Isaiah 48 (BOYCB)

1 “Tẹ́tí sí èyí, ìwọ ilé e Jakọbu,ìwọ tí a ń pè pẹ̀lú orúkọ Israẹlití o sì wá láti ẹ̀ka Juda,ìwọ tí ò ń búra ní orúkọ OLÚWAtí o sì ń pe Ọlọ́run Israẹliṣùgbọ́n kì í ṣe ní òtítọ́ àti òdodo, 2 ìwọ tí ò ń pe ara rẹ ní ọmọ ìlú mímọ́ n nìtí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run Israẹli— OLÚWA àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀. 3 Èmi sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀ lọ́jọ́ tó ti pẹ́,ẹnu mi ló ti kéde wọn, mo sì sọ wọ́n di mí mọ̀;lẹ́yìn náà lójijì mo gbé ìgbésẹ̀, wọ́n sì wá sí ìmúṣẹ. 4 Nítorí mo mọ bí ẹ ti jẹ́ olórí kunkun tó;àwọn iṣan ọrùn yín sì jẹ́ irin;bẹ́ẹ̀ ni iwájú yín idẹ ni. 5 Nítorí náà mo ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún ọní ọjọ́ tí ó ti pẹ́;kí wọn ó tó ṣẹlẹ̀ mo ti kéde wọn fún un yíntó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè sọ pé,‘Àwọn ère mi ló ṣe wọ́n;àwọn ère igi àti òrìṣà irin ló fọwọ́sí i.’ 6 Ìwọ ti gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí; wo gbogbo wọn.Ǹjẹ́ o kò nígbà wọ́n bí? “Láti ìsinsin yìí lọ, Èmi yóò máa sọfún ọ nípa nǹkan tuntun,àwọn nǹkan tí ó fi ara sin tí ìwọ kò mọ̀. 7 A dá wọn ní àkókò yìí kì í ṣe láti ìgbà pípẹ́ìwọ kò tí ì gbọ́ nípa wọn títí di òní.Nítorí náà, ìwọ kò lè sọ pé,‘Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ nípa wọn.’ 8 Ìwọ a ha ti gbọ́ tàbí ó ti yé ọ bíláti ìgbà àtijọ́ etí kò ti di yíyà.Ǹjẹ́ mo mọ̀ bí o ti jẹ́ alárékérekè tó;a ń pè ọ́ ní ọlọ̀tẹ̀ láti ìgbà ìbí rẹ. 9 Nítorí orúkọ ara mi, mo dáwọ́ ìbínú mi dúró;nítorí ìyìn ara mi, mo fà á sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ,kí a má ba à ké ọ kúrò. 10 Wò ó, èmi ti tún ọ ṣe, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pékì í ṣe bí i fàdákà;Èmi ti dán ọ wò nínú ìléru ìpọ́njú. 11 Nítorí orúkọ mi, nítorí orúkọ mi, mo ṣe èyí.Báwo ni mo ṣe lè jẹ́ kí a ba orúkọ mi jẹ́.Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmíràn. 12 “Tẹ́tí sí mi, ìwọ JakọbuIsraẹli ẹni tí mo pè.Èmi ni ẹni náà;Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn. 13 Ọwọ́ mi pàápàá ni ó fi àwọn ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,àti ọwọ́ ọ̀tún mi ni ó tẹ àwọn ọ̀run;nígbà tí mo pè wọ́n,gbogbo wọn dìde sókè papọ̀. 14 “Gbogbo yín, ẹ péjọ kí ẹ sì gbọ́.Ta nínú wọn ni ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí. OLÚWA ti fẹ́ ẹ,yóò sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní Babiloni,apá rẹ̀ ni yóò sì wà ní ará àwọn ará Kaldea. 15 Èmi, àní Èmi ló ti sọ̀rọ̀;bẹ́ẹ̀ ni, mo ti pè é.Èmi yóò mú un wá,òun yóò sì ṣe àṣeyọrí nínú ìrìnàjò rẹ̀. 16 “Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi kí ẹ sì dẹtí sí èyí:“Láti ìgbà ìkéde àkọ́kọ́ èmi kò sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀;ní àsìkò tí ó sì ṣẹlẹ̀, Èmi wà níbẹ̀.” Àti ní àkókò yìí, OLÚWA Olódùmarè ni ó ti rán mi,pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ̀. 17 Èyí ni ohun tí OLÚWA wí,Olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ Israẹli:“Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run rẹ,tí ó kọ́ ọ ní ohun tí ó dára fún ọ,tí ó tọ́ ọ ṣọ́nà tí ó yẹ kí o máa rìn. 18 Bí ó bá ṣe pé ìwọ bá ti tẹ́tí sílẹ̀ sí àṣẹ mi,àlàáfíà rẹ kì bá ti dàbí ì ti odò,àti òdodo rẹ bí ìgbì Òkun. 19 Àwọn ọmọ rẹ ìbá ti dàbí iyanrìn,àwọn ọmọ yín bí i hóró ọkà tí a kò lè kà tán;orúkọ wọn ni a kì yóò ké kúròtàbí kí a pa wọ́n run níwájú mi.” 20 Fi Babeli sílẹ̀,sá fún àwọn ará Babeli,ṣe ìfilọ̀ èyí pẹ̀lú ariwo ayọ̀kí o sì kéde rẹ̀.Rán an jáde lọ sí òpin ilẹ̀ ayé;wí pé, “OLÚWA ti dá ìránṣẹ́ rẹ̀ Jakọbu nídè.” 21 Òrùngbẹ kò gbẹ wọ́n nígbà tí ó kó wọnkọjá nínú aginjù;ó jẹ́ kí omi ó sàn fún wọn láti inú àpáta;ó fọ́ àpátaomi sì tú jáde. 22 “Kò sí àlàáfíà,” ni OLÚWA wí,“Fún àwọn ìkà.”

