Psalms 107 (BOYCB)
1 Ẹ fi ọpẹ́ fún OLÚWA, nítorí tí ó ṣeun;nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé. 2 Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà OLÚWA kí ó wí báyìí,àwọn ẹni tí ó rà padà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá, 3 àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì,láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn,láti àríwá àti Òkun wá. 4 Wọ́n ń rìn káàkiri ní aginjù ní ibi tí ọ̀nà kò sí,wọn kò rí ọ̀nà lọ sí ìlú níbi tíwọn ó máa gbé. 5 Ebi ń pa wọn, òǹgbẹ gbẹ wọ́n,ó sì rẹ ọkàn wọn nínú wọn. 6 Ní ìgbà náà, wọ́n kígbe sókèsí OLÚWA nínú ìdààmú wọn,ó sì yọ wọ́n kúrò nínú ìrora wọn 7 Ó fi ọ̀nà títọ́ hàn wọ́n sí ìlútí wọn lè máa gbé. 8 Ẹ jẹ́ kí wọn máa yin OLÚWA nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ìyanu rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn, 9 nítorí tí ó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn lọ́runó sì fi ìre fún ọkàn tí ebi ń pa. 10 Ọ̀pọ̀ jókòó nínú òkùnkùn àti òjìji ikú,a dè wọ́n ní ìrora àti ní irin, 11 nítorí tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ìbáwí Ọ̀gá-ògo, 12 Ó sì fi ìkorò rẹ àyà wọn sílẹ̀;wọn ṣubú, kò sì ṣí ẹni tíyóò ràn wọ́n lọ́wọ́. 13 Ní ìgbà náà wọ́n ké pe OLÚWA nínú ìdààmú wọn,ó sì gbà wọ́n nínú ìṣòro wọn 14 Ó mú wọn jáde kúrò nínúòkùnkùn àti òjìji ikú,ó sì fa irin tí wọ́n fi dè wọ́n já. 15 Ẹ jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún OLÚWA! Nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sí ọmọ ènìyàn. 16 Nítorí tí ó já ìlẹ̀kùn idẹ wọ̀n-ọn-nìó sì ké irin wọn ní agbede-méjì. 17 Ọ̀pọ̀ di aṣiwèrè nítorí ìrékọjá wọnwọ́n sì pọ́n wọn lójú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 18 Wọ́n kọ gbogbo oúnjẹwọ́n sì súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ikú. 19 Nígbà náà wọ́n kígbe sí OLÚWA nínú ìṣòro wọn,ó sì yọ wọ́n nínú ìdààmú wọn. 20 Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀, ara wọn sì dáó sì yọ wọ́n nínú isà òkú. 21 Ẹ jẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún OLÚWA nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn. 22 Jẹ́ kí wọn rú ẹbọ ọpẹ́kí wọn kí ó fi ayọ̀ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ̀. 23 Àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí Òkun nínú ọkọ̀ ojú omi,wọ́n jẹ́ oníṣòwò nínú omi ńlá. 24 Wọ́n rí iṣẹ́ OLÚWA,àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ nínú ibú. 25 Nítorí tí ó pàṣẹ, ó sì mú ìjì fẹ́tí ó gbé ríru rẹ̀ sókè. 26 Wọ́n gòkè lọ sí ọ̀run wọ́n sìtún sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibú:nítorí ìpọ́njú, ọkàn wọn di omi. 27 Wọ́n ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n bí ọ̀mùtí ènìyàn:ọgbọ́n wọn sì dé òpin. 28 Nígbà náà wọ́n ń kígbe sókèsí OLÚWA nínú ìdààmú wọn,ó sì mú wọn jáde nínú ìṣòro wọn. 29 Ó sọ ìjì di ìdákẹ́rọ́rọ́bẹ́ẹ̀ ni ríru omi rẹ̀ dúró jẹ́ẹ́. 