Isaiah 66 (BOYCB)

1 Báyìí ni OLÚWA wí:“Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi.Níbo ni ilé tí ẹ ó kọ́ fún mi wà?Níbo ní ibi ìsinmi mi yóò gbé wà? 2 Kì í ha á ṣe ọwọ́ mi ló tí ṣe nǹkan wọ̀nyí,bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì wà?”ni OLÚWA wí. “Eléyìí ni ẹni tí mo kà sí:ẹni náà tí ó rẹra rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì kẹ́dùn ní ọkàn rẹ̀,tí ó sì wárìrì sí ọ̀rọ̀ mi. 3 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fi akọ màlúù rú ẹbọó dàbí ẹni tí ó pa ènìyàn kanàti ẹni tí ó bá fi ọ̀dọ́-àgùntàn kan tọrẹ,dàbí ẹni tí ó bẹ́ ajá kan lọ́rùn;ẹnikẹ́ni tí ó bá fi irúgbìn ìyẹ̀fun tọrẹdàbí ẹni tí ó mú ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ wá,ẹni tí ó bá sì sun tùràrí ìrántí,dàbí ẹni tí ó súre fún òrìṣà.Wọ́n ti yan ipa ọ̀nà tì wọ́n,ọkàn wọn pẹ̀lú sì láyọ̀ nínú ohun ìríra wọn, 4 fún ìdí èyí ni èmi pẹ̀lú yóò ṣe fi ọwọ́ líle mú wọnn ó sì mú ohun tí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀ wá sórí wọn.Nítorí nígbà tí mo pè, kò sí ẹni tí ó dáhùn,nígbà tí mo sọ̀rọ̀, ẹnikẹ́ni kò tẹ́tí sílẹ̀.Wọ́n ṣe ohun búburú ní ojú miwọ́n sì yan ohun tí mo kórìíra rẹ̀.” 5 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA,ẹ̀yin tí ẹ ń wárìrì nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀:“Àwọn arákùnrin yín tí wọ́n kórìíra yín,tí wọ́n ta yín nù nítorí orúkọ mi, wí pé,‘Jẹ́ kí a yin OLÚWA lógo,kí a le rí ayọ̀ yín!’Ṣùgbọ́n àwọn ni ojú yóò tì. 6 Gbọ́ rògbòdìyàn láti ìlú wá,gbọ́ ariwo náà láti tẹmpili wá!Ariwo tí OLÚWA ní í ṣetí ó ń san án fún àwọn ọ̀tá rẹ̀ ohuntí ó tọ́ sí wọn. 7 “Kí ó tó lọ sí ìrọbí,ó ti bímọ;kí ó tó di pé ìrora dé bá a,ó ti bí ọmọkùnrin. 8 Ta ni ó ti gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí?Ta ni ó ti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí?Ǹjẹ́ a le bí orílẹ̀-èdè kan níjọ́ kantàbí kí orílẹ̀-èdè lalẹ̀hù ní ìṣẹ́jú kan?Síbẹ̀síbẹ̀ Sioni bẹ̀rẹ̀ rírọbíbẹ́ẹ̀ ni ó sì bí àwọn ọmọ rẹ̀. 9 Ǹjẹ́ èmi a ha máa mú wá sí ìrọbíkí èmi má sì mú ni bí?”ni OLÚWA wí.“Ǹjẹ́ èmi a ha máa ṣé ilé ọmọnígbà tí mo ń mú ìbí wá?”Ni Ọlọ́run yín wí. 10 “Ẹ bá Jerusalẹmu yọ̀ kí inú yín kí ó sì dùn sí i,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀;ẹ yọ̀ gidigidi pẹ̀lú rẹ̀,gbogbo ẹ̀yin tí ó ti kẹ́dùn fún un. 11 Nítorí pé ẹ̀yin yóò mu ẹ o sì ní ìtẹ́lọ́rùnnínú ọmú rẹ̀ tí ó tu ni lára,ẹ̀yin yóò mu àmuyóẹ ó sì gbádùn nínú àkúnwọ́sílẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀.” 12 Nítorí báyìí ni OLÚWA wí:“Èmi yóò fún un ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí odòàti ọrọ̀ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí ìṣàn omi;ẹ̀yin yóò mu ọmú, a ó sì gbé yín ní apá rẹ̀a ó bá yín ṣeré ní orúkún rẹ̀. 