In Other Versions

Isaiah 48 in the ANGEFD

Isaiah 48 in the ANTPNG2D

Isaiah 48 in the AS21

Isaiah 48 in the BAGH

Isaiah 48 in the BBPNG

Isaiah 48 in the BBT1E

Isaiah 48 in the BDS

Isaiah 48 in the BEV

Isaiah 48 in the BHAD

Isaiah 48 in the BIB

Isaiah 48 in the BLPT

Isaiah 48 in the BNT

Isaiah 48 in the BNTABOOT

Isaiah 48 in the BNTLV

Isaiah 48 in the BOATCB

Isaiah 48 in the BOATCB2

Isaiah 48 in the BOBCV

Isaiah 48 in the BOCNT

Isaiah 48 in the BOECS

Isaiah 48 in the BOGWICC

Isaiah 48 in the BOHCB

Isaiah 48 in the BOHCV

Isaiah 48 in the BOHLNT

Isaiah 48 in the BOHNTLTAL

Isaiah 48 in the BOICB

Isaiah 48 in the BOILNTAP

Isaiah 48 in the BOITCV

Isaiah 48 in the BOKCV

Isaiah 48 in the BOKCV2

Isaiah 48 in the BOKHWOG

Isaiah 48 in the BOKSSV

Isaiah 48 in the BOLCB

Isaiah 48 in the BOLCB2

Isaiah 48 in the BOMCV

Isaiah 48 in the BONAV

Isaiah 48 in the BONCB

Isaiah 48 in the BONLT

Isaiah 48 in the BONUT2

Isaiah 48 in the BOPLNT

Isaiah 48 in the BOSCB

Isaiah 48 in the BOSNC

Isaiah 48 in the BOTLNT

Isaiah 48 in the BOVCB

Isaiah 48 in the BPBB

Isaiah 48 in the BPH

Isaiah 48 in the BSB

Isaiah 48 in the CCB

Isaiah 48 in the CUV

Isaiah 48 in the CUVS

Isaiah 48 in the DBT

Isaiah 48 in the DGDNT

Isaiah 48 in the DHNT

Isaiah 48 in the DNT

Isaiah 48 in the ELBE

Isaiah 48 in the EMTV

Isaiah 48 in the ESV

Isaiah 48 in the FBV

Isaiah 48 in the FEB

Isaiah 48 in the GGMNT

Isaiah 48 in the GNT

Isaiah 48 in the HARY

Isaiah 48 in the HNT

Isaiah 48 in the IRVA

Isaiah 48 in the IRVB

Isaiah 48 in the IRVG

Isaiah 48 in the IRVH

Isaiah 48 in the IRVK

Isaiah 48 in the IRVM

Isaiah 48 in the IRVM2

Isaiah 48 in the IRVO

Isaiah 48 in the IRVP

Isaiah 48 in the IRVT

Isaiah 48 in the IRVT2

Isaiah 48 in the IRVU

Isaiah 48 in the ISVN

Isaiah 48 in the JSNT

Isaiah 48 in the KAPI

Isaiah 48 in the KBT1ETNIK

Isaiah 48 in the KBV

Isaiah 48 in the KJV