30 Inú wọn dùn nígbà tí ara wọn balẹ̀,ó mú wọn lọ sí ibi tí ọkàn wọn lọ. 31 Jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún OLÚWA nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn. 32 Jẹ́ kí wọn gbé e ga ní àárín àwọn ènìyànkí wọn kí ó sì yìn ín ní ìjọ àwọn àgbàgbà. 33 Ó sọ odò di aginjù,àti orísun omi di ilẹ̀ gbígbẹ. 34 Ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀nítorí ìwà búburú àwọn tí ó wà nínú rẹ̀. 35 O sọ aginjù di adágún omi àtiilẹ̀ gbígbẹ di orísun omi, 36 níbẹ̀ ó mú ẹni tí ebi ń pa wà,wọ́n sì pilẹ̀ ibi tí wọn ó máa gbé. 37 Wọn fún irúgbìn, wọ́n sì gbin ọgbà àjàràtí yóò máa so èso tí ó dára; 38 Ó bùkún wọn, wọ́n sì pọ̀ sí i ní iyekò sí jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọn kí ó dínkù. 39 Nígbà náà, ọjọ́ wọn kúrú,ìnira, ìpọ́njú àti ìṣòro wọn sì dínkù, 40 ẹni tí ó da ẹ̀gàn lu ọmọ-aládéó sì mú wọn rìn níbi tí ọ̀nà kò sí. 41 Ṣùgbọ́n ó gbé aláìní sókè kúrò nínú ìniraó mú ìdílé wọn pọ̀ bí agbo ẹran. 42 Àwọn tí ó dúró sì rí i, inú wọn sì dùnṣùgbọ́n gbogbo olùṣe búburú yóò pa ẹnu rẹ̀ mọ́. 43 Ẹni tí ó bá gbọ́n, jẹ́ kí ó kíyèsi nǹkan wọ̀nyíkí ó wo títóbi ìfẹ́ OLÚWA.
In Other Versions
Psalms 107 in the ANGEFD
Psalms 107 in the ANTPNG2D
Psalms 107 in the AS21
Psalms 107 in the BAGH
Psalms 107 in the BBPNG
Psalms 107 in the BBT1E
Psalms 107 in the BDS
Psalms 107 in the BEV
Psalms 107 in the BHAD
Psalms 107 in the BIB
Psalms 107 in the BLPT
Psalms 107 in the BNT
Psalms 107 in the BNTABOOT
Psalms 107 in the BNTLV
Psalms 107 in the BOATCB
Psalms 107 in the BOATCB2
Psalms 107 in the BOBCV
Psalms 107 in the BOCNT
Psalms 107 in the BOECS
Psalms 107 in the BOGWICC
Psalms 107 in the BOHCB
Psalms 107 in the BOHCV
Psalms 107 in the BOHLNT
Psalms 107 in the BOHNTLTAL
Psalms 107 in the BOICB
Psalms 107 in the BOILNTAP
Psalms 107 in the BOITCV
Psalms 107 in the BOKCV
Psalms 107 in the BOKCV2
Psalms 107 in the BOKHWOG
Psalms 107 in the BOKSSV
Psalms 107 in the BOLCB
Psalms 107 in the BOLCB2
Psalms 107 in the BOMCV
Psalms 107 in the BONAV
Psalms 107 in the BONCB
Psalms 107 in the BONLT
Psalms 107 in the BONUT2
Psalms 107 in the BOPLNT
Psalms 107 in the BOSCB
Psalms 107 in the BOSNC
Psalms 107 in the BOTLNT
Psalms 107 in the BOVCB
Psalms 107 in the BPBB
Psalms 107 in the BPH
Psalms 107 in the BSB
Psalms 107 in the CCB
Psalms 107 in the CUV
Psalms 107 in the CUVS
Psalms 107 in the DBT
Psalms 107 in the DGDNT
