Job 31 (BOYCB)
1 “Mo ti bá ojú mi dá májẹ̀mú,èmi yó ha ṣe tẹjúmọ́ wúńdíá? 2 Nítorí pé kí ni ìpín Ọlọ́run láti ọ̀run wá?Tàbí kí ni ogún Olódùmarè láti òkè ọ̀run wá. 3 Kò ṣe pé àwọn ènìyàn búburú ni ìparun wà fún,àti àjàkálẹ̀-ààrùn fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀? 4 Òun kò ha ri ipa ọ̀nà mi,òun kò ha sì ka gbogbo ìṣísẹ̀ mi? 5 “Bí ó bá ṣe pé èmi bá fi àìṣòótọ́ rìn,tàbí tí ẹsẹ̀ mi sì yára sí ẹ̀tàn, 6 (jẹ́ kí Ọlọ́run wọ́n mí nínú ìwọ̀n òdodo,kí Ọlọ́run le mọ ìdúró ṣinṣin mi.) 7 Bí ẹsẹ̀ mí bá yà kúrò lójú ọ̀nà,tí àyà mí sì tẹ̀lé ipa ojú mi,tàbí bí àbàwọ́n kan bá sì lẹ̀ mọ́ mi ní ọwọ́, 8 ǹjẹ́ kí èmi kí ó gbìn kí ẹlòmíràn kí ó sì mújẹ,àní kí a fa irú-ọmọ mi tu. 9 “Bí àyà mi bá di fífà sí ipasẹ̀ obìnrin kan,tàbí bí mo bá lọ í ba de ènìyàn ní ẹnu-ọ̀nà ilé aládùúgbò mi, 10 kí àyà mi kí ó lọ ọlọ fún ẹlòmíràn,kí àwọn ẹlòmíràn kí ó tẹ̀ ara wọn ní ara rẹ̀. 11 Nítorí pé yóò jẹ́ ohun ìtìjú àní,ẹ̀ṣẹ̀ tí a ó ṣe onídàájọ́ rẹ̀. 12 Nítorí pé iná ní èyí tí ó jó dé ibi ìparun,tí ìbá sì fa gbòǹgbò ohun ìbísí mi gbogbo tu. 13 “Tí mo bá sì ṣe àìka ọ̀ràn ìránṣẹ́kùnrin mitàbí ìránṣẹ́bìnrin mi sí,nígbà tí wọ́n bá ń bá mi jà; 14 kí ni èmi ó ha ṣe nígbà tí Ọlọ́run bá dìde?Nígbà tí ó bá sì ṣe ìbẹ̀wò, ohùn kí ni èmi ó dá? 15 Ẹni tí ó dá mi ní inú kọ́ ni ó dá a?Ẹnìkan náà kí ó mọ wá ní inú ìyá wa? 16 “Bí mo bá fa ọwọ́ sẹ́yìn fún ìfẹ́ inú tálákà,tàbí bí mo bá sì mú kí ojú opó rẹ̀wẹ̀sì, 17 tàbí tí mo bá nìkan bu òkèlè mi jẹ,tí aláìní baba kò jẹ nínú rẹ̀; 18 nítorí pé láti ìgbà èwe mi wá ni a ti tọ́ ọ dàgbà pẹ̀lú mi bí ẹni pé baba,èmi sì ń ṣe ìtọ́jú opó láti inú ìyá mi wá: 19 bí èmi bá rí olùpọ́njú láìní aṣọ,tàbí tálákà kan láìní ìbora; 20 bí ọkàn rẹ̀ kò bá súre fún mi,tàbí bí ara rẹ̀ kò sì gbóná nípasẹ̀ irun àgùntàn mi; 21 bí mo bá sì gbé ọwọ́ mi sókè sí aláìní baba,nítorí pé mo rí ìrànlọ́wọ́ mi ní ẹnu ibodè, 22 ǹjẹ́, ní apá mi kí o wọ́n kúrò ní ihò èjìká rẹ̀,kí apá mi kí ó sì ṣẹ́ láti egungun rẹ̀ wá. 23 Nítorí pé ìparun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ẹ̀rù ńlá fún mi,àti nítorí ọláńlá rẹ̀ èmi kò le è dúró. 24 “Bí ó bá ṣe pé mo fi wúrà ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé mi,tàbí tí mo bá wí fún fàdákà dídára pé, ‘Ìwọ ni ààbò mi,’ 25 bí mo bá yọ̀ nítorí ọrọ̀ mí pọ̀,àti nítorí ọwọ́ mi dara lọ́pọ̀lọ́pọ̀, 26 bí mo bá bojú wo oòrùn nígbà tí ń ràn,tàbí òṣùpá tí ń ràn nínú ìtànmọ́lẹ̀, 27 bí a bá tàn ọkàn mi jẹláti fi ẹnu mi kò ọwọ́ mi, 28 èyí pẹ̀lú ni ẹ̀ṣẹ̀ ti àwọn onídàájọ́ ní láti bẹ̀wò,nítorí pé èmí yóò jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run tí ó wà lókè. 29 “Bí ó bá ṣe pé mo yọ̀ sì ìparun ẹni tí ó kórìíra mi.Tàbí bí mo bá sì gbéraga sókè, nígbà tí ibi bá a. 30 Bẹ́ẹ̀ èmi kò sì jẹ ki ẹnu mi ki ó ṣẹ̀nípa fífẹ́ ègún sí ọkàn rẹ̀. 31 Bí àwọn ènìyàn inú àgọ́ mi kò bá lè wí pé,‘Ta ni kò ì tí ì jẹ ẹran rẹ̀ ní àjẹyó?’ 32 Àlejò kò wọ̀ ni ìgboro rí;èmí ṣí ìlẹ̀kùn mi sílẹ̀ fún èrò. 33 Bí mo bá bò ẹ̀ṣẹ̀ mi mọ́lẹ̀ bí Adamu ni pápá,ẹ̀bi mi pamọ́ ni àyà mi. 34 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni mo ha bẹ̀rù bí?Tàbí ẹ̀gàn àwọn ìdílé ní ń bà mí ní ẹ̀rù?Tí mo fi pa ẹnu mọ́, tí èmí kò sì fi sọ̀rọ̀ jáde? 35 (“Ìbá ṣe pé ẹnìkan le gbọ́ ti èmí!Kíyèsi i, àmì mi, kí Olódùmarè kí ó dá mi lóhùn,kí èmí kí ó sì rí ìwé náà tí olùfisùn mi ti kọ. 36 Nítòótọ́ èmí ìbá gbé le èjìká mi,èmi ìbá sì dé bí adé mọ́ orí mi. 37 Èmi ìbá sì sọ iye ìṣísẹ̀ mi fún un,bí ọmọ-aládé ni èmi ìbá súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.) 38 “Bí ilẹ̀ mi bá sì ké rara lòdì sí mití a sì fi omijé kún gbogbo poro rẹ̀. 39 Bí mo bá jẹ èso oko mi láìsan owótàbí tí mo sì mú ọkàn olúwa rẹ̀ fò lọ, 40 kí ẹ̀gún òṣùṣú kí ó hù dípò alikama,àti èpò búburú dípò ọkà barle.”Ọ̀rọ̀ Jobu parí.