Isaiah 60 (BOYCB)
1 “Dìde, tànmọ́lẹ̀, nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé,ògo OLÚWA sì ràdàbò ọ́. 2 Kíyèsi i, òkùnkùn bo ilẹ̀ ayéòkùnkùn biribiri sì wà lórí àwọn ènìyàn,ṣùgbọ́n OLÚWA ràn bò ọ́ògo rẹ̀ sì farahàn lórí i rẹ. 3 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá sí ìmọ́lẹ̀ rẹ,àti àwọn ọba sí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ rẹ. 4 “Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wò.Gbogbo wọn ṣa ara jọ pọ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ;àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin yóò wá láti ọ̀nà jíjìn,àwọn ọmọ rẹ obìnrin ni a ó tọ́jú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ. 5 Nígbà náà ni ìwọ yóò wò tí ojú rẹ yóò máa dán,ọkàn rẹ yó fò, yó sì kún fún ayọ̀;ọrọ̀ inú Òkun ni a ó kò wá sọ́dọ̀ rẹ,sí ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá. 6 Ọ̀wọ́ ìbákasẹ yóò bo gbogbo ilẹ̀ rẹ,àwọn ọ̀dọ́ ìbákasẹ Midiani àti Efani.Àti gbogbo wọn láti Ṣeba yóò wá,wọn yóò mú wúrà àti tùràrí lọ́wọ́tí wọn yóò sì máa kéde ìyìn OLÚWA. 7 Gbogbo agbo ẹran ìlú Kedari ni a ó kójọ sọ́dọ̀ rẹ,àwọn àgbò ti Nebaioti yóò sìn ọ́;wọn yóò jẹ́ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi,bẹ́ẹ̀ ni n ó sì ṣe tẹmpili ògo mi lọ́ṣọ̀ọ́. 8 “Ta ni àwọn wọ̀nyí tí ń fò lọ bí i kurukuru,gẹ́gẹ́ bí àwọn àdàbà sí ìtẹ́ wọn? 9 Lóòtítọ́ àwọn erékùṣù bojú wò mí;ní ìṣíwájú ni àwọn ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi;mú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn,pẹ̀lú fàdákà àti wúrà wọn,fún ti ọlá OLÚWA Ọlọ́run rẹ,Ẹni Mímọ́ Israẹli,nítorí òun ti fi ohun dídára ṣe ó lọ́ṣọ̀ọ́. 10 “Àwọn àjèjì yóò tún ògiri rẹ mọàwọn ọba wọn yóò sì sìn ọ́.Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ní ìbínú ni mo lù ọ́,ní àánú èmi yóò ṣe inú rere sí ọ. 11 Gbogbo ẹnu-bodè rẹ ni yóò wà ní ṣíṣí sílẹ̀,a kì yóò tì wọ́n ní ọ̀sán àti ní òru,tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọkùnrin yóò le è kóọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè wátí àwọn ọba wọn yóò ṣáájú ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ìṣẹ́gun. 12 Nítorí pé orílẹ̀-èdè tàbí ilẹ̀ ọba tí kì yóò sìn ọ́ ni yóò parun;pátápátá ni yóò sì dahoro. 13 “Ògo Lebanoni yóò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,igi junifa, firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀,láti bu ọlá fún ilé ìsìn mi;àti pé èmi yóò sì ṣe ibi ẹsẹ̀ mi lógo. 14 Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àwọn apọ́nilójú rẹ yóòwá foríbalẹ̀ fún ọ;gbogbo àwọn tí ó ti kẹ́gàn rẹ ni wọn yóò tẹríba níwájú rẹwọn yóò sì pè ọ́ ní ìlú OLÚWA,Sioni ti Ẹni Mímọ́ Israẹli. 