Psalms 107 in the DHNT
Psalms 107 in the DNT
Psalms 107 in the ELBE
Psalms 107 in the EMTV
Psalms 107 in the ESV
Psalms 107 in the FBV
Psalms 107 in the FEB
Psalms 107 in the GGMNT
Psalms 107 in the GNT
Psalms 107 in the HARY
Psalms 107 in the HNT
Psalms 107 in the IRVA
Psalms 107 in the IRVB
Psalms 107 in the IRVG
Psalms 107 in the IRVH
Psalms 107 in the IRVK
Psalms 107 in the IRVM
Psalms 107 in the IRVM2
Psalms 107 in the IRVO
Psalms 107 in the IRVP
Psalms 107 in the IRVT
Psalms 107 in the IRVT2
Psalms 107 in the IRVU
Psalms 107 in the ISVN
Psalms 107 in the JSNT
Psalms 107 in the KAPI
Psalms 107 in the KBT1ETNIK
Psalms 107 in the KBV
Psalms 107 in the KJV
Psalms 107 in the KNFD
Psalms 107 in the LBA
Psalms 107 in the LBLA
Psalms 107 in the LNT
Psalms 107 in the LSV
Psalms 107 in the MAAL
Psalms 107 in the MBV
Psalms 107 in the MBV2
Psalms 107 in the MHNT
Psalms 107 in the MKNFD
Psalms 107 in the MNG
Psalms 107 in the MNT
Psalms 107 in the MNT2
Psalms 107 in the MRS1T
Psalms 107 in the NAA
Psalms 107 in the NASB
Psalms 107 in the NBLA
Psalms 107 in the NBS
Psalms 107 in the NBVTP
Psalms 107 in the NET2
Psalms 107 in the NIV11
Psalms 107 in the NNT
Psalms 107 in the NNT2
Psalms 107 in the NNT3
Psalms 107 in the PDDPT
Psalms 107 in the PFNT
Psalms 107 in the RMNT
Psalms 107 in the SBIAS
Psalms 107 in the SBIBS
Psalms 107 in the SBIBS2
Psalms 107 in the SBICS
Psalms 107 in the SBIDS
Psalms 107 in the SBIGS
Psalms 107 in the SBIHS
Psalms 107 in the SBIIS
Psalms 107 in the SBIIS2
Psalms 107 in the SBIIS3
Psalms 107 in the SBIKS
Psalms 107 in the SBIKS2
Psalms 107 in the SBIMS
Psalms 107 in the SBIOS
Psalms 107 in the SBIPS
Psalms 107 in the SBISS
Psalms 107 in the SBITS
Psalms 107 in the SBITS2
Psalms 107 in the SBITS3
Psalms 107 in the SBITS4
Psalms 107 in the SBIUS
Psalms 107 in the SBIVS
Psalms 107 in the SBT
Psalms 107 in the SBT1E
Psalms 107 in the SCHL
Psalms 107 in the SNT
Psalms 107 in the SUSU
Psalms 107 in the SUSU2
Psalms 107 in the SYNO
Psalms 107 in the TBIAOTANT
Psalms 107 in the TBT1E
Psalms 107 in the TBT1E2
Psalms 107 in the TFTIP
Psalms 107 in the TFTU
Psalms 107 in the TGNTATF3T
Psalms 107 in the THAI
Psalms 107 in the TNFD
Psalms 107 in the TNT
Psalms 107 in the TNTIK
Psalms 107 in the TNTIL
Psalms 107 in the TNTIN
Psalms 107 in the TNTIP
Psalms 107 in the TNTIZ
Psalms 107 in the TOMA
Psalms 107 in the TTENT
Psalms 107 in the UBG
Psalms 107 in the UGV
Psalms 107 in the UGV2
Psalms 107 in the UGV3
Psalms 107 in the VBL
Psalms 107 in the VDCC
Psalms 107 in the YALU
Psalms 107 in the YAPE
Psalms 107 in the YBVTP
Psalms 107 in the ZBP