John 20 (BOYCB)

1 Ní kùtùkùtù ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, nígbà tí ilẹ̀ kò tí ì mọ́, ni Maria Magdalene wá sí ibojì, ó sì rí i pé, a ti gbé òkúta kúrò lẹ́nu ibojì. 2 Nítorí náà, ó sáré, ó sì tọ Simoni Peteru àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn wá, ẹni tí Jesu fẹ́ràn, ó sì wí fún wọn pé, “Wọ́n ti gbé Olúwa kúrò nínú ibojì, àwa kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.” 3 Nígbà náà ni Peteru àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà jáde, wọ́n sì wá sí ibojì. 4 Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ sáré: èyí ọmọ-ẹ̀yìn náà sì sáré ya Peteru, ó sì kọ́kọ́ dé ibojì. 5 Ó sì bẹ̀rẹ̀ láti wo inú rẹ̀, ó rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀; ṣùgbọ́n òun kò wọ inú rẹ̀. 6 Nígbà náà ni Simoni Peteru tí ń bọ̀ lẹ́yìn rẹ̀ dé, ó sì wọ inú ibojì, ó sì rí aṣọ ọ̀gbọ̀ náà ní ilẹ̀. 7 Àti pé, gèlè tí ó wà níbi orí rẹ̀ kò sì wà pẹ̀lú aṣọ ọ̀gbọ̀ náà, ṣùgbọ́n ó ká jọ ní ibìkan fúnra rẹ̀. 8 Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà, ẹni tí ó kọ́ dé ibojì wọ inú rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì rí i, ó sì gbàgbọ́. 9 (Nítorí tí wọn kò sá à tí mọ ìwé mímọ́ pé, Jesu ní láti jíǹde kúrò nínú òkú). 10 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà sì tún padà lọ sí ilé wọn. 11 Ṣùgbọ́n Maria dúró létí ibojì lóde, ó ń sọkún: bí ó ti ń sọkún, bẹ́ẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀, ó sì wo inú ibojì. 12 Ó sì kíyèsi àwọn angẹli méjì aláṣọ funfun, wọ́n jókòó, ọ̀kan níhà orí àti ọ̀kan níhà ẹsẹ̀, níbi tí òkú Jesu gbé ti sùn sí. 13 Wọ́n sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún?”Ó sì wí fún wọn pé, “Nítorí tí wọ́n ti gbé Olúwa mi, èmi kò sì mọ ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí.” 14 Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó yípadà, ó sì rí Jesu dúró, kò sì mọ̀ pé Jesu ni. 15 Jesu wí fún un pé, “Obìnrin yìí, èéṣe tí ìwọ fi ń sọkún? Ta ni ìwọ ń wá?”Òun ṣe bí olùṣọ́gbà ní í ṣe, ó wí fún un pé, “Alàgbà, bí ìwọ bá ti gbé e kúrò níhìn-ín yìí, sọ ibi tí ìwọ tẹ́ ẹ sí fún mi, èmi yóò sì gbé e kúrò.” 16 Jesu wí fún un pé, “Maria!”Ó sì yípadà, ó wí fún un ní èdè Heberu pé, “Rabboni!” (èyí tí ó túmọ̀ sí “Olùkọ́”). 17 Jesu wí fún un pé, “Má ṣe fi ọwọ́ kàn mí; nítorí tí èmi kò tí ì gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Baba mi. Ṣùgbọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin mi, sì wí fún wọn pé, ‘Èmi ń gòkè lọ sí ọ̀dọ̀ Baba mi, àti Baba yín, àti sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi, àti Ọlọ́run yín.’ ” 18 Maria Magdalene wá, ó sì sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, “Òun ti rí Olúwa!” Àti pé, ó sì ti fi nǹkan wọ̀nyí fún òun. 19 Ní ọjọ́ kan náà, lọ́jọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀ nígbà tí alẹ́ lẹ́, tí a sì ti ìlẹ̀kùn ibi tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbé péjọ, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, bẹ́ẹ̀ ni Jesu dé, ó dúró láàrín, ó sì wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín.” 20 Nígbà tí ó sì ti wí bẹ́ẹ̀ tán, ó fi ọwọ́ àti ìhà rẹ̀ hàn wọ́n. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yọ̀, nígbà tí wọ́n rí Olúwa. 21 Nítorí náà, Jesu sì tún wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín: gẹ́gẹ́ bí Baba ti rán mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì rán yín.” 22 Nígbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó mí sí wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ gba Ẹ̀mí Mímọ́! 23 Ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá fi jì, a fi jì wọ́n; ẹ̀ṣẹ̀ ẹnikẹ́ni tí ẹ̀yin bá dádúró, a dá wọn dúró.” 24 Ṣùgbọ́n Tomasi, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá, tí a ń pè ní Didimu, kò wà pẹ̀lú wọn nígbà tí Jesu dé. 25 Nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù wí fún un pé, “Àwa ti rí Olúwa!”Ṣùgbọ́n ó wí fún un pé, “Bí kò ṣe pé mo bá rí àpá ìṣó ni ọwọ́ rẹ̀ kí èmi sì fi ìka mi sí àpá ìṣó náà, kí èmi sì fi ọwọ́ mi sí ìhà rẹ̀, èmi kì yóò gbàgbọ́!” 26 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́jọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì tún wà nínú ilé, àti Tomasi pẹ̀lú wọn: nígbà tí a sì ti ti ìlẹ̀kùn, Jesu dé, ó sì dúró láàrín, ó wí pé, “Àlàáfíà fún yín.” 27 Nígbà náà ni ó wí fún Tomasi pé, “Mú ìka rẹ wá níhìn-ín yìí, kí o sì wo ọwọ́ mi; sì mú ọwọ́ rẹ wá níhìn-ín, kí o sì fi sí ìhà mi: kí ìwọ má ṣe jẹ́ aláìgbàgbọ́ mọ́, ṣùgbọ́n jẹ́ onígbàgbọ́.” 28 Tomasi dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Olúwa mi àti Ọlọ́run mi!” 29 Jesu wí fún un pé, “Nítorí tí ìwọ rí mi ni ìwọ ṣe gbàgbọ́, alábùkún fún ni àwọn tí kò rí mi, tí wọ́n sì gbàgbọ́!” 30 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì mìíràn ni Jesu ṣe níwájú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, tí a kò kọ sínú ìwé yìí. 31 Ṣùgbọ́n wọ̀nyí ni a kọ, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́ pé Jesu ní í ṣe Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run, àti pé nípa gbígbàgbọ́, kí ẹ̀yin lè ní ìyè ní orúkọ rẹ̀.

