Revelation 18 (BOYCB)

1 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo sì rí angẹli mìíràn, ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá ti òun ti agbára ńlá; ilẹ̀ ayé sì ti ipa ògo rẹ̀ mọ́lẹ̀. 2 Ó sì kígbe ní ohùn rara, wí pé:“Babeli ńlá ṣubú! Ó ṣubú!Ó sì di ibùjókòó àwọn ẹ̀mí èṣù,àti ihò fún ẹ̀mí àìmọ́ gbogbo,àti ilé fún ẹyẹ àìmọ́ gbogbo,ilé fún ẹranko ìríra àti àìmọ́ gbogbo. 3 Nítorí nípa ọtí wáìnì ìrunú àgbèrè rẹ̀ nigbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú.Àwọn ọba ayé sì ti bá a ṣe àgbèrè,àti àwọn oníṣòwò ayé sì di ọlọ́rọ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọ̀bìà rẹ̀.” 4 Mo sì gbọ́ ohùn mìíràn láti ọ̀run wá, wí pé:“ ‘Ẹ ti inú rẹ̀ jáde, ẹ̀yin ènìyàn mi,’kí ẹ ma bá a ṣe alábápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,kí ẹ ma bà á sì ṣe gbà nínú ìyọnu rẹ̀. 5 Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga títí dé ọ̀run,Ọlọ́run sì ti rántí àìṣedéédéé rẹ̀. 6 San an fún un, àní bí òun tí san án fún ní,kí ó sì ṣe e ni ìlọ́po méjì fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀,nínú ago náà tí o ti kún, òun ni kí ẹ sì kún fún un ni méjì. 7 Níwọ́n bí o ti yin ara rẹ̀ lógo tó,tí ó sì hùwà wọ̀bìà,níwọ̀n bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ dá a lóró kí ẹ sì fún un ní ìbànújẹ́;nítorí tí ó wí ní ọkàn rẹ̀ pé,‘Mo jókòó bí ọbabìnrin,èmi kì sì í ṣe opó, èmí kì yóò sì rí ìbànújẹ́ láé.’ 8 Nítorí náà, ní ọjọ́ kan ni ìyọnu rẹ̀ yóò dé,ikú, àti ìbìnújẹ́, àti ìyàn;a ó sì fi iná sun ún pátápátá:nítorí pé alágbára ni Olúwa Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀. 9 “Àti àwọn ọba ayé, tí ó ti ń bá a ṣe àgbèrè, tiwọn sì ń hùwà wọ̀bìà, yóò sì pohùnréré ẹkún lé e lórí, nígbà tí wọn bá wo èéfín ìjóná rẹ̀. 10 Wọ́n ó dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn ó máa wí pé:“ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà,Babeli ìlú alágbára nì!Nítorí ní wákàtí kan ni ìdájọ́ rẹ dé!’ 11 “Àwọn oníṣòwò ayé sì ń sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, nítorí pé ẹnikẹ́ni kò rà ọjà wọn mọ́. 12 Ọjà wúrà, àti ti fàdákà, àti ti òkúta iyebíye, àti ti perli, àti ti aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, àti tí elése àlùkò, àti ti ṣẹ́dà, àti ti òdòdó, àti ti gbogbo igi olóòórùn dídùn, àti ti olúkúlùkù ohun èlò tí a fi igi iyebíye ṣe, àti ti idẹ, àti ti irin, àti ti òkúta mabu. 13 Àti ti Kinamoni, àti ti onírúurú ohun olóòórùn dídùn, àti ti ohun ìkunra, àti tí tùràrí, àti ti ọtí wáìnì, àti ti òróró, àti ti ìyẹ̀fun dáradára, àti ti alikama, àti ti ẹran ńlá, àti ti àgùntàn, àti ti ẹṣin, àti ti kẹ̀kẹ́, àti ti ẹrú, àti ti ọkàn ènìyàn. 