13 Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti í tu ọmọ rẹ̀ nínú,bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò tù yín nínúa ó sì tù yín nínú lórí Jerusalẹmu.” 14 Nígbà tí ẹ bá rí èyí, inú yín yóò dùnẹ̀yin yóò sì gbilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i koríko;ọwọ́ OLÚWA ni a ó sọ di mí mọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ ni a ó fihàn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀. 15 Kíyèsi i, OLÚWA ń bọ̀ pẹ̀lú ináàti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ tí ó dàbí ìjì líle;òun yóò mú ìbínú rẹ sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ìrunú,àti ìbáwí rẹ̀ pẹ̀lú ahọ́n iná. 16 Nítorí pẹ̀lú iná àti idàni OLÚWA yóò ṣe ìdájọ́ lórí i gbogbo ènìyàn,àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí OLÚWA yóò pa. 17 “Gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì sọ ara wọn di mímọ́ láti lọ sínú ọgbà, tí wọ́n tẹ̀lé ẹni tí ó wà láàrín àwọn tí ó jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti èkúté àti àwọn ohun ìríra mìíràn ni wọn yóò bá òpin wọn pàdé papọ̀,” ni OLÚWA wí. 18 “Àti Èmi, nítorí ìgbésẹ̀ wọn àti èrò wọn, èmi ti múra tán láti wá kó àwọn orílẹ̀-èdè àti ahọ́n jọ, wọn yóò sì wá wo ògo mi. 19 “Èmi yóò sì gbé àmì kan kalẹ̀ láàrín wọn, èmi yóò sì rán díẹ̀ nínú àwọn tí ó sálà lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè Tarṣiṣi, sí àwọn ará Libia àti Ludi, sí Tubali àti ará Giriki, àti sí àwọn erékùṣù tí ó jìnnà réré tí kò tí ìgbọ́ nípa òkìkí mi tàbí kí ó rí ògo mi. Wọn yóò kéde ògo mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè. 20 Wọn yóò sì mú àwọn arákùnrin yín wá, láti gbogbo orílẹ̀-èdè, sí òkè mímọ́ mi ní Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí OLÚWA lórí ẹṣin, lórí kẹ̀kẹ́ ẹrù àti ọkọ̀-ẹṣin, àti lórí ìbáaka àti ìbákasẹ,” ni OLÚWA wí. “Wọn yóò kó wọn wá, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Israẹli ti mú ọrẹ oníhóró wọn wá, sínú Tẹmpili OLÚWA nínú ohun èlò mímọ́. 21 Àti pé èmi yóò sì yan àwọn kan nínú wọn pẹ̀lú láti jẹ́ àlùfáà àti Lefi,” ni OLÚWA wí. 22 “Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun tí mo dá yóò ṣe wà níwájú mi títí láé,” ni OLÚWA wí, “Bẹ́ẹ̀ ni orúkọ yín àti ìrandíran yín yóò pegedé. 23 Láti oṣù tuntun kan dé òmíràn àti láti ọjọ́ ìsinmi kan dé òmíràn, ni gbogbo ọmọ ènìyàn yóò wá, wọn yóò sì tẹríba níwájú mi,” ni OLÚWA wí. 24 “Wọn yóò sì jáde lọ wọn yóò sì lọ wo òkú àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ sí mi; kòkòrò wọn kì yóò kú, bẹ́ẹ̀ ni iná wọn ni a kì yóò pa, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jẹ́ ohun ìríra fún gbogbo ọmọ ènìyàn.”

