Lamentations 1 (BOYCB)
1 Báwo ni ìlú ṣe jókòó nìkan,nígbà kan tí ó sì kún fún ènìyàn!Ó ti fìgbà kan jẹ́ ìlú olókìkí láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,tí ó wà ní ipò opó,ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ọbabìnrin láàrín ìlúni ó padà di ẹrú. 2 Ọ̀gànjọ́ òru ni ó fi máa ń sọkún kíkoròpẹ̀lú omijé ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ tí ó dúró sí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀.Nínú gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ̀kò sí ọ̀kan nínú wọn láti rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún.Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti jọ̀wọ́ rẹ̀wọ́n ti di alátakò rẹ̀. 3 Lẹ́yìn ìjìyà àti ìpọ́njú nínú oko ẹrú,Juda lọ sí àjòÓ tẹ̀dó láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,ṣùgbọ́n kò rí ibi ìsinmi.Àwọn tí ó ń tẹ̀lé ká á mọ́ibi tí kò ti le sá àsálà. 4 Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ Sioni ń ṣọ̀fọ̀,nítorí ẹnìkan kò wá sí àjọ̀dún tí a yàn.Gbogbo ẹnu-bodè rẹ̀ dahoro,àwọn àlùfáà rẹ̀ kẹ́dùn,àwọn wúńdíá rẹ̀ sì ń káàánú,òun gan an wà ní ọkàn kíkorò. 5 Àwọn aninilára rẹ̀ gbogbo di olúwa rẹ̀,nǹkan sì rọrùn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀, OLÚWA ti fún un ní ìjìyà tó tọ́nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.Àwọn ẹ̀ṣọ́ wẹ́wẹ́ rẹ̀ lọ sí oko ẹrú,ìgbèkùn níwájú àwọn ọ̀tá. 6 Gbogbo ẹwà ti di ohun ìgbàgbékúrò lọ́dọ̀ ọmọbìnrin Sioni.Àwọn ìjòyè rẹ̀ dàbí i àgbọ̀nríntí kò rí ewé tútù jẹ;nínú àárẹ̀ wọ́n sáréníwájú ẹni tí ó ń lé wọn. 7 Ní ọjọ́ ìpọ́njú àti àrìnká rẹ̀ niJerusalẹmu rántí àwọn ohun ìní dáradára rẹ̀tí ó jẹ́ tirẹ̀ ní ọjọ́ pípẹ́.Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣubú ṣọ́wọ́ àwọn ọ̀tá,kò sì ṣí olùrànlọ́wọ́ fún un.Àwọn ọ̀tá rẹ̀ wò ówọ́n sì ń fi ìparun rẹ̀ ṣẹlẹ́yà. 8 Jerusalẹmu sì ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ó sì ti di aláìmọ́.Àwọn tí ó ń tẹríba fún un sì kẹ́gàn rẹ̀,nítorí wọ́n ti rí ìhòhò rẹ̀;ó kérora fúnra rẹ̀,ó sì lọ kúrò. 9 Ìdọ̀tí wà ní etí aṣọ rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò wo ọjọ́ iwájú rẹ̀.Ìṣubú rẹ̀ ya ni lẹ́nu;olùtùnú kò sì ṣí fún un.“Wo ìpọ́njú mi, OLÚWA,nítorí àwọn ọ̀tá ti borí.” 10 Ọ̀tá ti gbọ́wọ́ légbogbo ìní rẹ;o rí pé àwọn orílẹ̀-èdètí wọ́n wọ ibi mímọ́ rẹ—àwọn tí o ti kọ̀sílẹ̀láti wọ ìpéjọpọ̀ rẹ. 11 Àwọn ènìyàn rẹ̀ ń kérorabí wọ́n ti ń wá oúnjẹ;wọ́n fi ohun ìní wọn ṣe pàṣípàrọ̀ oúnjẹláti mú wọn wà láààyè.“Wò ó, OLÚWA, kí o sì rò ó,nítorí a kọ̀ mí sílẹ̀.” 12 “Kò ha jẹ́ nǹkan kan sí i yín?Gbogbo ẹ̀yin tí ń rékọjá.Ǹjẹ́ ẹnìkan ń jìyà bí èmi ti ń jìyàtí a fi fún mi, ti OLÚWA mú wá fún miní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ̀. 13 “Ó rán iná láti òkèsọ̀kalẹ̀ sínú egungun ara mi.Ó dẹ àwọ̀n fún ẹsẹ̀ mi,ó sì yí mi padà.Ó ti pa mí láramó ń kú lọ ní gbogbo ọjọ́. 14 “Ẹ̀ṣẹ̀ mi ti di sísopọ̀ sí àjàgà;ọwọ́ rẹ̀ ni a fi hun ún papọ̀.Wọ́n ti yí ọrùn mi káOlúwa sì ti dín agbára mi kù.Ó sì ti fi mí léàwọn tí n kò le dojúkọ lọ́wọ́. 