15 “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kórìíra rẹ, a sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀,láìsí ẹnìkan tí ó ń gba ọ̀dọ̀ rẹ kọjá,Èmi yóò ṣe ọ́ ní ìṣògo ayérayéàti ayọ̀ àtìrandíran. 16 Ìwọ yóò mu wàrà gbogbo orílẹ̀-èdèa ó sì fun ọ́ ni ọmú àwọn ọba.Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé, Èmi OLÚWA,èmi ni Olùgbàlà rẹ,Olùdáǹdè rẹ, Alágbára ti Jakọbu. 17 Dípò idẹ, èmi ó mú wúrà wá fún ọ,dípò fàdákà èmi ó mú irin wá. Dípò igi yóò mú idẹ wá fún ọ,àti irin dípò òkúta.Èmi yóò fi àlàáfíà ṣe àwọn ìjòyè rẹàti òdodo gẹ́gẹ́ bí alákòóso rẹ. 18 A kì yóò gbọ́ nípa rògbòdìyàn ní ilẹ̀ rẹ mọ́,tàbí ìdahoro àti ìparun nínú agbègbè rẹ,ṣùgbọ́n ìwọ yóò pe ògiri rẹ ní ìgbàlààti àwọn ẹnu-bodè rẹ ní ìyìn. 19 Òòrùn kì yóò sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ní ọ̀sán mọ́,tàbí kí ìtànṣán òṣùpá tún ràn sí ọ mọ́,nítorí OLÚWA ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ayérayé,àti Ọlọ́run rẹ yóò jẹ́ ògo rẹ. 20 Òòrùn rẹ kì yóò sì wọ̀ mọ́,àti òṣùpá rẹ kì yóò sì wọ òòkùn mọ́; OLÚWA ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé rẹ,àti àwọn ọjọ́ arò rẹ yóò sì dópin. 21 Lẹ́yìn náà ni gbogbo àwọn ènìyàn rẹ yóò di òdodoàwọn ni yóò sì jogún ilẹ̀ náà títí ayé.Àwọn ni irúgbìn tí mo ti gbìn,iṣẹ́ ọwọ́ mi,láti fi ọláńlá mi hàn. 22 Èyí tí ó kéré jù nínú yín yóò di ẹgbẹ̀rún (1,000) kan,èyí tí ó kéré yóò di orílẹ̀-èdè ńlá.Èmi ni OLÚWA;ní àkókò rẹ̀, Èmi yóò ṣe èyí kánkán.”
In Other Versions
Isaiah 60 in the ANGEFD
Isaiah 60 in the ANTPNG2D
Isaiah 60 in the AS21
Isaiah 60 in the BAGH
Isaiah 60 in the BBPNG
Isaiah 60 in the BBT1E
Isaiah 60 in the BDS
Isaiah 60 in the BEV
Isaiah 60 in the BHAD
Isaiah 60 in the BIB
Isaiah 60 in the BLPT
Isaiah 60 in the BNT
Isaiah 60 in the BNTABOOT
Isaiah 60 in the BNTLV
Isaiah 60 in the BOATCB
Isaiah 60 in the BOATCB2
Isaiah 60 in the BOBCV
Isaiah 60 in the BOCNT
Isaiah 60 in the BOECS
Isaiah 60 in the BOGWICC
Isaiah 60 in the BOHCB
Isaiah 60 in the BOHCV
Isaiah 60 in the BOHLNT
Isaiah 60 in the BOHNTLTAL
Isaiah 60 in the BOICB
Isaiah 60 in the BOILNTAP
Isaiah 60 in the BOITCV
Isaiah 60 in the BOKCV
Isaiah 60 in the BOKCV2
Isaiah 60 in the BOKHWOG
Isaiah 60 in the BOKSSV
Isaiah 60 in the BOLCB
Isaiah 60 in the BOLCB2
Isaiah 60 in the BOMCV
Isaiah 60 in the BONAV
Isaiah 60 in the BONCB
Isaiah 60 in the BONLT
Isaiah 60 in the BONUT2
Isaiah 60 in the BOPLNT
Isaiah 60 in the BOSCB
Isaiah 60 in the BOSNC
Isaiah 60 in the BOTLNT
Isaiah 60 in the BOVCB
Isaiah 60 in the BPBB
Isaiah 60 in the BPH
Isaiah 60 in the BSB
Isaiah 60 in the CCB