14 “Àti àwọn èso tí ọkàn rẹ̀ ń ṣe. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí, si lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ, àti ohun gbogbo tí ó dùn tí ó sì dára ṣègbé mọ́ ọ lójú, kì yóò sì tún rí wọn mọ́ láé. 15 Àwọn oníṣòwò nǹkan wọ̀nyí, tí a ti ipa rẹ̀ sọ di ọlọ́rọ̀, yóò dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn o máa sọkún, wọ́n ó sì máa ṣọ̀fọ̀, 16 wí pé:“ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá nì,tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́,àti ti elése àlùkò, àti ti òdòdó, àti ti a sì fi wúrà ṣe ní ọ̀ṣọ́, pẹ̀lú òkúta iyebíye àti peali! 17 Nítorí pé ní wákàtí kan ni ọrọ̀ ti o pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ di asán!’“Àti olúkúlùkù ẹni tí ń rin ojú omi lọ sí ibikíbi, àti àwọn ti ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ àwọn ti ń ṣòwò ojú Òkun dúró ní òkèrè réré, 18 wọ́n sì kígbe nígbà tí wọ́n rí èéfín jíjóná rẹ́, wí pé, ‘Ìlú wo ni o dàbí ìlú yìí?’ 19 Wọ́n sì kú ekuru sí orí wọn, wọ́n kígbe, wọ́n sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀, wí pé:“ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà,nínú èyí tí a sọ gbogbo àwọn tí ó ni ọkọ̀ní Òkun di ọlọ́rọ̀ nípa ohun iyebíye rẹ̀!Nítorí pé ni wákàtí kan, a sọ ọ́ di ahoro.’ 20 “Yọ̀ lórí rẹ̀, ìwọ ọ̀run!Ẹ yọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Ọlọ́run!Ẹ yọ̀, ẹ̀yin aposteli mímọ́ àti wòlíì!Nítorí Ọlọ́run ti gbẹ̀san yín lára rẹ̀nítorí ìdájọ́ tí ó gbé ka orí rẹ.” 21 Angẹli alágbára kan sì gbé òkúta kan sókè, ó dàbí ọlọ ńlá, ó sì jù ú sínú Òkun, wí pé:“Báyìí ní a ó fi agbára ńlábí i Babeli ìlú ńlá ni wó,a kì yóò sì rí i mọ́ láé. 22 Àti ohùn àwọn aludùùrù, àti ti àwọn olórin,àti ti àwọn afunfèrè, àti ti àwọn afùnpè,ni a kì yóò sì gbọ́ nínú rẹ mọ́ rara;àti olúkúlùkù oníṣọ̀nà ohunkóhun ni a kì yóò sì rí nínú rẹ mọ́ láé.Àti ìró ọlọ ní a kì yóòsì gbọ́ mọ̀ nínú rẹ láé; 23 Àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà ni kì yóò sì tàn nínú rẹ̀ mọ́ láé;a kì yóò sì gbọ́ ohùn ọkọ ìyàwó àti ti ìyàwó nínú rẹ mọ́ láé:nítorí pé àwọn oníṣòwò rẹ̀ ni àwọn ẹni ńlá ayé;nítorí pé nípa ọ̀ṣọ́ rẹ̀ ní a fi tàn orílẹ̀-èdè gbogbo jẹ. 24 Àti nínú rẹ̀ ní a gbé ri ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì,àti ti àwọn ènìyàn mímọ́, àti ti gbogbo àwọn tí a pa lórí ilẹ̀ ayé.”