15 “Olúwa kọàwọn akọni mi sílẹ̀,ó rán àwọn ológun lòdì sí mikí wọn pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi run.Nínú ìfúntí wáìnì rẹ̀ Olúwa tẹ́àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Juda. 16 “Ìdí nìyí tí mo fi ń sọkúntí omijé sì ń dà lójú mi.Olùtùnú àti ẹni tí ó le mú ọkàn mi sọjí jìnnà sí mi,kò sí ẹni tí yóò dá ẹ̀mí mi padà.Àwọn ọmọ mi di aláìnínítorí ọ̀tá ti borí.” 17 Sioni na ọwọ́ jáde,ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún un. OLÚWA ti pàṣẹ fún Jakọbupé àwọn ará ilé rẹ̀ di ọ̀tá fún unJerusalẹmu ti diohun aláìmọ́ láàrín wọn. 18 “Olóòtítọ́ ni OLÚWA,ṣùgbọ́n mo ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀.Ẹ gbọ́, gbogbo ènìyàn;ẹ wò mí wò ìyà mi.Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mini a ti kó lọ sí ìgbèkùn. 19 “Mo pe àwọn ọ̀rẹ́ miṣùgbọ́n wọ́n dà mí.Àwọn olórí àlùfáà àti àgbàgbà miṣègbé sínú ìlúnígbà tí wọ́n ń wá oúnjẹtí yóò mú wọn wà láààyè. 20 “OLÚWA, wò ó, bí mo ti wà nínú ìnira!Tí mo sì ń jẹ̀rora nínú mi,ìdààmú dé bá ọkàn minítorí pé a ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi gidigidi.Ní gbangba ni idà ń parun;ikú wà nínú ilé pẹ̀lú. 21 “Àwọn ènìyàn ti gbọ́ ìrora mi,ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún mi.Àwọn ọ̀tá mi ti gbọ́ ìparun mi;wọ́n yọ̀ sí ohun tí o ṣe.Kí o mú ọjọ́ tí o ti kéde,kí wọ́n le dàbí tèmi. 22 “Jẹ́ kí ìwà ìkà wọn wá síwájú rẹ;jẹ wọ́n ní yàbí o ṣe jẹ mí ní yànítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi.Ìrora mi pọ̀ọkàn mi sì rẹ̀wẹ̀sì.”
In Other Versions
Lamentations 1 in the ANGEFD
Lamentations 1 in the ANTPNG2D
Lamentations 1 in the AS21
Lamentations 1 in the BAGH
Lamentations 1 in the BBPNG
Lamentations 1 in the BBT1E
Lamentations 1 in the BDS
Lamentations 1 in the BEV
Lamentations 1 in the BHAD
Lamentations 1 in the BIB
Lamentations 1 in the BLPT
Lamentations 1 in the BNT
Lamentations 1 in the BNTABOOT
Lamentations 1 in the BNTLV
Lamentations 1 in the BOATCB
Lamentations 1 in the BOATCB2
Lamentations 1 in the BOBCV
Lamentations 1 in the BOCNT
Lamentations 1 in the BOECS
Lamentations 1 in the BOGWICC
Lamentations 1 in the BOHCB
Lamentations 1 in the BOHCV
Lamentations 1 in the BOHLNT
Lamentations 1 in the BOHNTLTAL
Lamentations 1 in the BOICB
Lamentations 1 in the BOILNTAP
Lamentations 1 in the BOITCV
Lamentations 1 in the BOKCV
Lamentations 1 in the BOKCV2
Lamentations 1 in the BOKHWOG
Lamentations 1 in the BOKSSV
Lamentations 1 in the BOLCB
Lamentations 1 in the BOLCB2
Lamentations 1 in the BOMCV
Lamentations 1 in the BONAV
Lamentations 1 in the BONCB
Lamentations 1 in the BONLT
Lamentations 1 in the BONUT2
Lamentations 1 in the BOPLNT
Lamentations 1 in the BOSCB
Lamentations 1 in the BOSNC
Lamentations 1 in the BOTLNT
Lamentations 1 in the BOVCB
Lamentations 1 in the BPBB
Lamentations 1 in the BPH
Lamentations 1 in the BSB
Lamentations 1 in the CCB
Lamentations 1 in the CUV
Lamentations 1 in the CUVS
Lamentations 1 in the DBT
Lamentations 1 in the DGDNT
Lamentations 1 in the DHNT
Lamentations 1 in the DNT