Isaiah 48 in the KNFD

Isaiah 48 in the LBA

Isaiah 48 in the LBLA

Isaiah 48 in the LNT

Isaiah 48 in the LSV

Isaiah 48 in the MAAL

Isaiah 48 in the MBV

Isaiah 48 in the MBV2

Isaiah 48 in the MHNT

Isaiah 48 in the MKNFD

Isaiah 48 in the MNG

Isaiah 48 in the MNT

Isaiah 48 in the MNT2

Isaiah 48 in the MRS1T

Isaiah 48 in the NAA

Isaiah 48 in the NASB

Isaiah 48 in the NBLA

Isaiah 48 in the NBS

Isaiah 48 in the NBVTP

Isaiah 48 in the NET2

Isaiah 48 in the NIV11

Isaiah 48 in the NNT

Isaiah 48 in the NNT2

Isaiah 48 in the NNT3

Isaiah 48 in the PDDPT

Isaiah 48 in the PFNT

Isaiah 48 in the RMNT

Isaiah 48 in the SBIAS

Isaiah 48 in the SBIBS

Isaiah 48 in the SBIBS2

Isaiah 48 in the SBICS

Isaiah 48 in the SBIDS

Isaiah 48 in the SBIGS

Isaiah 48 in the SBIHS

Isaiah 48 in the SBIIS

Isaiah 48 in the SBIIS2

Isaiah 48 in the SBIIS3

Isaiah 48 in the SBIKS

Isaiah 48 in the SBIKS2

Isaiah 48 in the SBIMS

Isaiah 48 in the SBIOS

Isaiah 48 in the SBIPS

Isaiah 48 in the SBISS

Isaiah 48 in the SBITS

Isaiah 48 in the SBITS2

Isaiah 48 in the SBITS3

Isaiah 48 in the SBITS4

Isaiah 48 in the SBIUS

Isaiah 48 in the SBIVS

Isaiah 48 in the SBT

Isaiah 48 in the SBT1E

Isaiah 48 in the SCHL

Isaiah 48 in the SNT

Isaiah 48 in the SUSU

Isaiah 48 in the SUSU2

Isaiah 48 in the SYNO

Isaiah 48 in the TBIAOTANT

Isaiah 48 in the TBT1E

Isaiah 48 in the TBT1E2

Isaiah 48 in the TFTIP

Isaiah 48 in the TFTU

Isaiah 48 in the TGNTATF3T

Isaiah 48 in the THAI

Isaiah 48 in the TNFD

Isaiah 48 in the TNT

Isaiah 48 in the TNTIK

Isaiah 48 in the TNTIL

Isaiah 48 in the TNTIN

Isaiah 48 in the TNTIP

Isaiah 48 in the TNTIZ

Isaiah 48 in the TOMA

Isaiah 48 in the TTENT

Isaiah 48 in the UBG

Isaiah 48 in the UGV

Isaiah 48 in the UGV2

Isaiah 48 in the UGV3

Isaiah 48 in the VBL

Isaiah 48 in the VDCC

Isaiah 48 in the YALU

Isaiah 48 in the YAPE

Isaiah 48 in the YBVTP

Isaiah 48 in the ZBP