In Other Versions

Isaiah 66 in the ANGEFD

Isaiah 66 in the ANTPNG2D

Isaiah 66 in the AS21

Isaiah 66 in the BAGH

Isaiah 66 in the BBPNG

Isaiah 66 in the BBT1E

Isaiah 66 in the BDS

Isaiah 66 in the BEV

Isaiah 66 in the BHAD

Isaiah 66 in the BIB

Isaiah 66 in the BLPT

Isaiah 66 in the BNT

Isaiah 66 in the BNTABOOT

Isaiah 66 in the BNTLV

Isaiah 66 in the BOATCB

Isaiah 66 in the BOATCB2

Isaiah 66 in the BOBCV

Isaiah 66 in the BOCNT

Isaiah 66 in the BOECS

Isaiah 66 in the BOGWICC

Isaiah 66 in the BOHCB

Isaiah 66 in the BOHCV

Isaiah 66 in the BOHLNT

Isaiah 66 in the BOHNTLTAL

Isaiah 66 in the BOICB

Isaiah 66 in the BOILNTAP

Isaiah 66 in the BOITCV

Isaiah 66 in the BOKCV

Isaiah 66 in the BOKCV2

Isaiah 66 in the BOKHWOG

Isaiah 66 in the BOKSSV

Isaiah 66 in the BOLCB

Isaiah 66 in the BOLCB2

Isaiah 66 in the BOMCV

Isaiah 66 in the BONAV

Isaiah 66 in the BONCB

Isaiah 66 in the BONLT

Isaiah 66 in the BONUT2

Isaiah 66 in the BOPLNT

Isaiah 66 in the BOSCB

Isaiah 66 in the BOSNC

Isaiah 66 in the BOTLNT

Isaiah 66 in the BOVCB

Isaiah 66 in the BPBB

Isaiah 66 in the BPH

Isaiah 66 in the BSB

Isaiah 66 in the CCB

Isaiah 66 in the CUV

Isaiah 66 in the CUVS

Isaiah 66 in the DBT

Isaiah 66 in the DGDNT

Isaiah 66 in the DHNT

Isaiah 66 in the DNT

Isaiah 66 in the ELBE

Isaiah 66 in the EMTV

Isaiah 66 in the ESV

Isaiah 66 in the FBV

Isaiah 66 in the FEB

Isaiah 66 in the GGMNT

Isaiah 66 in the GNT

Isaiah 66 in the HARY

Isaiah 66 in the HNT

Isaiah 66 in the IRVA

Isaiah 66 in the IRVB

Isaiah 66 in the IRVG

Isaiah 66 in the IRVH

Isaiah 66 in the IRVK

Isaiah 66 in the IRVM

Isaiah 66 in the IRVM2

Isaiah 66 in the IRVO

Isaiah 66 in the IRVP

Isaiah 66 in the IRVT

Isaiah 66 in the IRVT2

Isaiah 66 in the IRVU

Isaiah 66 in the ISVN

Isaiah 66 in the JSNT

Isaiah 66 in the KAPI

Isaiah 66 in the KBT1ETNIK

Isaiah 66 in the KBV

Isaiah 66 in the KJV

Isaiah 66 in the KNFD

Isaiah 66 in the LBA

Isaiah 66 in the LBLA

Isaiah 66 in the LNT

Isaiah 66 in the LSV

Isaiah 66 in the MAAL

Isaiah 66 in the MBV

Isaiah 66 in the MBV2

Isaiah 66 in the MHNT

Isaiah 66 in the MKNFD

Isaiah 66 in the MNG

Isaiah 66 in the MNT

Isaiah 66 in the MNT2

Isaiah 66 in the MRS1T

Isaiah 66 in the NAA

Isaiah 66 in the NASB

Isaiah 66 in the NBLA

Isaiah 66 in the NBS

Isaiah 66 in the NBVTP

Isaiah 66 in the NET2

Isaiah 66 in the NIV11

Isaiah 66 in the NNT

Isaiah 66 in the NNT2

Isaiah 66 in the NNT3

Isaiah 66 in the PDDPT

Isaiah 66 in the PFNT

Isaiah 66 in the RMNT

Isaiah 66 in the SBIAS

Isaiah 66 in the SBIBS

Isaiah 66 in the SBIBS2

Isaiah 66 in the SBICS

Isaiah 66 in the SBIDS

Isaiah 66 in the SBIGS

Isaiah 66 in the SBIHS

Isaiah 66 in the SBIIS

Isaiah 66 in the SBIIS2

Isaiah 66 in the SBIIS3

Isaiah 66 in the SBIKS

Isaiah 66 in the SBIKS2

Isaiah 66 in the SBIMS

Isaiah 66 in the SBIOS

Isaiah 66 in the SBIPS

Isaiah 66 in the SBISS

Isaiah 66 in the SBITS

Isaiah 66 in the SBITS2

Isaiah 66 in the SBITS3

Isaiah 66 in the SBITS4

Isaiah 66 in the SBIUS

Isaiah 66 in the SBIVS

Isaiah 66 in the SBT

Isaiah 66 in the SBT1E

Isaiah 66 in the SCHL

Isaiah 66 in the SNT

Isaiah 66 in the SUSU

Isaiah 66 in the SUSU2

Isaiah 66 in the SYNO

Isaiah 66 in the TBIAOTANT

Isaiah 66 in the TBT1E

Isaiah 66 in the TBT1E2

Isaiah 66 in the TFTIP

Isaiah 66 in the TFTU

Isaiah 66 in the TGNTATF3T

Isaiah 66 in the THAI

Isaiah 66 in the TNFD

Isaiah 66 in the TNT

Isaiah 66 in the TNTIK

Isaiah 66 in the TNTIL

Isaiah 66 in the TNTIN

Isaiah 66 in the TNTIP

Isaiah 66 in the TNTIZ

Isaiah 66 in the TOMA

Isaiah 66 in the TTENT

Isaiah 66 in the UBG

Isaiah 66 in the UGV

Isaiah 66 in the UGV2

Isaiah 66 in the UGV3

Isaiah 66 in the VBL

Isaiah 66 in the VDCC

Isaiah 66 in the YALU

Isaiah 66 in the YAPE

Isaiah 66 in the YBVTP

Isaiah 66 in the ZBP