Lamentations 1 in the ELBE
Lamentations 1 in the EMTV
Lamentations 1 in the ESV
Lamentations 1 in the FBV
Lamentations 1 in the FEB
Lamentations 1 in the GGMNT
Lamentations 1 in the GNT
Lamentations 1 in the HARY
Lamentations 1 in the HNT
Lamentations 1 in the IRVA
Lamentations 1 in the IRVB
Lamentations 1 in the IRVG
Lamentations 1 in the IRVH
Lamentations 1 in the IRVK
Lamentations 1 in the IRVM
Lamentations 1 in the IRVM2
Lamentations 1 in the IRVO
Lamentations 1 in the IRVP
Lamentations 1 in the IRVT
Lamentations 1 in the IRVT2
Lamentations 1 in the IRVU
Lamentations 1 in the ISVN
Lamentations 1 in the JSNT
Lamentations 1 in the KAPI
Lamentations 1 in the KBT1ETNIK
Lamentations 1 in the KBV
Lamentations 1 in the KJV
Lamentations 1 in the KNFD
Lamentations 1 in the LBA
Lamentations 1 in the LBLA
Lamentations 1 in the LNT
Lamentations 1 in the LSV
Lamentations 1 in the MAAL
Lamentations 1 in the MBV
Lamentations 1 in the MBV2
Lamentations 1 in the MHNT
Lamentations 1 in the MKNFD
Lamentations 1 in the MNG
Lamentations 1 in the MNT
Lamentations 1 in the MNT2
Lamentations 1 in the MRS1T
Lamentations 1 in the NAA
Lamentations 1 in the NASB
Lamentations 1 in the NBLA
Lamentations 1 in the NBS
Lamentations 1 in the NBVTP
Lamentations 1 in the NET2
Lamentations 1 in the NIV11
Lamentations 1 in the NNT
Lamentations 1 in the NNT2
Lamentations 1 in the NNT3
Lamentations 1 in the PDDPT
Lamentations 1 in the PFNT
Lamentations 1 in the RMNT
Lamentations 1 in the SBIAS
Lamentations 1 in the SBIBS
Lamentations 1 in the SBIBS2
Lamentations 1 in the SBICS
Lamentations 1 in the SBIDS
Lamentations 1 in the SBIGS
Lamentations 1 in the SBIHS
Lamentations 1 in the SBIIS
Lamentations 1 in the SBIIS2
Lamentations 1 in the SBIIS3
Lamentations 1 in the SBIKS
Lamentations 1 in the SBIKS2
Lamentations 1 in the SBIMS
Lamentations 1 in the SBIOS
Lamentations 1 in the SBIPS
Lamentations 1 in the SBISS
Lamentations 1 in the SBITS
Lamentations 1 in the SBITS2
Lamentations 1 in the SBITS3
Lamentations 1 in the SBITS4
Lamentations 1 in the SBIUS
Lamentations 1 in the SBIVS
Lamentations 1 in the SBT
Lamentations 1 in the SBT1E
Lamentations 1 in the SCHL
Lamentations 1 in the SNT
Lamentations 1 in the SUSU
Lamentations 1 in the SUSU2
Lamentations 1 in the SYNO
Lamentations 1 in the TBIAOTANT
Lamentations 1 in the TBT1E
Lamentations 1 in the TBT1E2
Lamentations 1 in the TFTIP
Lamentations 1 in the TFTU
Lamentations 1 in the TGNTATF3T
Lamentations 1 in the THAI
Lamentations 1 in the TNFD
Lamentations 1 in the TNT
Lamentations 1 in the TNTIK
Lamentations 1 in the TNTIL
Lamentations 1 in the TNTIN
Lamentations 1 in the TNTIP
Lamentations 1 in the TNTIZ
Lamentations 1 in the TOMA
Lamentations 1 in the TTENT
Lamentations 1 in the UBG
Lamentations 1 in the UGV
Lamentations 1 in the UGV2
Lamentations 1 in the UGV3
Lamentations 1 in the VBL
Lamentations 1 in the VDCC
Lamentations 1 in the YALU
Lamentations 1 in the YAPE
Lamentations 1 in the YBVTP
Lamentations 1 in the ZBP