomy 33 in the BONUT2
Deuteronomy 33 in the BOPLNT
Deuteronomy 33 in the BOSCB
Deuteronomy 33 in the BOSNC
Deuteronomy 33 in the BOTLNT
Deuteronomy 33 in the BOVCB
Deuteronomy 33 in the BPBB
Deuteronomy 33 in the BPH
Deuteronomy 33 in the BSB
Deuteronomy 33 in the CCB
Deuteronomy 33 in the CUV
Deuteronomy 33 in the CUVS
Deuteronomy 33 in the DBT
Deuteronomy 33 in the DGDNT
Deuteronomy 33 in the DHNT
Deuteronomy 33 in the DNT
Deuteronomy 33 in the ELBE
Deuteronomy 33 in the EMTV
Deuteronomy 33 in the ESV
Deuteronomy 33 in the FBV
Deuteronomy 33 in the FEB
Deuteronomy 33 in the GGMNT
Deuteronomy 33 in the GNT
Deuteronomy 33 in the HARY
Deuteronomy 33 in the HNT
Deuteronomy 33 in the IRVA
Deuteronomy 33 in the IRVB
Deuteronomy 33 in the IRVG
Deuteronomy 33 in the IRVH
Deuteronomy 33 in the IRVK
Deuteronomy 33 in the IRVM
Deuteronomy 33 in the IRVM2
Deuteronomy 33 in the IRVO
Deuteronomy 33 in the IRVP
Deuteronomy 33 in the IRVT
Deuteronomy 33 in the IRVT2
Deuteronomy 33 in the IRVU
Deuteronomy 33 in the ISVN
Deuteronomy 33 in the JSNT
Deuteronomy 33 in the KAPI
Deuteronomy 33 in the KBT1ETNIK
Deuteronomy 33 in the KBV
Deuteronomy 33 in the KJV
Deuteronomy 33 in the KNFD
Deuteronomy 33 in the LBA
Deuteronomy 33 in the LBLA
Deuteronomy 33 in the LNT
Deuteronomy 33 in the LSV
Deuteronomy 33 in the MAAL
Deuteronomy 33 in the MBV
Deuteronomy 33 in the MBV2
Deuteronomy 33 in the MHNT
Deuteronomy 33 in the MKNFD
Deuteronomy 33 in the MNG
Deuteronomy 33 in the MNT
Deuteronomy 33 in the MNT2
Deuteronomy 33 in the MRS1T
Deuteronomy 33 in the NAA
Deuteronomy 33 in the NASB
Deuteronomy 33 in the NBLA
Deuteronomy 33 in the NBS
Deuteronomy 33 in the NBVTP
Deuteronomy 33 in the NET2
Deuteronomy 33 in the NIV11
Deuteronomy 33 in the NNT
Deuteronomy 33 in the NNT2
Deuteronomy 33 in the NNT3
Deuteronomy 33 in the PDDPT
Deuteronomy 33 in the PFNT
Deuteronomy 33 in the RMNT
Deuteronomy 33 in the SBIAS
Deuteronomy 33 in the SBIBS
Deuteronomy 33 in the SBIBS2
Deuteronomy 33 in the SBICS
Deuteronomy 33 in the SBIDS
Deuteronomy 33 in the SBIGS
Deuteronomy 33 in the SBIHS
Deuteronomy 33 in the SBIIS
Deuteronomy 33 in the SBIIS2
Deuteronomy 33 in the SBIIS3
Deuteronomy 33 in the SBIKS
Deuteronomy 33 in the SBIKS2
Deuteronomy 33 in the SBIMS
Deuteronomy 33 in the SBIOS
Deuteronomy 33 in the SBIPS
Deuteronomy 33 in the SBISS
Deuteronomy 33 in the SBITS
Deuteronomy 33 in the SBITS2
Deuteronomy 33 in the SBITS3
Deuteronomy 33 in the SBITS4
Deuteronomy 33 in the SBIUS
Deuteronomy 33 in the SBIVS
Deuteronomy 33 in the SBT
Deuteronomy 33 in the SBT1E
Deuteronomy 33 in the SCHL
Deuteronomy 33 in the SNT
Deuteronomy 33 in the SUSU
Deuteronomy 33 in the SUSU2
Deuteronomy 33 in the SYNO
Deuteronomy 33 in the TBIAOTANT
Deuteronomy 33 in the TBT1E
Deuteronomy 33 in the TBT1E2
Deuteronomy 33 in the TFTIP
Deuteronomy 33 in the TFTU
Deuteronomy 33 in the TGNTATF3T
Deuteronomy 33 in the THAI
Deuteronomy 33 in the TNFD
Deuteronomy 33 in the TNT
Deuteronomy 33 in the TNTIK
Deuteronomy 33 in the TNTIL
Deuteronomy 33 in the TNTIN
Deuteronomy 33 in the TNTIP
Deuteronomy 33 in the TNTIZ
Deuteronomy 33 in the TOMA
Deuteronomy 33 in the TTENT
Deuteronomy 33 in the UBG
Deuteronomy 33 in the UGV
Deuteronomy 33 in the UGV2
Deuteronomy 33 in the UGV3
Deuteronomy 33 in the VBL
Deuteronomy 33 in the VDCC
Deuteronomy 33 in the YALU
Deuteronomy 33 in the YAPE
Deuteronomy 33 in the YBVTP
Deuteronomy 33 in the ZBP