Isaiah 60 in the CUV
Isaiah 60 in the CUVS
Isaiah 60 in the DBT
Isaiah 60 in the DGDNT
Isaiah 60 in the DHNT
Isaiah 60 in the DNT
Isaiah 60 in the ELBE
Isaiah 60 in the EMTV
Isaiah 60 in the ESV
Isaiah 60 in the FBV
Isaiah 60 in the FEB
Isaiah 60 in the GGMNT
Isaiah 60 in the GNT
Isaiah 60 in the HARY
Isaiah 60 in the HNT
Isaiah 60 in the IRVA
Isaiah 60 in the IRVB
Isaiah 60 in the IRVG
Isaiah 60 in the IRVH
Isaiah 60 in the IRVK
Isaiah 60 in the IRVM
Isaiah 60 in the IRVM2
Isaiah 60 in the IRVO
Isaiah 60 in the IRVP
Isaiah 60 in the IRVT
Isaiah 60 in the IRVT2
Isaiah 60 in the IRVU
Isaiah 60 in the ISVN
Isaiah 60 in the JSNT
Isaiah 60 in the KAPI
Isaiah 60 in the KBT1ETNIK
Isaiah 60 in the KBV
Isaiah 60 in the KJV
Isaiah 60 in the KNFD
Isaiah 60 in the LBA
Isaiah 60 in the LBLA
Isaiah 60 in the LNT
Isaiah 60 in the LSV
Isaiah 60 in the MAAL
Isaiah 60 in the MBV
Isaiah 60 in the MBV2
Isaiah 60 in the MHNT
Isaiah 60 in the MKNFD
Isaiah 60 in the MNG
Isaiah 60 in the MNT
Isaiah 60 in the MNT2
Isaiah 60 in the MRS1T
Isaiah 60 in the NAA
Isaiah 60 in the NASB
Isaiah 60 in the NBLA
Isaiah 60 in the NBS
Isaiah 60 in the NBVTP
Isaiah 60 in the NET2
Isaiah 60 in the NIV11
Isaiah 60 in the NNT
Isaiah 60 in the NNT2
Isaiah 60 in the NNT3
Isaiah 60 in the PDDPT
Isaiah 60 in the PFNT
Isaiah 60 in the RMNT
Isaiah 60 in the SBIAS
Isaiah 60 in the SBIBS
Isaiah 60 in the SBIBS2
Isaiah 60 in the SBICS
Isaiah 60 in the SBIDS
Isaiah 60 in the SBIGS
Isaiah 60 in the SBIHS
Isaiah 60 in the SBIIS
Isaiah 60 in the SBIIS2
Isaiah 60 in the SBIIS3
Isaiah 60 in the SBIKS
Isaiah 60 in the SBIKS2
Isaiah 60 in the SBIMS
Isaiah 60 in the SBIOS
Isaiah 60 in the SBIPS
Isaiah 60 in the SBISS
Isaiah 60 in the SBITS
Isaiah 60 in the SBITS2
Isaiah 60 in the SBITS3
Isaiah 60 in the SBITS4
Isaiah 60 in the SBIUS
Isaiah 60 in the SBIVS
Isaiah 60 in the SBT
Isaiah 60 in the SBT1E
Isaiah 60 in the SCHL
Isaiah 60 in the SNT
Isaiah 60 in the SUSU
Isaiah 60 in the SUSU2
Isaiah 60 in the SYNO
Isaiah 60 in the TBIAOTANT
Isaiah 60 in the TBT1E
Isaiah 60 in the TBT1E2
Isaiah 60 in the TFTIP
Isaiah 60 in the TFTU
Isaiah 60 in the TGNTATF3T
Isaiah 60 in the THAI
Isaiah 60 in the TNFD
Isaiah 60 in the TNT
Isaiah 60 in the TNTIK
Isaiah 60 in the TNTIL
Isaiah 60 in the TNTIN
Isaiah 60 in the TNTIP
Isaiah 60 in the TNTIZ
Isaiah 60 in the TOMA
Isaiah 60 in the TTENT
Isaiah 60 in the UBG
Isaiah 60 in the UGV
Isaiah 60 in the UGV2
Isaiah 60 in the UGV3
Isaiah 60 in the VBL
Isaiah 60 in the VDCC
Isaiah 60 in the YALU
Isaiah 60 in the YAPE
Isaiah 60 in the YBVTP
Isaiah 60 in the ZBP