In Other Versions

Revelation 18 in the ANGEFD

Revelation 18 in the ANTPNG2D

Revelation 18 in the AS21

Revelation 18 in the BAGH

Revelation 18 in the BBPNG

Revelation 18 in the BBT1E

Revelation 18 in the BDS

Revelation 18 in the BEV

Revelation 18 in the BHAD

Revelation 18 in the BIB

Revelation 18 in the BLPT

Revelation 18 in the BNT

Revelation 18 in the BNTABOOT

Revelation 18 in the BNTLV

Revelation 18 in the BOATCB

Revelation 18 in the BOATCB2

Revelation 18 in the BOBCV

Revelation 18 in the BOCNT

Revelation 18 in the BOECS

Revelation 18 in the BOGWICC

Revelation 18 in the BOHCB

Revelation 18 in the BOHCV

Revelation 18 in the BOHLNT

Revelation 18 in the BOHNTLTAL

Revelation 18 in the BOICB

Revelation 18 in the BOILNTAP

Revelation 18 in the BOITCV

Revelation 18 in the BOKCV

Revelation 18 in the BOKCV2

Revelation 18 in the BOKHWOG

Revelation 18 in the BOKSSV

Revelation 18 in the BOLCB

Revelation 18 in the BOLCB2

Revelation 18 in the BOMCV

Revelation 18 in the BONAV

Revelation 18 in the BONCB

Revelation 18 in the BONLT

Revelation 18 in the BONUT2

Revelation 18 in the BOPLNT

Revelation 18 in the BOSCB

Revelation 18 in the BOSNC

Revelation 18 in the BOTLNT

Revelation 18 in the BOVCB

Revelation 18 in the BPBB

Revelation 18 in the BPH

Revelation 18 in the BSB

Revelation 18 in the CCB

Revelation 18 in the CUV

Revelation 18 in the CUVS

Revelation 18 in the DBT

Revelation 18 in the DGDNT

Revelation 18 in the DHNT

Revelation 18 in the DNT

Revelation 18 in the ELBE

Revelation 18 in the EMTV

Revelation 18 in the ESV

Revelation 18 in the FBV

Revelation 18 in the FEB

Revelation 18 in the GGMNT

Revelation 18 in the GNT

Revelation 18 in the HARY

Revelation 18 in the HNT

Revelation 18 in the IRVA

Revelation 18 in the IRVB

Revelation 18 in the IRVG

Revelation 18 in the IRVH

Revelation 18 in the IRVK

Revelation 18 in the IRVM

Revelation 18 in the IRVM2

Revelation 18 in the IRVO

Revelation 18 in the IRVP

Revelation 18 in the IRVT

Revelation 18 in the IRVT2

Revelation 18 in the IRVU

Revelation 18 in the ISVN

Revelation 18 in the JSNT

Revelation 18 in the KAPI

Revelation 18 in the KBT1ETNIK

Revelation 18 in the KBV

Revelation 18 in the KJV

Revelation 18 in the KNFD

Revelation 18 in the LBA

Revelation 18 in the LBLA

Revelation 18 in the LNT

Revelation 18 in the LSV

Revelation 18 in the MAAL

Revelation 18 in the MBV

Revelation 18 in the MBV2

Revelation 18 in the MHNT

Revelation 18 in the MKNFD

Revelation 18 in the MNG

Revelation 18 in the MNT

Revelation 18 in the MNT2

Revelation 18 in the MRS1T

Revelation 18 in the NAA

Revelation 18 in the NASB

Revelation 18 in the NBLA

Revelation 18 in the NBS

Revelation 18 in the NBVTP

Revelation 18 in the NET2

Revelation 18 in the NIV11

Revelation 18 in the NNT

Revelation 18 in the NNT2

Revelation 18 in the NNT3

Revelation 18 in the PDDPT

Revelation 18 in the PFNT

Revelation 18 in the RMNT

Revelation 18 in the SBIAS

Revelation 18 in the SBIBS

Revelation 18 in the SBIBS2

Revelation 18 in the SBICS

Revelation 18 in the SBIDS

Revelation 18 in the SBIGS

Revelation 18 in the SBIHS

Revelation 18 in the SBIIS

Revelation 18 in the SBIIS2

Revelation 18 in the SBIIS3

Revelation 18 in the SBIKS

Revelation 18 in the SBIKS2

Revelation 18 in the SBIMS

Revelation 18 in the SBIOS

Revelation 18 in the SBIPS

Revelation 18 in the SBISS

Revelation 18 in the SBITS

Revelation 18 in the SBITS2

Revelation 18 in the SBITS3

Revelation 18 in the SBITS4

Revelation 18 in the SBIUS

Revelation 18 in the SBIVS

Revelation 18 in the SBT

Revelation 18 in the SBT1E

Revelation 18 in the SCHL

Revelation 18 in the SNT

Revelation 18 in the SUSU

Revelation 18 in the SUSU2

Revelation 18 in the SYNO

Revelation 18 in the TBIAOTANT

Revelation 18 in the TBT1E

Revelation 18 in the TBT1E2

Revelation 18 in the TFTIP

Revelation 18 in the TFTU

Revelation 18 in the TGNTATF3T

Revelation 18 in the THAI

Revelation 18 in the TNFD

Revelation 18 in the TNT

Revelation 18 in the TNTIK

Revelation 18 in the TNTIL

Revelation 18 in the TNTIN

Revelation 18 in the TNTIP

Revelation 18 in the TNTIZ

Revelation 18 in the TOMA

Revelation 18 in the TTENT

Revelation 18 in the UBG

Revelation 18 in the UGV

Revelation 18 in the UGV2

Revelation 18 in the UGV3

Revelation 18 in the VBL

Revelation 18 in the VDCC

Revelation 18 in the YALU

Revelation 18 in the YAPE

Revelation 18 in the YBVTP

Revelation 18 in the ZBP