In Other Versions

John 20 in the ANGEFD

John 20 in the ANTPNG2D

John 20 in the AS21

John 20 in the BAGH

John 20 in the BBPNG

John 20 in the BBT1E

John 20 in the BDS

John 20 in the BEV

John 20 in the BHAD

John 20 in the BIB

John 20 in the BLPT

John 20 in the BNT

John 20 in the BNTABOOT

John 20 in the BNTLV

John 20 in the BOATCB

John 20 in the BOATCB2

John 20 in the BOBCV

John 20 in the BOCNT

John 20 in the BOECS

John 20 in the BOGWICC

John 20 in the BOHCB

John 20 in the BOHCV

John 20 in the BOHLNT

John 20 in the BOHNTLTAL

John 20 in the BOICB

John 20 in the BOILNTAP

John 20 in the BOITCV

John 20 in the BOKCV

John 20 in the BOKCV2

John 20 in the BOKHWOG

John 20 in the BOKSSV

John 20 in the BOLCB

John 20 in the BOLCB2

John 20 in the BOMCV

John 20 in the BONAV

John 20 in the BONCB

John 20 in the BONLT

John 20 in the BONUT2

John 20 in the BOPLNT

John 20 in the BOSCB

John 20 in the BOSNC

John 20 in the BOTLNT

John 20 in the BOVCB

John 20 in the BPBB

John 20 in the BPH

John 20 in the BSB

John 20 in the CCB

John 20 in the CUV

John 20 in the CUVS

John 20 in the DBT

John 20 in the DGDNT

John 20 in the DHNT

John 20 in the DNT

John 20 in the ELBE

John 20 in the EMTV

John 20 in the ESV

John 20 in the FBV

John 20 in the FEB

John 20 in the GGMNT

John 20 in the GNT

John 20 in the HARY

John 20 in the HNT

John 20 in the IRVA

John 20 in the IRVB

John 20 in the IRVG

John 20 in the IRVH

John 20 in the IRVK

John 20 in the IRVM

John 20 in the IRVM2

John 20 in the IRVO

John 20 in the IRVP

John 20 in the IRVT

John 20 in the IRVT2

John 20 in the IRVU

John 20 in the ISVN

John 20 in the JSNT

John 20 in the KAPI

John 20 in the KBT1ETNIK

John 20 in the KBV

John 20 in the KJV

John 20 in the KNFD

John 20 in the LBA

John 20 in the LBLA

John 20 in the LNT

John 20 in the LSV

John 20 in the MAAL

John 20 in the MBV

John 20 in the MBV2

John 20 in the MHNT

John 20 in the MKNFD

John 20 in the MNG

John 20 in the MNT

John 20 in the MNT2

John 20 in the MRS1T

John 20 in the NAA

John 20 in the NASB

John 20 in the NBLA

John 20 in the NBS

John 20 in the NBVTP

John 20 in the NET2

John 20 in the NIV11

John 20 in the NNT

John 20 in the NNT2

John 20 in the NNT3

John 20 in the PDDPT

John 20 in the PFNT

John 20 in the RMNT

John 20 in the SBIAS

John 20 in the SBIBS

John 20 in the SBIBS2

John 20 in the SBICS

John 20 in the SBIDS

John 20 in the SBIGS

John 20 in the SBIHS

John 20 in the SBIIS

John 20 in the SBIIS2

John 20 in the SBIIS3

John 20 in the SBIKS

John 20 in the SBIKS2

John 20 in the SBIMS

John 20 in the SBIOS

John 20 in the SBIPS

John 20 in the SBISS

John 20 in the SBITS

John 20 in the SBITS2

John 20 in the SBITS3

John 20 in the SBITS4

John 20 in the SBIUS

John 20 in the SBIVS

John 20 in the SBT

John 20 in the SBT1E

John 20 in the SCHL

John 20 in the SNT

John 20 in the SUSU

John 20 in the SUSU2

John 20 in the SYNO

John 20 in the TBIAOTANT

John 20 in the TBT1E

John 20 in the TBT1E2

John 20 in the TFTIP

John 20 in the TFTU

John 20 in the TGNTATF3T

John 20 in the THAI

John 20 in the TNFD

John 20 in the TNT

John 20 in the TNTIK

John 20 in the TNTIL

John 20 in the TNTIN

John 20 in the TNTIP

John 20 in the TNTIZ

John 20 in the TOMA

John 20 in the TTENT

John 20 in the UBG

John 20 in the UGV

John 20 in the UGV2

John 20 in the UGV3

John 20 in the VBL

John 20 in the VDCC

John 20 in the YALU

John 20 in the YAPE

John 20 in the YBVTP

John 20 in the ZBP